Ekiti Oba Crisis: Ọọ̀ni ṣalàyé ìdí tí ààwọ̀ àwọn ọba Ekiti fi yàtọ̀ sí ti ẹ̀ẹ̀yà míràn

Oríṣun àwòrán, Ekiti state government
Ni ipo rẹ gẹgẹ bi Arole Oodua nibi ti igi gbogbo ọmọ kootu oo jiire bi ti ṣan jade wa, Ọọni ile ifẹ ti pana aawọ laarin awsn lọbalọba ni ipinlẹ Ekiti.
Ni ọjọ Aje ni Ọọni Adeyẹye Ogunwusi gunlẹ silu Ado Ekiti lati lọ igi alaafia laarin awọn ipele lọbalọba mọkanla ti a mọ si pelupelu ti wọn fariga pe awọn ko fara mọ igbesẹ gomina ipinlẹ naa, iyẹn Kayọde Fayẹmi lati yan Alawẹ ti ilu Ilawẹ Ekiti gẹgẹ bii olori igbimọ lọbalọba ni ipinlẹ naa.
- Àwọn ọba Yorùbá kan rèé tí wọ́n rọ̀ lóyè, tí ọba míràn jẹ lójú ayé wọn
- Ajá kìí rorò kó ṣọ́ ojú'lé méjì, kò tọ́ ọ́ sí Alaafin láti dásí ọ̀rọ̀ ọba l‘Ekiti - Peter Fatomilọla
- Ilé ẹjọ́ ti sún ìgbẹ́jọ́ pásítọ̀ Sotitobire si Ọjọ́bo̩
- Wọ́n gbé òkú ọgá iléẹ̀kọ́ àti òṣìṣẹ́ méjì míì tó kú nínú ìbúgbàmù lọ sílé ìgbókùsí ológun ojú omi l‘Eko
- Mo kó àrùn Coronavirus lẹ́yìn tí mo ṣalábapàdé ẹni tó ní àrùn náà lára - Idris Elba
- Oshiomole ṣì ni alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC - ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn
Bakan naa ni Ọọni ile ifẹ tun ṣepade pẹlu gomina ipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayẹmi lọna ati wojuutu sii iṣẹlẹ ọhun.
Gẹgẹ bi awọn itakun iroyin abẹle ṣe sọ, nigba ti ipade naa yoo fi pari, ẹrin ayọ lo gba ẹnu awọn ọbalade naa kan.

Oríṣun àwòrán, Ekiti state government
Ninu ọrọ to ba awọn oniroyin sọ lẹyin ipade naa, Ọọni Ogunwusi ṣalaye pe gbun-gbun-gbun gbogbo ti pari.
"Ọrọ laarin agboole oduduwa ni, a si ti yanju rẹ"
Bakan naa ni Ewi ti ilu Ado Ekiti, Ọba Rufus Adeyẹmọ Adejugbe pẹlu Ajero ti Ijero Ekiti, Ọba Adewọle Adebayọ ti wọn sọrs loruks awọn ọba pelu-pelu mọkanla yooku ni awọn ti panupọ lati fagile gbogbo ẹjọ to wa niwaju ile ẹjọ lori ọrọ naa.
Fayemi, lọ so ewé agbéjẹ́ mọ́wọ́ lórí ọ̀rọ̀ àwọn ọba Ekiti! Àwọn Mogaji Ibadan kìlọ̀

Oríṣun àwòrán, Ekiti state government
O ti to ọjọ mẹta kan bayi ti ọrọ aawọ awọn lọbalọba nipinlẹ Ekiti ti oruyeye ati iṣu ata yan-an yan-an.
Bi alara ti n da sii naa ni Ajero n da sii titi to fi kan Ọwarangun aga.
Ni bayii, awọn Mogaji ilẹ Ibadan naa ti kilọ fun Gomina Kayode Fayemi tipinlẹ Ekiti wi pe ko so ewe agbejẹ mọwọ lori igbesẹ rẹ lati rọ awọn ọba kan loye nipinlẹ ọhun.
Awọn Mogaji ilẹ Ibadan ti wa sọ fun Gomina Fayemi pe ko maa ko aṣa atọhunrinwa de ilẹ Yoruba.
Ninu atẹjade ti Oloye Wale Oladoja fi sita, awọn Mogaji sọ fun Fayemi pe ọdun mẹji nikan lo lanfaani lati lo gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Ekiti, ṣugbọn laelae ni ipo awọn lọbalọba.

Oríṣun àwòrán, Ekiti state government
Wọn ni ṣiṣe ayọjuran si ọrọ awọn lọbalọba ko le bimọ ire fun idagbasoke orililẹede Naijiria lapaapọ.
Awọn Mogaji Ibadan ni agba kii wa lọja, ki ọmọ tuntun wọ lọri jẹ fun awọn agbaagba ilẹ Yoruba.
Alaafin tilu Ọyọ, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi ti kọkọ kọ lẹta si gomina ipinlẹ Ekiti lori ọrọ naa pe ko maṣe foju ohun to ṣẹlẹ si Emir Kano wo ọrọ aawọ lọbalọba nipinlẹ Ekiti.
Amọ, Alawe ti ilu Ilawẹ Ekiti, Ọba Adebanji Ajibade Alabi, Afuntade Kinni, to ba BBC Yoruba sọrọ salaye pe ko si ohun to kan Alaafin ninu ọrọ naa, eyi to oun naa kọ lẹta si Gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde wi pe ko kilọ fun Alaafin lori ọrọ naa.
Laipẹ yii ni wọn fẹsun kan Gomina Fayemi pe o fẹ rọ Ewi of Ado-Ekiti, Oba Rufus Adejugbe loye atawọn ọba alaye mẹwaa mii ti ọpọ mọ si awọn Ọba Pelupelu.












