Emir of Kano: El Rufai ní ó yẹ ká maa bọ̀wọ̀ fún àwọn ọba alayé ní òun ṣe fún Sanusi ní oyè méjì pọ̀

Oríṣun àwòrán, @GovKaduna
Gomina ipinlẹ Kano, Mallam Nasir El Rufai ti fọwọ gbaya pe oun ko lee fi Emir tilu Kano ti wọn rọ loye, Sanusi Lamido Sanusi silẹ lasiko yii nitori kii buru buru, ko ma ku ẹnikan mọni.
El Rufai to kede eyi lasiko to n sọrọ lori bi ileẹjọ se pasẹ pe ki wọn fun Sanusi ni ominira rẹ, tun fikun pe ojo ti n pa igun ati Sanusi bọ, ọjọ ti pẹ, tori lati majesin lawọn mejeeji ti n bara awọn bọ, tawọn ko si fi ara awọn silẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Èrò ọ̀pọ̀ èèyàn yàtọ̀ lórí lẹ́tà Alaafin Oyo sí Gomina Fayemi l‘Ekiti nípa ìyọnípò ọba
- Láì lo Kakulétọ̀, mo ní ọpọlọ ìṣirò, tábìlì ìṣirò wà lórí mi - Human Calculator
- Eré apanilẹ́rìn ké kè ké lórí ayélujára ti ṣí ọ̀pọ̀ ìlẹ̀kùn fún mi - Mr Macaroni
- Chatta bímọ tuntun, Mide àti Osupa lẹ̀pọ̀, Sanwo-Olu fún Sola Sobowale lámì ẹ̀yẹ
- Osinbajo wọ́gilé ìrìn-àjò rẹ̀ lẹ́yìn tí ọ̀kan lára ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ kú nínú ìjàmbá ọkọ̀
Gomina Kaduna naa, ẹni to yan Sanusi si ipo meji ọtọọtọ ni kete ti wọn rọọ loye, lo tun ti se abẹwo si ọba alaye ana naa nilu Awe, nipinlẹ Nasarrawa tijọba fi pamọ si lọjọ Ẹti.

Oríṣun àwòrán, @GovKaduna
"Lati majesin lemi ati Sanusi ti jẹ ọrẹ timọtimọ, ko si ja lẹyin mi lasiko gbogbo wahala ti mo la kọja ati awọn aseyọri mi, emi naa si gbọdọ wa lẹyin rẹ lasiko yii to n la isoro kọja, a ko lee ya ara wa, igba ipọnju sa ni a n mọ ọrẹ."
"Sanusi ti ni ominira bayii gẹgẹ bi ileẹjọ ti kede rẹ, o si lee gbe ni ibikibi to ba wu, to fi mọ ilu Kano amọ ilu Abuja la n lọ. O si seese ki Sanusi gba ibẹ lọ si ilu Eko, nibi to wu lati maa gbe lati igba ti wọn ti rọọ loye."

Oríṣun àwòrán, @GovKaduna
Bakan naa ni El Rufai fikun pe, awọn kii tẹ oju ọba mọlẹ nipinlẹ Kaduna n tawọn, awọn si maa n bọwọ fawọn ọba alaye ni nitori awọn ni oludaabo bo asa wa.
"Yatọ si pe Sanusi jẹ ọrẹ atigba ewe mi, o yẹ ka maa gbe ọla fun awọn ọba alaye wa, idi si ree ti mo se yan gẹgẹ bii baba isalẹ fasiti ipinlẹ Kaduna."









