Alaafin: Yóò dára kí Fayemi máṣe fọwọ́ yẹpẹrẹ àwọn oríadé nílẹ̀ Yorùbá

Alaafin tilu Oyo

Oríṣun àwòrán, Alaafin of Oyo

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Alaafin tilu Ọyọ, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi kẹta, ti kọ lẹta ransẹ si gomina ipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi lorukọ awọn ọba alaye ilẹ Yoruba.

Ninu lẹta naa si ni Alaafin ti ni oun kọ iwe ọhun lorukọ awọn ọba ọhun bii Ọọni tilu ile Ifẹ, Awujalẹ tilẹ Ijẹbu, Alake tilẹ Ẹgba, Ọwa Obokun tilẹ Ijẹsa, Ọrangun ti Ila, to si fun pe oruko awọn sba naa si ku.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Alaafin wa n rọ̀ Fayemi lati mase gbe igbesẹ to lee tabuku awọn awọn ọ̀ba alaye nilẹ Yoruba nitori a ni asa to n bu ọwọ ati apọnle fun awọn oriade wa, ju awọn ẹya miran nilẹ Naijria lọ.

Alaafin tilu Oyo

Oríṣun àwòrán, Alaafin of Oyo

Lẹta Alaafin naa, to jẹ oju ewe mẹta, ti oun gan funra rẹ buwọlu, lo salaye nipa aawọ to n jẹ laarin igbimọ lọbslọba nipinlẹ Ekiti ati gomina gan funra.

Awọn koko ohun to wa ninu lẹta Alaafin naa ree:

Koko ohun to wa ninu lẹta ti Alaafin kọ si Fayemi:

  • Alaafin ni lẹta oun da lori agbekalẹ igbimọ lọbalọba nipinlẹ Ekiti, to si yẹ ki Fayemi ranti pe a kii fi ọwọ rọ baa se dagba ju ara wa lọ sẹyin nilẹ Yoruba, to si maa n fara han ninu ipo ta ba dimu.
  • O ni lati igba ti alaye ti daye, bi awọn ọba se ga ju ara wọn lọ wa laarin awọn ọba mẹrindinlogun laisi ija abi ariyanjiyan laarin wọn lori eyi, eyi tawọn agbegbe miran nilẹ Yoruba maa fi n se awokọse rere.
  • Alaafin ni inu awọn ọba alaye yoku nilẹ Yoruba ko dun si bi Fayemi se yan ọba kekere gẹgẹ bii alaga igbimọ lọbalọba ati ijoye nipinlẹ Ekiti, to si gbe lori awọn ilana to wa nilẹ́ tẹlẹ
  • Idi ree tawọn ọba alaye naa fi panu wọn mọ, ti wọn si fi ọrọ naa sikun bii agba. Dipo ki wọn si maa taporogan pẹlu ijọba, wọn gba ileejọ lọ
  • Alaafin ni niwọn igba ti ẹjọ ọhun ti wa nile ẹjọ, ohun ko ni sọrọ lori rẹ pupọ, oun si ro pe o yẹ ki Fayemi naa ro eyi, ko to di pe o tun lọ gbe igbesẹ miran lori isẹlẹ ọhun.
  • Ọba alaye naa ni oun ati ọba yoku nilẹ Yoruba ni inu awọn ko dun si iwe wawi tẹnu rẹ, taa mọ si Query ti Fayemi fun ikọọkan awọn ọba alaye naa, awọn ẹni ti gbogbo aye n bọwọ nla fun, to si n bi wọn pe ki lo de ti wsn ko se wa si ipade lọbalọba lati wa maa fi ori ade tẹ ilẹ niwaju ọmọ inu wọn
  • Alaafin wa ran Fayemi leti nipa ojuse 'Pẹlupẹlu' laarin awọn ọba Ekiti ati bo se kan idagbasoke nilẹ Yoruba, paapa ogun Ekiti Parapọ, taa tun mọ si Ogun Kiriji to waye laarin ọdun 1870 si 1886
  • Ẹya Yoruba ni itan ju ọpọ ẹya ni agbaye lọ. Yatọ sawọn ẹya miran, ẹsin ko so mọ ipo ọba wa rara amọ asa ati ise lo so mọ ipo ọba wa, ti awọn ẹya miran si ri iyansipo ati irọloye ọba bii isẹ akoso wọn lasan, eyi ti ko ri bẹẹ nilẹ Yoruba
  • Alaafin ni si awọn ẹya mii, ko si ohun kan pataki ninu ipo ọba, amọ nilẹ Yoruba, ipo ọba se pataki, to si nii nkan se pẹlu isẹdalẹ ati ọrọ ẹmi tori awọn ọba wa ni asoju awọn alalẹ nilẹ Yoruba, awọn eeyan to ni ilẹ gangan
  • O wa gba Fayemi nimọran pe awọn ọba n rọọ lati mase fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ipo ọba alaye, ko si yago fun ete lati gbe asa ajeji to lee tabuku ba asa ibilẹ wa wọ ilẹ Yoruba.
  • O ni akọsilẹ wa pe lasiko awọn asaaju Fayemi, awọn ọba safihan ẹmi ifọwọsowọpọ ati igboya, ti wọn si koju awọn alagbara ogun lati Ibadan fun odidi ọdun mẹrindinlogun, Fayemi si jẹ ọkan lara awọn to n janfaani ogun rere tawọn ọba Yoruba fisilẹ, itan ti wa fẹ maa fi oju awọn alalẹ rẹ gbolẹ bayii.
  • Gẹgẹ bii baba, awọn ọba alaye wa n gba gomina Fayemi nimọran, lorukọ Oduduwa ati awọn alalẹ yoku nilẹ Yoruba, lati tẹẹ jẹjẹ ninu ibasepọ rẹ pẹlu igbimọ awọn lọbalọba, ko si lo ọgbọn agba lati yanju ọrọ naa nitori Yoruba ni ọgbọn isẹdalẹ ti wọn fi n yanju aawọ nilana ibilẹ.

Wayi, oju opo Twitter lo ti n gbona jainjain pe ki lo de ti Alaafin ko darkọ̀ Ọba tilu Eko gẹgẹ bii awọn oriade to kọ iwe naa lorukọ wọn.

Ero ọ̀pọ̀ eeyan yatọ lori lẹta Alaafin Oyo si gomina Fayemi l‘Ekiti nipa iyọnipo ọba

Saaju la ti mu wa fun yin pe awọn ọmọ Naijiria lori oju opo ikansiraẹni Twitter ti dasi ọrọ laarin Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi ati awọn ọba ni ipinlẹ naa.

Alafin tilu Oyo ati Kayode Fayemi

Eyi ko sẹyin lẹta to jade lori ẹrọ ayelujara nibi ti Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi Kẹta ti kilọ fun gomina ipinlẹ Ekiti lati sọra ṣe, ki o si tẹlẹ jẹjẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iroyin ohun jade wi pe, Gomina Fayemi ni wọn lo fi iwe wawitẹnurẹ ranṣẹ si awọn ọba mẹrindinlogun ni ipinlẹ nitori wọn kọ ọrọ si oun lẹnu.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Fayẹmi ni wọn lo sọ pe awọn ọba naa kọ lati wa si ipade awọn lọbalọba ati ijọba lati Osu Kẹjọ, ọdun 2019 nitori naa, ki wọn sọ idi ti wọn fi gbe iru igbesẹ bẹẹ.

Ekiti

Oríṣun àwòrán, TWITTER

Àkọlé àwòrán, Àwòrán lẹ́tà jáde lórí ẹ̀rọ Twitter níbí tí Alaafin oyotí kìlò fún gomina ìpínlẹ̀ Ekiti pé kó tẹlẹ̀ jẹ́jẹ́ lórí àwọn ọba tó wà ní ìpínlẹ̀ Ekiti.

Amọ Alaafin ninu lẹta ti wọn lo kọ si Fayẹmi sọ wi pe, agbarijọpọ awọn ọba ni ilẹ Yoruba lo fọwọsowọpọ fi ikilọ naa ranṣẹ si gomina naa, lati maṣe fi ori ade tẹlẹ ni ipinlẹ rẹ.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Alaafin ni inu awọn ọba naa ko dun nitori pe goimna Fayemi fi ọba to kere ni ipo jẹ adari ẹgbẹ awọn lọbalọba nipinlẹ naa, idi si niyi ti wọn ṣe gbe igbesẹ ti wọn gbe.

Ekiti

Oríṣun àwòrán, Twitter

Amọ awọn eniyan to fesi lori Twitter si lẹta naa sọ wi pe, ohun ti Alaafin n sọ yii lo n kilọ fun Fayemi wi pe, ilẹ Yoruba kii ṣẹ̀ ipinlẹ Kano ti gomina ti n yọ Emir, ti yoo si le kuro ni ilu nigba to ba wu u.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Bẹẹ ni awọn miran sọ wi pe, ibẹru bojo mu awọn ara Ekiti nitori Fayemi fẹ yọ Ewi ti ilu Ado-Ekiti, Oba Rufus Adejugbe ati awọn ọba mọkanla miran, to n fapajanu si gomina ipinlẹ naa.

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

Awọn miran tilẹ tun fi orukọ gbogbo awọn ti ọrọ naa kan sita lori ẹrọ ayelujara, bi iwadi wa ba si se n lọ lori isẹlẹ yii, BBC Yoruba yoo maa mu wa fun yin.