Ṣé ẹ̀yin mọ idí ti Abass Akande fi n jẹ Obesere?

Obesere olorin

Oríṣun àwòrán, Obesere

Àkọlé àwòrán, Ṣé ẹ̀yin mọ idí ti Abass Akande fi n jẹ Obesere?
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Lórí ìfọ̀rọ̀wérọ to wáye níle iṣẹ́ BBC News Yoruba lonii pẹlú Abass Akande loti sàlaye oníruuru nipa àra rẹ àti iṣẹ́ orin to yàn láàyò.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ Abass Akande sàlayé ìdí ti oun fi n jẹ Obesere ti gbogbo ènìyàn n pe oun lọ́nìí, o ní èyi kìí ṣe orukọ abísọ ti iyá àti bàbá sọ oun o, sùgbọ́n lásìkò ere ori náà ni oun gba orukọ náà.

Gẹ́gẹ́ bo ṣe sọ oni aluṣẹkẹrẹ oun lágbo ere lo n jẹ orúkọ náà, sùgbọ́n ko nífẹ si orúkọ náà o si maa n bá àwọn èni[yàn ja nítori rẹ.

Àkọlé fídíò, Peter Fatomilola ní àìsí ẹ̀kọ́ ń mú káwọn òṣèré tíátà ó máá ṣe oun tí kò tọ́.

Lẹ́yin o rẹyin, ti mo ri pé ọmọ náà ko nifẹ si orukọ "Obesere" ni mo ba fi kọrin pe ẹmi ni mo n jẹ bẹẹ, botilẹ̀ jẹ́ pé mo tun fi igba kan gbé orukọ náà jù sílẹ̀ nígba ti o mú awuyewuye dáni pé àwọn obinrin ni mo n fi orin náà bu"

Ẹ̀yin o rẹyin, gbogbo aye gba orúkọ náà ti o si di ilú mọọka ti gbogbo ènìyàn n pariwo lónìí.

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

Lori ipo ti Naijira de dúro lonìí, Obesere sàlayhe pe botill jẹ pe ìjọba o ṣe nkan ti ilú n fẹ, o ṣe pataki láti maa fi adura ran wọ́n lọ́wọ́.

O ní ti gbogbo ènìyàn ba le gbáradì láti gbadura ati ààwẹ fun orilẹ̀-èdè yìí, Ọlọrun yóò boju wolẹ̀ láti Ọrun yóò si gbọ ẹbẹ̀ àdura ti yoò mu ki ilú rojú ki o ráye, ti gbogbo nkan yóò si maa lọ dede.

Abasido fi kún pé, gẹ́gẹ́ bi ọlọdan ni o ṣe pataki láti nawọ ìrànwọ si ijọba náà lori àwọn nàkan kan , nítori ijọba nikan ko le dá gbogbo rẹ ṣe.

O ni lai si ìrànlọ́wọ́ ará ilú, ijọba Naijiria ko le ri ilú tò, iranwọ ara ilú ni àwọn oyinbo fi n rọ́wọ́ mú, tori pe to ba jẹ ti ẹsẹ ni, àwọn oyinbo n dẹsẹ ju Naijiria lọ.

O ní ọ̀pọ̀ àwọn oṣere kéèké aye ode oni ni oun ti ba kọ́wọ́ pọ la'ti ṣe àwo orin jáde àti pe àànu ọlọrun ni oun ri gba ti o si fi jẹ ẹni ti aye n fẹ titi di àsìkò yìí láti igbà ti oun ti bẹrẹ orin.