Alaafin: Ọ̀sán ọjọ́ Àìkú ní Ọba Adeyemi gbalejo Kayode Fayemi

Gomina Kayode Fayemi ati Alaafin Ọyọ

Oríṣun àwòrán, @ekitistategov

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Yoruba ni baba ba sẹ ọmọ, ọmọ ni yoo bẹ baba, bi ọmọ si sẹ baba, ọmọ naa ni yoo bẹ baba, nitori agba ni agba yoo maa jẹ.

O si dabi ẹni pe ede aiyede to n waye lori ọrọ lọbalọba nipinlẹ Ekiti, eyi to ti n mu ọpọ awuyewuye dani, ko ni pẹ rodo, lọ ree mumi bayii, ta ba wo isẹlẹ to n waye ni aafin Ọyọ lọsan ọjọ Aiku.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Idi ni pe Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi ti lọ se ago laafin sọdọ Alaafin tilu Oyo, Ọba Lamide Ọlayiwọla Adeyemi kẹta lọsan ọjọ Aiku.

Gomina Kayode Fayemi ati Alaafin Ọyọ

Oríṣun àwòrán, @ekitistategov

Gbalaja ni Fayemi fi idọbalẹ bẹ fun Alaafin, eyi to n fihan pe ko si aawọ ma.

Ninu ikede kan ti ijọba ipinlẹ Ekiti fi sori ayelujara Twitter rẹ, ni a ti ri ọpọ aworan to n safihan bi Alaafin se tẹwọ gba Fayemi tọwọ-tẹsẹ.

Fayemi dọbalẹ gbalaja, Alaafin naa si fọwọ mejeeji gbe e dide pe "kare, ọmọ daada. Dide nlẹ, ma fọwọ ọla tẹlẹ"

Gomina Kayode Fayemi ati Alaafin Ọyọ

Oríṣun àwòrán, @ekitistategov

Lẹyin naa ni awọn aworan miran tun fi wọn han nibi ti wọn ti jọ joko, n ka iwe kan to jọ lẹta ti Alaafin ti kọkọ kọ si Fayemi, lori ọrọ kan to sọ pe oun yoo rọ awọn ọba Ekiti l'oye.

Ko tan si bẹ o, aworan miran tun fi awọn mejeeji han, nibi ti wọn ti n rẹẹrin sira wọn lori ijoko to jọ pe, Alaafin n sọ fun Fayemi pe, "eeyan o ki n ṣe bayẹn. Ko yẹ ki iwọ naa o sọ pe o maa rọ awọn ọba loye.

Gomina Kayode Fayemi ati Alaafin Ọyọ

Oríṣun àwòrán, @ekitistategov

BBC Yoruba yoo maa mu ẹkunrẹrẹ ijiroro awọn mejeeji wa fun yin laipẹ.

Ọọ̀ni Ifẹ̀ la mọ̀ bíi olórí ọba Yorùbá, kí Aláàfin ya ṣo ewé gbéjẹ́ mọ́wọ́ - Ọ́ba Ekiti fárígá

Alafin tilu Oyo ati Alawẹ ti ilu Ilawẹ Ekiti

Saaju la ti sọ pe Alawe ti ilu Ilawẹ Ekiti, Ọba Adebanji Ajibade Alabi, Afuntade Kinni, ti ba BBC Yoruba sọrọ lati salaye idi to fi kọ lẹta kan si Gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde lori ọ̀rọ̀ Alaafin tilu Ọyọ.

Nigba to ba BBC Yoruba, Alawe ṣalaye gbogbo nkan to kọ sinu lẹta ọhun lẹẹkan si, to si ni pe, ọrọ lọbalọba ipinlẹ Ekiti ko le ye Alaafin laelae, nitorinaa ko maa da si ohun ti ko kan an.

''A fẹ ki Gomina Makinde kilọ fun Alaafin wi pe ko maa da aarin awọn lọbalọba ru nipinlẹ Ekiti nitori Ekiti kii ṣe ilẹ Oyo,'' Alawe lo woye bẹẹ.

Kabiyesi Alawe ni awọn lọbalọba Ekiti ko ranṣẹ pe Alaafin lati da si ọrọ to n lọ laarin wọn, nitorinaa ko duro si aye rẹ.

O ni Alaafin ko le duro si Oyo, ki o maa kọ lẹta ranṣẹ si Ekiti nitori Aguda o jẹ labẹ Gẹeṣi ati wi pe kaka ki kiniun ṣe akapo ẹkun, onikaluku a maa ṣọdẹ tiẹ lọtọọtọọ.

Alawe ti Ilawẹ Ekiti

Oríṣun àwòrán, Alawe of Ilawe Ekiti

O fikun ọrọ rẹ pe, Ọọni Ile Ife, ni gbogbo lọbalọba gba gẹgẹ bi olori nilẹ Yoruba, kii ṣe Alaafin, yoo si dara ki oriade ilu Ọyọ lọ so ewe gbejẹ mọwọ.

Alawe ni ''asiko ajẹlẹ ti kọja, ati wi pe Ooni Ile Ife ni a gba si baba nilẹ Yoruba, oun ni kokari.''

''Kabiyesi Ọọni ni Arole Oduduwa ti gbogbo wa mọ, Ile Ife si ni gbogbo wa ti san wa, kii ṣe Oyo, bẹẹ si ni Ọọ ni ko lee kọ iru lẹta buruku ti Alaafin kọ yii si gomina Fayemi laelae, arifin gbaa ni oun ti Alaafin se naa'' Kabiyesi Alawe lo sọ bẹẹ.

Àkọlé fídíò, Tantra: Ìlànà yìí ló ń kọ́ wa láti fi èémí àti ìṣẹ́po ara gbádùn ìbálòpọ̀

Kabiyesi Alawe ni ọgbọn ati imọ ni Kabiyesi Ọọni fi n to ilẹ Yoruba, Ọọni ko le kọ iru iwe ti Alaafin kọ to fi n bu gomina atawọn ọba alaye l'Ekiti.

Àwa ọba Ekiti kìí ṣe Ajẹ́lẹ̀ rẹ̀, máṣe yọnu sí ohun tí kò kàn ọ́ ní Ekiti - Aláwẹ̀ fèsì fún Aláàfin

Lẹta ti Alaafin tilu Ọyọ, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi Kẹta kọ si gomina ipinlẹ Ekiti, Dokita Kayọde Fayemi, ti n bi Ige ati Adubi bayii.

Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi Keta

Oríṣun àwòrán, Alaafin Oba Adeyemi III

Idi ni pe ojo lẹta miran tun ti yọju sita eyi ti wọn kọ si gomina Seyi Makinde, amọ to n fun Alaafin lesi pada nipa ọrọ to ba Fayemi sọ lori ọrọ awọn lọbalọba.

Ninu lẹta tuntun naa ni alaga igbimọ lọbalọba nipinlẹ Ekiti, tii tun se Alawẹ tilu Ilawẹ Ekiti, Ọba Adebanji Ajibade Alabi, Afuntade Kinni, ti fesi pada fun Alaafin.

Alawe ati gomina Fayemi lọjọ iyansipo rẹ bii alaga igbimọ lọ̀balọba ni Ekiti

Oríṣun àwòrán, Alawe of Ilawe Ekiti

Ninu iwe oloju ewe marun ọhun, ni Ọba Alabi ti n kesi gomina ipinlẹ Ọyọ pe igbimọ lọbalọba ni Ekiti koro oju si awọn ohun ti Alaafin mẹnuba ninu lẹta rẹ.

Fun alaye, Alawẹ ni alaga igbimọ lọbalọba ni Ekiti, ta gbọ pe awọn ọba yoku kọ lati ba se ipade nitori pe wọn ni o kere si awọn ni ipo, ti ko si lẹtọ lati jẹ alaga le awọn lori.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Alawẹ ni Alaafin ko lee wa jẹ gaba lori awọn ọba Ekiti nitori Ekiti ko si labẹ isejọba Ọyọ ri, bẹẹ ni ko lee si labẹ Alaafin laelae.

Alawẹ wa n rọ Gomina Makinde pe ko da Alaafin lẹkun lori bo se n toju bọ awọn ọrọ abẹle to kan awọn lọbalọba nipinlẹ Ekiti nitori lẹta ti Alaafin kọ yii, lo kun fun didọwọ bo ootọ loju ati agbekalẹ ti ko tọna nipa isẹlẹ to n waye laarin awọn lọbalọba ati ijọba ipinlẹ Ekiti.

Lẹta naa fikun pe "Awọn ọba mẹtadinlogun ni Ekiti lo n tọkasi pe awọn wa lara ilana Pẹlupẹlu ninu igbimọ lọbalọba ni Ekiti, amọ pẹlu akọọlẹ ilana ofin ijọba tọdun 2018, ọba meji pere ni ijọba fọwọsi. Ko si sẹni to tako ijọba gomina Ayodele Fayose nigbanaa, ki wa ni pataki ọba mẹrindinlogun ti Alaafin n tọkasi pe o wa ninu ilana pẹlupẹlu?"

"Mo si n fi gbogbo ẹnu ati asẹ mi sọ pe Alaafin se asise pẹlu bo se ni lati igba iwasẹ ni awọn asaaju ọba ni Ekiti ti jẹ mẹrindinlogun, eyiun awọn ọba ti ko lee darukọ wọn, amọ okan n dibọn pe oun ko mọ pe iye ọba to wa labẹ pẹlupẹlu koo duro si oju kan."

Seyi MAkinde ati Alaafin tilu Ọyọ

Oríṣun àwòrán, Alaafin Oba Adeyemi III

Alawẹ ni se ni Alaafin kan n feti si gbọyisọyi kiri lai wadi otitọ ko to maa naka aleebu si gomina Fayemi, to si tun kọ lati darukọ awọn ọba to to ni o kere ni ipo, o si n beere pe awọn ọba wo lo n baa wi gan?

Alaawẹ, ninu lẹta naa, lo tun ni ko si aniani pe Alaafin maa n mọọmọ da awuyewuye ati rogbodiyan silẹ ni nibi ti ko si, to si n dasi ọrọ ti ko kan, to n gbe wahala to da silẹ fun igbimọ lọbalọba ni ipinlẹ Ọyọ ijọun wa, eyi to da ija agba meji silẹ laarin Alaafin ati Ọọni, ti wọn ko si lee se ipade mọ titi ti wọn fi yọ ipinlẹ Ọsun lara Ọyọ.

"Eyi to wa buru ju nibẹ ni pe igbimọ lọbalọba nipinlẹ Ọyọ ko tii se ipade kankan lati ọdun mẹrin nibiti o ti jẹ alaga wọn, eyi ko si sẹyin bo se nira fun lati jẹ ki alaafia, isọkan ati irẹpọ waye laarin awọn ọba alaye nipinlẹ naa. Bawo lo se fẹ fun wa ni ohun ti iwọ gan ko ni, awa ọba Ekiti kii se Ajẹlẹ Alaafin nitori naa ayọnisọ rẹ si ọrọ abẹle lọbalọba Ekiti ko tọ"

Alawẹ ni awọn ọba Ekiti wa n rọ Makinde lati fewe ọmọ mọ Alaafin leti, ko yee da si ọrọ ti ko kan, paapa lori ọrọ to wa nile ẹjọ.

N kò ní ìjà pẹ̀lú Fayemi, ipò mi bíi aláàbò àṣà Yorùbá ní mó ṣe kọ lẹ́tà sí gómìnà Ekiti - Aláàfin

Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi Keta

Oríṣun àwòrán, Alaafin Oba Adeyemi III

Saaju la ti sọ fun yin pe Alaafin tilu Ọyọ, Aba Lamidi Ọlayiwọla Adeyemi Kẹta ti salaye pe agba kii wa lọja, ki ori ọmọ tuntun wọ, ni oun se fi imọran sọwọ si gomina ipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi lori aawọ awọn lọbalọba.

Bẹẹ ba gbagbe, a ti kọkọ mu iroyin wa fun yin nipa lẹta kan ti Alaafin kọ si Fayemi lọjọ kejila osu kẹta, ati awọn koko to wa ninu rẹ.

Nigba to n salaye siwaju lori lẹta naa, Alaafin ni oun ko ni kọnu n kọhọ kankan si gomina naa, koda inu oun ms si amọ oun gbe igbesẹ naa gẹgẹ bii oludaabo bo asa ati ise Yoruba ni.

Alafin tilu Oyo ati Kayode Fayemi

Alaafin sọ siwaju pe agba ti ko ba kẹhun sọrọ, afaimọ ko ma kẹtan sare, idi si ree ti oun fi n fa Fayemi leti pe ko gbọdọ yi asa ati ise wa pada nipinlẹ Ekiti lọna ti ko bojumu.

"Mo kọ lẹta naa gẹgẹ bii Alaafin Ọyọ, ohun mi si ni ohun gbogbo ọmọ Yoruba. Emi ni mo wa nipo to dara julọ lati tọ ijọba sọna, ki n si gba wọn ni imọran lori awọn ọrọ to nii se pẹlu asa ati isẹse Yoruba nitori Alaafin ni oludaabo bo asa to ga julọ."

Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi Keta

Oríṣun àwòrán, Alaafin Oba Adeyemi III

"Ojuse Alaafin ni lati da si awọn ọrọ to ba nii se pẹlu asa to ba suyọ nilẹ Yoruba. Asa atijọ si ni ilana Pẹlupẹlu to jẹ asa awọn ọba alaye ni Ekiti. Taa ba si wo ipa ti awọn Ekiti ko ninu ogun Kiriji, ko yẹ ka fọwọ rọ wọn sẹyin. Awọn ọba mẹrindinlogun to wa ni Ekiti jẹ akikanju ati alagbara ti Yoruba lee gboju le."

Leta ti Fayemi kọ si awọn ọba ni Ekiti

Oríṣun àwòrán, Others

Alaafin tẹsiwaju pe ni gbogbo ọna, ohun amuyangan lawọn Ekiti jẹ fun ilẹ Yoruba, paapa lẹka eto ẹkọ, ko si fẹẹ si agboole kan ti wọn ko ti ni ẹni to kawe de ipo Ọjọgbọn. Iwe ti mo kọ si Fayemi jẹ lẹta baba si ọmọ ni, mo si nigbagbọ pe awọn ohun to wa ninu iwe shun yoo ye yekeyeke.

Amọ titi di akoko yii, ijọba ipinlẹ Ekiti ko tii sọrọ lori lẹta ti Alaafin kọ si naa.