Coronavirus: Ẹ tilẹ̀kùn ṣọ́ọ̀ṣì àti mọ́ṣáláṣí yín tí èrò bá ju 50 lọ láti dẹ́kun Coronavirus - ìjọba Eko

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba ipinlẹ Eko ti gba awọn olori ẹlẹsin lamọran lati gbẹsẹ le apejọpọ ita gbangba ti awọn eeyan rẹ ba le ni aadọta lawọn ile ijọsin wọn.
Kọmiṣọna fun ọrọ abẹle, Anofiu Elegushi lo fi ọrọ naa lede lẹyin apero pẹlu awọn olori ẹlẹsin nipinlẹ naa.
Lara awọn to peju sibi ipade naa ni alaga ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi, CAN nipinlẹ Eko, Alexander bamgbola, Imamu agba ipinlẹ Eko Sheikh Suleiman Abou Nolla ati awọn olori ẹlẹ mii kaakiri ipinlẹ ọhun.
Kọmiṣona ọrọ to n lọ, Gbenga Omotoso sọ fun BBC pe bo tilẹ jẹ pe ijọba ipinlẹ Eko ko laṣẹ lati gbẹsẹle ipejọpọ awọn ẹlẹsin, amọran naa ṣe pataki lasikjo yii.
Lati igba ti arun Coronavirus ti bẹ silẹ nilu Wuhan lorilẹede China lọdun 2019, ọpọ orilẹede lagbaye ni arun naa ti rapala wọ, ilẹ Naijiria ko gbẹyin pẹlu.
Awọn orilẹde bi Kenya ati Somalia ti tilẹkun ibode rẹ mọ awọn eeyan lati ilẹ okere ti arun ọhun ti ṣọṣẹ julọ, bẹẹ lawọn orilẹede kan ti tilẹkun ile iwe atawọn ile ijọsin.









