Oluwo ti Iwo: N kò ni nkan kan sọ lórí fídíò to gba ayélujára kan pé mo ń we igbó, ẹ mú ẹnu kúrò nibẹ

Oríṣun àwòrán, oluwo of iwo
Oluwo tilu Iwo, Oba Abdul Rasheed Adewale Akanbi, Telu Kínní, tí kéde pé ẹẹmẹta laarin ọ̀sẹ̀ kan ni òun ń fún àwọn ará ìlú Iwo tí ebi ń pá ni oúnjẹ èyí tó bẹ̀rẹ̀ ni ọdún mẹrin sẹ́yìn.Ọba Akanbi, lásìkò to ń bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀ ni òun tún máa ń wọ agboolé lọ n'ilu Iwo láti fún àwọn arúgbó tí kò leè jáde nílé ní oúnjẹ.O ni òun gẹ́gẹ́ bí ọba ìlú, òun kò leè là ojú ṣílẹ̀, kí àwọn ọmọ òun máa kú ní oju òun, ó ní bí èyí bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ pe ìgbà òun kò dára lórí òye nuu.
Ọba Akanbi ni, òun kò gbà nkankan lọ́wọ́ aráàlú n'ilu iwo, àmọ́ òun ń lọ ṣíṣẹ wá fún wọn láti tọju wọn ni, torí òun gan ni ẹrú aráàlú, òun sì máa ń ṣe aráàlú Iwo bíi ọba ní."Èmi kii pá aago ìbánisọ̀rọ̀ mi, igbakuugba táwọn aráàlú bá sì pé mi, ní wọn máa ń rí mi bá sọ̀rọ̀, mo sì leè fọwọ́ gbaya pé, kò sí aráàlú Iwo tí kò ní nọ́mbà ẹ̀rọ ibaraẹnisọrọ mi lọ́wọ́"Bákan ni Ọba Akanbi ni ìjọba nìkan kò leè dá gbé ẹrù ìpèsè oúnjẹ fún aráàlú, kódà, ìjọba Ìpínlẹ̀ Osun kò leè dá gbé ẹrù oúnjẹ fún àwọn èèyàn ìlú Iwo nìkan, nitori naa, o yẹ ki aráàlú dìde lásìkò yìí, láti ran ìjọba lọ́wọ́.Oluwo fikùn pé òun wà nínú ogún Liberia lọ́dún 1989, tí òun sì ti dé ẹnu ikú ni igba mẹ́jọ, bẹ́ẹ̀ si ni àkókò ogun aifojuri là wá yìí, to jọ tí ogun ìbọn.

- Coronavirus: Àwọn ohun tí a kò tíì mọ̀ nípa àrùn Covid-19
- Kí lo mọ̀ nípa fẹntilétọ̀, ohun èlò aṣèrànwọ́ èémí
- Ṣé òògùn Chloroquine lè dènà ààrùn Coronavirus bí?
- Coronavirus tún ti ṣe ọṣẹ́ lórí iṣẹ́ líla ojú ọ̀nà relùwe láti Eko sí Ibadan - Ìjọba àpapọ̀
- Àrùn Coronavirus fa'lẹ̀ya láwọn ìletò aláwọ̀dúdú ní Amẹ́ríkà

"Nígbà ogun, gbogbo aráàlú máa ń kó ohun tí wọ́n bá ní síta ni. Ohun to sí wa de yii, ki awon olowo àti oloro kò owó wọn síta ni lati rán aráàlú lọ́wọ́, gbogbo àwọn èèyàn ti ko si leè lọ sí Mecca lọ́dún yìí, ní kí wọn kò owó wọn
kalẹ fún ìjọba, mo sì ń rọ àwọn aráàlú láti fi idi mọle wọn."
Oluwo wá ṣe sadankata si ìjọba Ìpínlẹ̀ Osun fun bo ṣe kogiri mọ igbogun tí àrùn Covid-19, ó si tún woye pe, ẹsẹ̀ lo fà ajakalẹ àrùn yìí.
" Ojojumo là ń fi ara wa se oogun owó, a ń fi ojú rí apá àti ẹsẹ, tó fi mọ orí èèyàn nigboro, táwọn ọmọ Badoo sì ń fọ orí àwọn èèyàn kiri, èyí tí kò dun mọ Ọlọ́run nínú."

Oríṣun àwòrán, oluwo of iwo
Ọba Akanbi ni isẹ ti ń lọ láti ṣe agbelaruge àwọn aṣọ ìbílẹ̀ wá, èyí tí yóò fara jọ 'Jeans' oloyinbo, tí yóò sì tún wúlò fún wa lásìkò yìí tí ìlú Oyinbo kò ṣeé lọ fún wa mọ.
Nígbà tó ń dáhùn ìbéèrè lórí fìdío kan tó jáde sórí ayelujara laipẹ yii, ti ẹnikan tí ojú rẹ jọ tí ọba Akanbi tí ń we igbó, Oluwo ni òun kò ní ohunkóhun sọ lori rẹ, kí wọn mú ẹnu kúrò lórí ọ̀rọ̀ náà ni torí òun kò mọ ohun kohun nípa
rẹ.
Oluwo ni àṣà Yoruba lo dára julọ, àmọ́ àwọn ohun tí kò bá dára, ó yẹ ká mú kuro ninu rẹ. Ó ní fún àpẹẹrẹ ila kíkọ kò bá ìgbà mú mọ, tó fi mọ sise oogun owó àti lilo ẹ̀yà ara èèyàn fún òrìṣà bíbọ nítorí gbogbo ohun tó bá ń mú
ẹ̀mí lọ kò dára, ó yẹ ká mú kúrò nínú àṣà wá.

Oríṣun àwòrán, oluwo
Nígbà tó ń ṣàlàyé ìdí tó fi sọ ọmọ rẹ ni Odùduwà, Oluwo ni kí ló burú nínú kí èèyàn sọ ọmọ rẹ ni orúkọ Baba ńlá rẹ, o ni, ohun tó dára gbaa ni.
Nígbà tó ń fèsì lórí ìbéèrè pé ìgbà wo ni olori tuntun yóò wọ ààfin rẹ lẹ́yìn tí aya rẹ tí kúrò ní ààfin, Oluwo ni àìmọye ọba míì tí wá nílẹ Yoruba ti wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ ń wá ìyàwó, nígbà tó sì yá, wọn si ri ìyàwó, ó fikùn pé, kí àwọn èèyàn
dúró de ìgbà tí Ọlọ́run bá yàn fún òun.
Lórí ibasepọ to wá laarin Oluwo àti Ọọni tilu ilé Ilé-Ifẹ̀, Oluwo ni ibasepọ àwọn gùn régé pupọ, to sì tun tọ ipàṣẹ orírun àwọn ìdílé to ń jọba n'ilu Iwo lọ sí Ilé-Ifè nítorí Ooni obìnrin Luwoo Gbagida to wá láti agboolé Lafogido
n'ilu Ilé-Ifè.
Oluwo wá ṣe ikilọ pé arun Coronavirus kò gbọ́dọ̀ gbilẹ ni Nàìjíríà gẹgẹ bo se n pa wọn nílẹ òkèèrè, tó sì rọ àwọn èèyàn láti mase máa yọjú síta kiri àmọ́ kí wọn joko sílè koowa wọn.
Oluwo tún kesi àwọn ọmọ Naijiria lati fara dà ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí nítorí kò sí epo rọbi mọ ní Nàìjíríà.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ọpọ ọrọ kobakungbe tí àwọn èèyàn kan ń sọ nípa rẹ lórí ayélujára, Oluwo ni òun ń sanwó òkìkí ni ọ̀rọ̀ òun ti wọn n sọ, ẹni tó bá sì wà ipò, ó di dandan kí wọn sọ̀rọ̀ rẹ.
Oluwo wá gba àwọn Mùsùlùmí to bẹ̀rẹ̀ aawẹ Ramadan nímọ̀ràn, láti kó owó síta fún àwọn aláìní, pàápàá àwọn èèyàn tó fẹ́ lọ sí Mecca, tí wọn kò leè lọ mọ.
Oluwo ni òun kò fẹ́ kí àwọn èèyàn kú tàbí máa sunkún, òun sì ń fẹ́ kí Ọlọ́run mú ẹ̀mí oun lati kò Coronavirus kúrò nílẹ nítorí òun kò fẹ́ káwọn aráàlú máa kú báyìí.
Coronavirus: Oluwo ké sáwọn ọmọ Nàìjíríà láti mú ètò ìmọ́tótó lọ́kúnkúndùn lásìkò coronavirus yìí
Pẹlu bi ọwọja arun Coronavirus ṣe n gbilẹ kaakiri agbaye bayii, Oluwo ti ilẹ Iwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi Telu I ti ke sawọn ọmọ Naijiria lati rii pe wọn tẹle gbogbo ilana to yẹ lati daabo bo ara wọn lọwọ itankalẹ arun naa.
Ninu fidio kan eyi to fi ṣọwọ si BBC News Yoruba, Oluwo ti ilu Iwo rọ gbogbo awọn muslumi lati maṣe lọ si Mọṣalaṣi fun irun Jimọ ni ọjọ Ẹti.
- Báwo ni o ṣe le mọ̀ pé o ní àrùn Coronavirus?
- Ẹgbẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi kéde àdúrà nítórí àrùn Coronavirus
- Àwọn ọmọ Nàìjíríà ń kérora àdánù tí àṣẹ ìjọba tó wọ́gilé ìrìnàjò láti òké òun mú bá wọn
- Ilé ẹjọ́ dá pásítọ̀ ìjọ Sotitobire padà sọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ó sún ẹjọ́ síwájú
- Coronavirus:Ọmọ mi to ṣẹ̀sẹ̀ dé láti UK ko fi àmi Coronavirus han, sùgbọ́n....
- Ṣé òògùn Chloroquine lè dènà ààrùn Coronavirus bí?
Bakan naa lo tun rọ awọn ọmọlẹyin Kristi lati joko sile wọn lọjọ Aiku ki wọn si jina si ile ijọsin wọn gbogbo.
Ọba Akanbi ṣalaye wi pe koda ilẹ Mẹka nibi ti awọn Musulumi maa n rinrinajo mims lọ pẹlu ti se ilẹkun wọn pa ti wọn si ti ni ko saye lọwọ yii.
Oluwo ni gbogbo ọmọ Naijiria lo ni ojuṣe lati rii pe arun naa ko gbilẹ lorilẹede Naijiria gẹgẹ bi o ti ṣẹ lawọn orilẹede kan lagbaye.
Ninu ọrọ rẹ, ogun ebi lawọn ọmọ orilẹede Naijiria ṣi n ba ja bayii, ko si daju pe orilẹede yii yoo lagbara lati koju ogun arun Coronavirus bi o ba di tọrọ fọnkale.
Bakan naa lo ke ke gbajare sita pe oun ko ṣetan ati gbalejo kankan lasiko yii nitori pe ilana ati daabo bo ara ẹni kan oun naa gẹgẹ bi Ọba.
O ni gbogbo ẹru ẹbun ti ẹnikẹni lee ni lọwọ lati fun oun ki wọn fi sọwọ lọ gbe ile wọn naa titi di igba ti arun naa yoo dẹkun.














