Coronavirus:Ọmọ mi to ṣẹ̀sẹ̀ dé láti UK ko fi àmi Coronavirus han, sùgbọ́n....

Oríṣun àwòrán, Aisha
Aya ààrẹ Naijiria Aisha Buhari ni ọmọ oun náà ṣẹṣẹ ti ilẹ̀ Amẹrika de ni àti pé, ìlànà ti ìjọba là silẹ̀ lati ri dáju pé ẹni to ba ti irin ahjò dé láti àwọn iríll-èdè ti ààrun náà n ba fira jùlọ ki wan ma wà ni ìgbélé.
Bótilẹ̀ jẹ́ pé Aisha Buhari ni kii ṣe pe ọmọ òun ni àpẹrẹ pé òun ni ààrun náà, sùgbọ́n àwọn kan gbọdọ tẹ̀lé òfin ti mínísita fi ilera àti NCDC là silẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Aya ààrẹ wá rọ gbogbo obí láti tọ ipasẹ ti òun tọ nítori pe ìgbọ̀ran sa ju ọ̀rá àgbò lọ.
O ni sáàju àsìkò yìí ni òun ti gbe ilẹ̀kun ofí'si oun ti ni nkan bi ọ̀ṣẹ̀ meji sẹyin ti oun si ti paṣẹ fun àwọn òṣìṣẹ́ to ba pọ́ndandan láti maa ṣiṣẹ́ láti ilé.
Bakan náà ni o gbé oriyin fún ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara ati Niger fun ìgbésẹ̀ weọ́n lati fokun so àjàkálẹ̀ ààrun COVID19.
O dúpẹ lọ́wọ ọmọ Naijira bákan náà lo gbadura pé àsìkò yìí yóò ré kọja ti a ba tèlé àwọn alasill ìjọba
Coronavirus: Ọmọ ilẹ̀ Amẹrika kú sí Ekiti

Oríṣun àwòrán, Ekiti state government
Pẹlu bi arun Coronavirus ṣe fẹ sọ ara rẹ di tọrọ fọnkale bayii lorilẹede Naijiria, ipinlẹ Ekiti naa ti ni ipin ninu rẹ bayii.
Atẹjade kan ti ijọba ipinlẹ Ekiti fi sita ṣalaye pe ọmọ ipinlẹ naa kan ti ko arun Coronavirus lẹyin to ni ajọṣepọ pẹlu ọmọ orilẹede Amẹrika kan to wọ orilẹede Naijiria ni ọjọ kẹta, oṣu kẹta ọdun 2020.
- Ẹyin ilé ìjọsìn, ẹ tilẹ̀kùn ṣọ́ọ̀ṣì àti mọ́ṣáláṣí yín láti dènà àrùn Coronavirus - ìjọba Eko
- Ẹ wo ohun tí baba Adeboye sọ lórí ọ̀rọ̀ Coronavirus
- Kí ni ìtumọ̀ Pelúpelú, ìlànà àkàsọ̀ ọba tó fa wàhálà l'ọ́balọ́ba l'Ekiti
- Nílé ijó Fẹla Anikulapo, àrùn Coronavirus dá fàájì dúró
- Wo àwọn irọ́ tí wọ́n ń pa fún ọ nípa àrùn Coronavirus
Arakunrin naa to jẹ awakọ fun ọmọ ilẹ Amẹrika naa, pẹlu arabinrin kan to jẹ olutọju fun un n lo ọsẹ meji ni ilu Ibadan ki wọn to tẹkọleti lọ si ilu Ado Ekiti nibi ti ọmọ orilẹede Amẹrika naa ti dubulẹ aisan to si ku. Amọṣa, ayẹwo awakọ rẹ pẹlu arabinrin olutọju rẹ fihan pe awakọ naa ti ko arun Coronavirus, ṣugbọn ayẹwo ti arabinrin naa fihan pe oun ko ni.
Kọmiṣọna feto ilera nipinlẹ Ekiti, Dokita Mojisọla Yaya Kọlade ṣalaye ninu atẹjade naa ṣalaye pe gbogbo ilana to yẹ ni titẹle ni wọn n tẹle gẹgẹ bi ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun lorilẹede Naijiria, NCDC ṣe laa kalẹ.
Ijọba ipinlẹ Ekiti ni ayẹwo tuntun yoo tun waye fun arabinrin olutọju ọmọ ilẹ Amẹrika naa latọdọ ajọ NCDC.
Arakunrin ọmọ Ekiti to ni aarun naa wa lara awọn marun un ti ijọba apapọ kede pe o ni aarun ọhun lọjọru.













