Lagos Explosion: Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ iléẹ̀kọ́ Bethlehem ń gbàdúrà òwúrọ̀ lọ́wọ́ ní ìbúgbàmù wáyé

Oríṣun àwòrán, others
Ẹnikan ti isẹlẹ ile to dawo ladugbo Festac nilu Eko, ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ sọ fun BBC pe, o ṣoju oun koro nigba ti wọn gbe ọkan lara awọn sista ileewe Bethlehem Girls College jade, lẹyin ti ile iwe ọhun wọ le wọn lori.
Victor Obanor sọ pe oun wa ni nkan bi kilomita meji si ibi ti iṣelẹ naa ti ṣẹ, ṣugbọn iro ibugbamu naa milẹ titi.
Victor ni, ariwo yii lo mu ki oun ati awọn eeyan mii to wa layika sare tete lọ wa ibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹ lọ, lati le ṣe iranlọwọ fun awọn ti ọrọ naa kan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ajá kìí rorò kó ṣọ́ ojú'lé méjì, kò tọ́ ọ́ sí Alaafin láti dásí ọ̀rọ̀ ọba l‘Ekiti - Peter Fatomilọla
- Coronavirus dá wàhálà sílẹ̀ ní Ghana, ìjọba gbé ìlẹ̀kùn gbogbo iléẹ̀kọ́ tìpa
- Iṣẹ́ akin ni ọ̀gá iléẹ̀kọ́ tó kú nínú ìbúgbàmù Eko ṣe, ẹ fàmì ẹ̀yẹ da lọ́lá - PDP késí ìjọba
- Rẹ́rẹ́ rún níbi ìbúgbàmù l'Eko, ọ̀pọ̀ àwòrán rèé
- Gbogbo ẹ̀yin tẹ fẹ́ yọ Oshiomole nípò, ẹ kò moore, ìwà yín ń kóbá APC - Tinubu
Iwaadi ileeṣẹ iroyin BBC fi han pe, wọn ti gbe oku sista Henrietta Alokha, to jẹ alakoso ileewe Bethlehem Girls College ati awọn oṣiṣe ile iwe ọhun meji miran, ti jade laye lẹyin iṣẹlẹ yii, lọ si ile iwosan awọn omọ ogun ori omi nilu Eko.

Oríṣun àwòrán, others
A gbọ pe awọn akẹkọ ile iwe naa wa ni adura owuro, lasiko ti ibugbamu naa ṣẹlẹ, leyi to mu ẹmi rẹ lọ.
Nosa Okunbo, to n gbẹnusọ fun LASEMA sọ fun awọn oniroyin pe igbugbamu miran to waye lẹyin ti ina naa bẹrẹ, lo ba awọn ile to wa layika jẹ, bi ile ijọsin kan ati ibugbe awọn ọmọ ile iwe St Margaret, to wa lagbegbe ọhun.."
Iṣẹ́ akin ni ọ̀gá iléẹ̀kọ́ tó kú nínú ìbúgbàmù Eko ṣe, ẹ fàmì ẹ̀yẹ da lọ́lá - PDP késí ìjọba
Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, ti kesi ijọba apapọ Naijiria, lati fi ami ẹyẹ da Olori ileewe girama Bethlehem, Ẹni ọwọ Henrietta Alokha lọla, to padanu ẹmi rẹ ninu ibugbamu to waye nilu Eko lọjọ Aiku.
Iroyin gbe e pe, arabinrin Alokha ku lẹyin to doola ẹmi awọn akẹẹkọ ileewe naa lasiko ti ibugbamu waye ladugbo Festac nilu Eko.
- Ìpele tuntun ló kàn nínú ìrìnàjò ayé mi, ń kò pe ẹjọ́ lóri ìrọ̀lóyé - Sanusi
- Kò sẹ́ni tó fẹ́ pa Buhari o, ọkùnrin tó pakuru mọ́ ààrẹ kàn fẹ́ bọ̀ọ́ lọ́wọ́ ni - Femi Adesina
- Ọmọ ti lọ kí baba, Fayemi bẹ Aláàfin wo l‘Ọyọ, wọ́n jírórò lórí lẹ́tà
- Ẹ́ gbaradì, to bá lo jẹnẹrátọ̀ àbí tà á, ò ń fi ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá ṣeré - Sẹ́nétọ̀ ń dábàá
- Láì lo Kakulétọ̀, mo ní ọpọlọ ìṣirò, tábìlì ìṣirò wà lórí mi - Human Calculator
Ẹgbẹ PDP, ninu ikede kan ti wọn fi sita loju opo Twitter rẹ sọ pe, oun mọ riri iṣẹ akọni ti arabinrin naa ṣe, ti oun si rọ ijọba apapọ lati fi ami ẹyẹ da a lọla lẹyin iku rẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Màá fún àwọn èèyàn tó forí ṣọta ìbúgbàmù l'Eko ní ₦2bn
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ati igbakeji rẹ Obafemi Hamzat ti ṣabẹwo si ibi ti ọpa epo gaasi ti bu gbamu lagbegbe Abule Ado naa.

Gomina Sanwo-Olu ranṣẹ ibanikẹdun si awọn ti ẹbi ati ara ba iṣẹlẹ naa atawọn ti ile wọn ati ọpọ dukia wọn ṣofo ninu iṣẹlẹ naa.
Gomina ipinlẹ Eko ni iwadii n lọ lọwọ lati mọ ohun to ṣe okunfa iṣẹlẹ ibugbamu ọhun gan an.
Sanwo-Olu ni iṣẹlẹ naa ṣeni laanu pupọ, o ni niṣe lo dabi ẹni pe ogun ṣẹṣẹ ja tan nibi ti iṣẹlẹ ti ṣẹlẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Gomina ipinlẹ wa ṣeleri owo iranwọ biliọnu meji naira fawọn ti wọn fara kaasa ninu iṣẹlẹ naa.
O ni ijọba ti ṣetan lati kọkọ fi aadọta miliọnu le lugba silẹ, nigba to rọ awọn ẹlẹyinju aanu ọmọ Naijiria fikun owo naa ko le pe.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Ọga agba ajọ to n ri si ọrọ pajawiri (LASEMA), Olufemi Oke-Osanyintolu, ṣalaye pe eeyan mẹtadinlogun lo padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ naa.
Oke-Osanyintolu ni awọn to farapa ninu iṣẹlẹ ọhun si n gba itọju lọwọ nile iwosan.












