Coronavirus: Pásítọ̀ Adeboye ní òun faramọ́ ìmọ́tótó, ṣùgbọ́n àwàdà ni ìgbésẹ̀ àwọn ìjọba lágbáyé láti kojú Coronavirus

Oríṣun àwòrán, PAstor enoch adeboye
Pasitọ Enoch Adejare, oluṣọagutan agbafun ijọ Redeemed Christian Church of God , RCCG lagbaye ti sọ wi pe awọn igbesẹ ti ijọba n gbe lati wawọ arun Coronavirus bọlẹ lagbaye ati paapaa julọ lorilẹede Naijiria jẹ eyi to n pani lẹrin pupọpupọ.
Oluṣọaguntan Adeboye to ṣalaye ninu iwaasu rẹ to ṣe fun awọn ọmọ ijọ naa lagbaye lori ẹrọ ayelujara ati mohunmaworan ṣalaye pe oun ti paṣẹ fun gbogbo ẹka ijs naa lati tẹle aṣẹ ijsba lori pe ko gbọdọ si ipejọpọ ero to ba ju aadọta lọ kaakiri.
- Èèyàn kan láti ìpínlẹ Ọ̀yọ́ kún iye àwọn tó ní àrùn Corona Virus
- Ìjọba ti pápákọ̀ òfúrufú Eko àti Abuja pa nítorí coronavirus
- Aawakọ̀èrò, ọlọ́kadà farakásá àṣẹ ìjọba Ekiti láti dẹ́kun Coronavirus
- Báwo ni àrùn coronavirus ṣe ń wọ Nàìjíríà
- Àwọn ìbéèrè tó yẹ kí o bi ara a rẹ̀ kí ó tó gba ìròyìn kankan nípa coronavirus gbọ́
- Báwo ni o ṣe le mọ̀ pé o ní àrùn Coronavirus?
Amọṣa o ni nigba ti oun wo awọn igbesẹ ti ijsba gbe kalẹ bii pe ki awọn eeyan to ba ju aadọta lọ o maa korajọ pọ si oju kan naa fun ohunkohun, ẹrin fẹ maa pa oun bi o tilẹ jẹ wi pe ajalu ni nnkan to n ṣẹlẹ.
Baba Adeboye, gẹgẹ bi ọpọ eeyan lagbaye ṣe maa n pee ni ki ni ka ti pe tawọn ibudokọ gbogbo, ati awọn ọja nibi ti ero n pọ si.
Bakan naa lo ni ọgba ileewe wa lara awọn ibudo to dara lati wa julọ lasiko ajakalẹ arun bayii ṣugbọn ijọba ninu ọgbsn wọn le awọn akẹkọ kuro niblẹ wa sile nibi ti arun yi ti n gbilẹ.
Iranṣẹ Ọlọrun naa ni gbogbo eyi lo n mu ki ẹrin o maa pa eniyan lori igbesẹ awọn ijsba gbogbo.
"Fun apẹrẹ wọn ni ki a maa jinna si ara wa nitori kokoro arun yii, ṣugbọn nibi ti wọn ti n sọ ọ gan ni mo ti n ri awọn minisita ti wọn n joko sun mọ ara wọn pẹkipẹki."
O wa beere pe ki ni ijọba yoo ṣe si awọn ibudo bii ọgba ẹwọn? ṣe wọn yoo ni ki wọn maa lọ si ile bii ti awọn orilẹede kan nii?
O fi kun pe gbogbo agbaye ni yoo gba isinmi lẹnu iṣẹ nitori arun coronavirus yii, nitori naa ki gbogbo awọn smọ ijọ naa o maa gbadun isinmui lẹnu iṣẹ ti Ọlọrun fun wọn.
Ẹwẹ o ṣalaye pe, bi iku ti arun Coronavirus ti mu wa yii ṣe pọ to ti o si bani ninu jẹ, sibẹ ko to iye ẹmi ti aisan iba ati ijamba mọto ti mu lọ laarin oṣu mẹta akọkọ ninu ọdun 2020.
O ni ohun to jẹ ki orukọ arun coronavirus o gbode kan ni pe, 'aisan alariwo'ni.
O ni arun coronavirus ko lee parẹ mọ laye, o kan lee wawọ lọ silẹ bi awọn aṣiwaju rẹ bii Ebola ni ati pe ẹrin gbaa lawọn wolii kan to n sọ pe ọjọ bayii ni arun naa yoo parẹ n pa oun.














