Coronavirus: Àjọ NYSC ké ètò ìfinimọ̀ fáwọn àgùnbánirọ̀ kúrú nítorí Coronavirus

NYSC

Wọn ni ki oju maa ribi, ẹsẹ loogun rẹ.

Eyi lo difa fun ajọ agunbanirọ lorilẹede Naijiria, NYSC ti wọn sọ agadangodo si iloro gbogbo ibudo ifinimọle fawọn agunbanirọ kaakiri orilẹede Naijiria; iyẹn lẹyin ti wọn ti ni ki awọn agunbanirọ naa o maa lọ sibi ti wọn yoo ti ṣe isinruulu lẹyẹ o ṣọka.

Ajọ naa kede pe, ohun to fa igbesẹ yii ni arun Coronavirus to ti wa di tọrọ fọnkale yii eleyii to ti mu ki ijọba apapọ paapaa o wọgile idije ere idaraya apapọ orilẹede Naijiria, National Sports festival to yẹ ko waye nipinlẹ Edo lọdun yii.

Awon agunbanirọ

Oríṣun àwòrán, Nysc Edo State/facebook

Atẹjade to fi igbesẹ naa han sita jẹyọ loju opo facebook lowurọ Ọjọru.

Atẹjade naa fi kun un pekawọn agunbanirọ o lọ bẹrẹ isinruulu wọn lawọn ibudo ti wọn pin wọn si ati pe nigba ti nnkan ba ṣẹnuure, wọn yoo pe wọn pada.