International flights resumption: Bàálù ilẹ̀ òkèèrè bà l'Abuja léyìn ìṣéde oṣù márùn ún coronavirus

Oríṣun àwòrán, others
Lẹyin ti irin ajo ọkọ ofurufu silẹ okeere gberasọ pada ni Naijiria, baalu Ethiopia Airline lo kọkọ ba silu Abuja lati Addis Ababa, Ethiopia.
Oṣu marun un gbako ni ko fi si lilọ bibọ ọkọ ofurufu lati ilẹ okeere sí Naijiria ati lati Naijiria sí oke okun nitori iṣede coronavirus.
Ni deedee aago kan aabọ kọja iṣẹju marun un ni baalu naa ba l'Abuja lọjọ Aje.

Oríṣun àwòrán, others
Aago mejila ọsan ló yẹ ki baalu naa ba ni Abuja tẹlẹ, amọ awọn ero kan ti ko tete sanwo fun ayẹwo coronavirus ti wọn ba ti de Naijiria lo da a duro.
Ẹgbẹrun un mejilelogoji ati aabọ naira(N42,500) lawọn ẹro gbọdọ san gẹgẹ bi owo ayẹwo fun covid-19 ti wọn ba de Naijiria eleyi ti ọpọ wọn koro oju sí.
Ọkunrin kan to de lati UK, Joe Ogwu bu ẹnu atẹ lu sisan owo naa.
Ọgbẹni Ogwu sọ pe ọfẹ ní ìjọba UK n ṣe iru ayẹwo bẹẹ fawọn arinrinajo.
O ni ohun to buru julọ ni pe ko si ohun kan lati fi ṣe afihan pe awọn ero ti san N42,500 fun ayẹwo naa.
Ẹwẹ, ọga agba ileeṣẹ ọkọ ofurufu ni Naijiria (FAAN), Rabiu Yadudu sọ pe lilọ bibọ baalu silẹ okeere to gberasọ pada ni Naijiria tẹ oun lọrun.
- Wo àwọn ìlànà tuntun ti o gbọdọ tẹlèé rèé ki ó to le wọkọ̀ òfurufú lọ sókè òkun
- Ọmọ Ààrẹ lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ìgbéyàwó yálà àwọn ará ìlú fẹ́ràn ìjọba bàbá rẹ̀ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́ - Aisha Buhari
- Ó yẹ kí Buhari dá owó epo padà sí ₦97 tàbí kó kọ̀wé fipò sílẹ̀ - Àwọn akẹ́kọ̀ọ́
- Àbá àpérò 2014 CONFAB lojútùú sí àtúnṣe ìwé òfin Nàìjíríà- Afenifere sáwọn sẹ́nẹ́tọ̀

Wo àwọn orilẹ́èdè àgbáyé tó ti sí pápákọ̀ òfurufú wọn fún ìrìnàjò
Àwọn orílẹ̀èdè to le wọ bàálù lọ lókè òkun
Ọpọlọpọ awọn eniyan lo ti n beere igba ti Naijiria yoo si papakọ ofurufu fun irinajo lati orilẹede Naijiria lọ si oke okun.
Amọ ọjọ Kẹjọ, oṣu Keje, ọdun 2020 ni wọn si papakọ ofurufu ti ilu Abuja ati Eko fun irinajo labẹle.
Awọn arinrinajo ni anfaani lati lo papakọ ofurufu naa, lẹyin to ti wa ni titi pa fun oṣu mẹta lati dẹkun itankalẹ arun Coronavirus.
Nipa ti irinajo si okeere, adari ajọ irinna ofurufu ni Naijiria, Sam Adurogboye salaye pe, awọn si n duro de abọ awọn eleto ilera ati ajọ amuṣẹya, ti aarẹ Buhari gbekalẹ, lati koju arun Coronavirus.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìtàn ayé Henry Fajemirokun, olówó tó fi owó mọ Olúwa àti ènìyàn
- N kò gba ₦4bn lọ́wọ́ Magu, ẹ má ró àjẹbánu mọ́ mi láṣọ - Osinbajo pariwo
- Àṣírí tú! Ẹ̀rọ ayàwòrán ara ọlọ́pàá fihàn pé ìgbà ogún ni George Floyd pariwo, kó tó kú
- Iléesẹ́ rẹ́kọ́ọ̀dù tí mo ti bẹ̀bẹ̀ láti kọrin, padà di tèmi lónìí - Ebenezer Obey
- Èyí kò wa pọ̀ jù, kí ló ń pa ọ̀pọ̀ dókítà ní Ondo báyìí?
- Ọ̀pá epo NNPC bú gbàmú ní Benin, òṣìṣẹ́ méje kàgbákò ikú òjijì
- Ọ̀fọ̀ ńlá ṣẹ̀ ní Ivory Coast, Olóòtú ìjọba, Amadou Gon Coulibaly jáde láye
- Tó o bá fẹ́ wọ bàálù lásìkò yìí, wo òfin tuntun tó tẹ̀lé
Adurogboye fikun pe, awọn ko tii da ọjọ ti wọn yoo si papakọ ofurufu naa, nitori ọpọlọpọ nnkan lo rọ mọ igbesẹ naa.
Adari ajọ irinna ofurufu ni Naijiria, Sam Adurogboye fikun pe, awọn orilẹede miran to si papakọ wọn, lai tẹle ofin to n dẹkun itankalẹ arun Coronavirus, sakiyesi pe arun naa n peleke si.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn orilẹede re e ti wọn ti ṣi papakọ ofurufu wọn fun irinajo si orilẹede miran:
Yuroopu:
Ọjọ Kini, Oṣu Keje ni wọn ṣi papakọ wọn fun awọn arinrinajo lati orilẹede marundinlogun, eleyii ti Canada, Morocco ati Australia wa lara wọn,
Amọ wọn ko fun orilẹede Naijiria, Amerika, Brazil ati Russia laaye lati wọle sọdọ wọn.
Greece:
Orilẹede Greece naa si papakọ ofurufu rẹ fun awọn arinrinajo, amọ wọn ko fun orilẹede Amerika, Brazil ati Russia ni anfaani lati wọ ibẹ nitori arun Coronavirus.
Spain ati Portugal:
Orilẹede mejeeji ṣi ibode wọn lẹyin ọpọlọpọ oṣu nitori arun Coronavirus.
Jamaica ati awọn orilẹede to wa ni agbegbe Caribbean:
Awọn orilẹede bii Antigua, Saint Lucia ati agbegbe U.S. Virgin Island si papakọ ofurufu wọn ni Oṣu Kẹfa.
Egypt to ṣi ni ibẹrẹ Oṣu Keje sọ pe awọn eniyan gbọdọ ni iwe eto ilẹra ti wọn yoo fihan awọn oṣiṣẹ ajọ aṣọbọde ni papakọ ofurufu.
Turkey:
Minisita fun eto igbafẹ lorilẹede naa sọ wi pe, awọn yoo ṣi gbogbo ile iṣẹ eto igbafẹ lorilẹede naa lati Oṣu Keje, amọ awọn arinrinajo lati Germany nikan lo le wọle.
Dubai (UAE) n reti ẹni to ba fẹ wọle si orilẹede wọn lati Ọjọ Keje, Oṣu Keje, lati ri pe wọn mu iwe to fihan pe, wọn ko ni arun Coronavirus dani wa.
Dominican Republic fi lede pe awọn arinrinajo gbọdọ ni kaadi eto ilera ti wọn yoo fihan awọn ẹsọ aṣọbode bi wọn ba ṣe n wọ orilẹede wọn lati Ọjọ Keji, Oṣu Keje.
Haiti ni ti wọn sọ wi pe, awọn arinrinajo naa gbọdọ ni iwe ilera lati wọ orilẹede wọn, eleyii ti wọn yoo fihan awọn ẹṣọ aṣọbode lati Ọgbọnjọ, Oṣu Kẹfa.
Nitori naa ti Naijiria ba fẹ si ibode wọn, wọn gbọdọ ri pe gbogbo eto wa nilẹ lati dẹkun itankalẹ arun Coronavirus.
Tó o bá fẹ́ wọ bàálù lásìkò yìí, wo òfin tuntun tó tẹ̀lé

Nibayii ti awọn papakọ ofurufu ilu Eko ati Abuja ti bẹrẹ si ni gbe ero pada, o tọ ki a fi diẹ lara awọn ilana to de irina lawọn papakọ ofurufu yii to ara wa leti.
Ilana ti a n sọ wọn yi nii se pẹlu bi awọn arinrinajo yoo ti se ma se nibẹ, ṣaaju ki wọn to wọ inu baalu ati nigba ti wọn ba ti wọ inu rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìtàn ayé Henry Fajemirokun, olówó tó fi owó mọ Olúwa àti ènìyàn
- Ọwọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oyo ti tẹ àwọn aṣekúpani tó ń ṣọṣẹ́ ní Akinyele
- Ìpínlẹ̀ Eko kéde ọ̀nà àbáyọ sí súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀ lásìkò àtúnṣe afárá Third Mainland
- Wo ìgbẹ́sẹ̀ méjọ tí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ gbọdọ̀ tẹ̀lé láti yọ igbákejì gómìnà
- Ilé aṣofin Ondo fọwọ́ òsì júwe ilé fún aṣòfin mẹ́ta pé wọ́n tàpá sí òfin ilé
Diẹ ree lara awọn ilana ti ajọ to n ṣe amojuto awọn papakọ ni Naijiria, FAAN,gbe kalẹ.
O kere tan o ni lati de papakọ ofurufu ni wakati mẹta ṣaaju ki baalu rẹ to gbera
O ni lati tẹle ilana ijinasiraẹni nipa diduro lori awọn aaye ti wan ti ṣe ami si ti awọn oṣiṣẹ ilera yoo si yẹ bi ara rẹ ti ṣe gbona si
Ti ara rẹ ko ba gbona pupọ, wọn ma ni ki o tẹsiwaju lati lo ọṣẹ ifọwọ lẹyin ti wa lọ gba iyọnda lati wọ baalu
Ti ara rẹ ba gbona ju bo ti ṣe yẹ lọ, wọn ma da ẹ pada tabi ki wọn fi ọkọ agbe alaarẹ gbe ọ kuro ni kiakia

Oríṣun àwòrán, FAAN
Ri wi pe awọn aaye ti wọn ṣami si ni o duro si
Bi o ba ti wọ inu ọkọ ti yoo gbe yin lọ sinu baalu, joko sọtọ si awọn ti ẹ ba jijọ wọ ọkọ
Ki ẹ to wọ inu baalu,ri wi pe o jina si ẹni to wa ni iwaju rẹ
Ri wi pe ẹni to fẹ wọ baalu ṣaaju rẹ wọle tan ki o to wọle
Ninu baalu wọn ko ni fun yin lounjẹ kankan bi tatẹyinwa
Ri wi pe o fi aaye ijoko to wa laarin kalẹ laarin iwọ ati ẹlomiiran

Wọn yoo fi omi kalẹ si aye ijoko to wa niwaju rẹ ki o ba le muu fun ara rẹ
O gbọdọ wọ ibomu lopin igba to ba wa ninu baalu
Ti baalu ba ti balẹ,ri wi pe o dide lati gbe ẹru rẹ lẹyin ti ẹni to wa niwaju rẹ ba ti gbe ẹru rẹ sọkalẹ
Aaye ibi ti wọn ṣe ami si ni ko gba lati lọ gba ẹru rẹ

Duro si oju ibi ti wọn ṣe ami si lati gbe ẹru rẹ
Ti o ba ti gbe baagi rẹ tan, to sẹyin awọn to wa niwaju rẹ ki awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọkọ ofurufu baa le ṣe ayẹwo ẹru rẹ boya iwọ lo ni lootọ.
Nǹkan tí ojú rí rè é bí pápákọ̀ òfurufú ṣe di ṣíṣí padà ní Nàìjíríà
Oni ọjọ kẹjọ, oṣu Keje, ni irinajo oju ofurufu labẹle yoo bẹrẹ pada ni Naijiria.
Awọn papakọ ofurufu bi i ti ilu Eko, ati Abuja ni yoo kọkọ bẹrẹ iṣẹ, ko to o kan awọn ilu yooku.
Ṣugbọn ṣa, abẹwo ti BBC ṣe si papakọ ofurufu ni owurọ kutukutu ọjọ kẹjọ, oṣu Keje, fihan pe, nkan ko lọ leto-leto.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ṣé lóòtọ́ ni Lateef Adedimeji àti Adebimpe Oyebade ṣe ìgbéyàwó?
- Kòṣẹlẹ̀rí ni Hajj ọdún 2020, wo ìyàtọ̀ tó wà nínú rẹ̀ sí ti tẹ́lẹ̀
- Ẹ̀yin ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn tẹ fẹ́ ṣe àjọ̀dún lónìí, lákọ la ń dúró dè yín - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
- Ìjọba Akeredolu kò ní omi àánú lójú, a kò tọ́jú alárùn Coronavirus mọ́ - Dókítá Ondo
- Bí àwọn adarí ìjọba ṣe ń kó Coronavirus, ń kọ wá lóminú - Ìjọba àpapọ̀

Oríṣun àwòrán, Others
Ṣaaju ki awọn papakọ ọkọ ofurufu o to o di ṣiṣi pada, ajọ to n ṣe amojuto awọn papakọ ni Naijiria, FAAN, kede pe, ki awọn arinrinajo ti pe si papakọ, o kere tan, wakati mẹta ṣaaju akoko ti baalu wọn yoo gbera.
Eyi tumọ si pe, ẹni ti yoo ba rinrinajo laago meje owurọ, ti gbọdọ de si papakọ laago mẹrin idaji.
Aago meje owurọ lo yẹ ki baalu akọkọ o gbera lati ilu Eko si Abuja, ṣugbọn, akọroyin BBC ri i pe, wọn ko ti ẹ ti i ṣe ilẹkun papakọ laago maarun owurọ.
Eyi si tumọ si pe, oju titi to wọ inu papakọ ni awọn arinrinajo duro si. Koda, ko yọ awọn ọkọ silẹ.
- Eji Gbadero, ọmọ Ibadan àti jayé-jayé ọmọ ónílẹ̀ ti wọn yẹgi fun l'Eko
- Lisabi Agbongbo Akala rèé, ẹni tó fi ìfẹ́, ìṣọ̀kan àti ìrẹ́pọ̀ gba ilẹ̀ Ẹ̀gbá lọ́wọ́ ìmúnisìn
- A jọ ṣe ìyàwó pọ̀, a jọ bímọ ní ọjọ́ kan náà, a tún jọ máa ń ṣàìsàn pọ̀ ni
- Ìyàwó mi fẹ́ràn ìrìnàjò òfurufú ni mo ṣe kọ́ ilé Bàálù yìí fún un
- Omi ìṣẹ̀ńbáyé tó ń dà ní Ówù rèé, èyí tó ga jùlọ ní Afirika
Awọn arinrinajo to ba akọroyin BBC Yoruba sọrọ sọ pe, dide si papakọ ọkọ ofurufu ni wakati mẹta ṣaaju irinajo, ko rọrun.
Ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹta nijọba ti awọn papakọ ọkọ ofurufu ni Naijiria, nitori itankalẹ aarun Covid-19.
Ìjọba ti pápákọ̀ òfúrufú Eko àti Abuja pa láti dènà àrùn coronavirus nípasẹ̀ wọléwọ̀de
Ina ti jo dori koko bayii lori ọrọ ajakalẹ arun coronavirus lorilẹede Naijiria, ajọ to n ri si igbokegbodo ọkọ ofurufu, NCAA ti kede pe papakọ ofurufu ilu Eko ati Abuja yoo di titi pa lọna ọjọ Aje, ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹta yii.
Oṣu kan gbakako lawọn papakọ ofurufu mejeeji naa yoo fi wa ni titi pa.
Mínísita fun ọ̀rọ̀ irinajo ofurufu Hadi Sirika, ti kọkọ sọrọ naa tẹlẹ pe ìjọba yóò gbé papakọ ofurufu mejeeji pa.
- Èèyàn mẹ́wàá míràn kó àrùn Coronavirus ní Nàìjíríà
- Aawakọ̀èrò, ọlọ́kadà farakásá àṣẹ ìjọba Ekiti láti dẹ́kun Coronavirus
- Àwọn ìbéèrè tó yẹ kí o bi ara a rẹ̀ kí ó tó gba ìròyìn kankan nípa coronavirus gbọ́
- Kò tíì sí àrùn Coronavirus ní ìpínlẹ̀ Oyo, a ṣi ń retí èsì àyẹ̀wò - Ijọba Oyo
- Ṣé ẹ̀yin mọ idí ti Abass Akande fi n jẹ Obesere?
- Ìjọba àpapọ̀ fi Austria, Sweden kún àwọn orílẹ̀èdè tí kò lè wọ Nàìjíríà
- Ogun ebi ni Nàìjíríà ń bá fínra lọ́wọ́, ogun coronavirus kò gbọdọ̀ kún un-Oluwo
- Èyí làwọn ayẹyẹ nlá tí kò ní wáyé nítorí coronavirus
Ajọ NACAA ni igbesẹ yii jẹ ọkan lara ọna lati dekun itankalẹ arun coronavirus lorilẹede Naijiria.
Amọ ajọ naa sọ pe iṣẹlẹ pajawiri tabi iṣẹ pataki nikan lo le mu ki baalu fo tabi ba lawọn papakọ ofurufu naa.
Lasiko to n ba awọn akọròyìn, ilé ijọba sọ̀rọ̀, lẹ́yìn ìpàdé pẹlú ààrẹ Buhari, Sirika ni, àwọn yóò dẹkun itankalẹ ajakalẹ ààrun Coronavirus.

Oríṣun àwòrán, Other
Sirika jẹ ọkan lara ọmo igbimọ amúṣẹsẹ lori COVID-19 nigba ti Boss Mustapha to jẹ akọwé ijoba apapọ jẹ́ alaga wọ́n.
O ti di eeyan mejilelogun bayii to ti lugbadi arun coronavirus ni Naijiria, amọ ọmọ ilẹ Italy to kọkọ ko arun naa wọ Naijiria ti gbadun bayii, o si ti kuru ni ile iwosan.
Ẹ̀wẹ̀ ìjọba ti fi orilẹ̀-èdè Sweden àti Austgria si àra àwọn orilẹ̀-èdè ti wọ́n ti fi ofin de láti ma wọ Naijiria mọ.
Ní bayìí, orilẹ̀-èdè mẹẹdogun ni wọ́n ti fi ofin de láti ma wọ Naijira mọ















