Ronke Oshodi Oke: N kò ṣe mọ́na-mọ̀na púpọ̀ ni ìgbéyàwó mi ṣe tọ́jọ́

Oríṣun àwòrán, Instagram/ronkeoshodioke
Gbajugbaja oṣere tiata, Ibironke Ojo-Anthony, ti gbogbo eniyan mọ si Ronke Oshodi-oke, ti sọ idi ti ọpọ igbeyawo awọn oṣere fi n fori sanpọn.
Ronke Oshodi-Oke lasiko ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Yoruba salaye pe, nitori asa to gbode kan bi awọn eniyan ṣe n gbe igbesẹ lati kọ ọkọ tabi aya silẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Mò máa ń fọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ ìyá mi, ni ìṣe àwọn obìnrin fi wù mí - Bobrisky
- Ẹ bá mi wá nọ́ńbà ìpè òbí ọmọ Mummy Calm Down jáde - Yinka Ayefele
- Ọlọ́pàá sálọ fún aráàlú l‘Okeho, nígbà tí wọn yari láti ṣun olè méjì tó kù
- Ìpalẹ̀mọ́ ọdún Ileya kò rọgbọ ní Maiduguri, ojo ado oloro n rọ leralera
- Kí ìjọ mi ní Sagamu le gbòòrò ni mo fi ń ṣiṣẹ́ ajínigbé pawó - Pásítọ̀
O ni idi ti igbeyawo oun ṣe wa titi di isinyii ni wi pe, oun kii ṣe mọnamọna pupọ, nitori niwọntun wọnsi ni ọrọ toun, bẹẹ si ni Olorun lo gbe ẹbi oun ro.
"Ki igbeyawo to le dan mọran tabi ki o pẹ, ọkọ ati iyawo gbọdọ bọwọ fun ara wọn."
'Ni aye isinyii to jẹ wi pe bi ọkọ ṣe n gbe bukata ẹbi naa ni iyawo n fi owo silẹ, o pọn dandan ki obinrin ni irẹlẹ, ki ọkọ rẹ naa si fẹran rẹ.

Oríṣun àwòrán, Instagram/ronkeoshodioke
Ọmọ bibi ipinlẹ Ondo ni Ronke Oshodi-Oke, amọ ilu Eko lo ti lọ si ileewe alakọbẹrẹ ati girama, to si ni nitori idi kan tabi omiran ni oun ko fi le tẹsiwaju ni idi ẹkọ oun, lọ si ileewe giga.
Lori alaye bi o ṣe bẹrẹ tiata, Ronke oshodi ni iṣẹ karakata ni oun kọkọ n ṣe,lasiko naa ni oun fẹran lati ma a lọ si 'National Theatre' lati lọ wo fiimu, eleyii to mu ki oun ni ifẹ si ere ṣiṣe, ti oun si fẹran lati ma a rẹrin.
O ni ninu fiimu ti oun kọkọ darapọ mọ ti akọle rẹ jẹ 'Oshodi Oke', ni awọn eniyan ti bẹrẹ si ni pe oun bẹẹ, amọ ko ni nkankan ṣe pẹlu ọmu aya oun.
Bakan naa ni Oshodi Oke tun sọrọ lori ajọsepọ rẹ pẹlu gbajugbaja olorin takasufe 'Nice' ati alaga ẹgbẹ ọlọkọ ero nipinlẹ Eko, Alhaji Musiliu Akinsanya, ti ọpọ eeyan mọ si MC Oluomo.
Ronke Oshodi Oke ni ọrẹ timọtimọ ni awọn mejeeji jẹ si oun, ti ko si si nnkan ikọkọ laarin awọn, bẹẹ ni awọn ẹbi ati iyawo MC Oluomo mọ oun daadaa ninu ile rẹ.
- Àwa àti fijilanté pẹ̀lú ọdẹ́ ìbílẹ̀ ló dojú kọ adigunjalè ní First Bank Okeho - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
- Ìtàn ọba Yorùbá tí wọn yẹgi fún torí ó jí ọmọ gbé ṣe ètùtù
- Ẹ káàbọ̀ sọ́jọ́ Arafat, tí Ọlọ́run yóò fi ààwẹ̀ Mùsùlùmí pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́
- Boko Haram da ìbọn bo ọkọ̀ gómìnà Borno, ẹ̀ṣọ́ àláàbò rẹ̀ farapa
- Ìtàn Ọba Yorùbá tí wọ́n yẹgi fún torí ó jí ọmọ gbé ṣe ètùtù
O fikun pe, oun fẹran orin kikọ, ti oun si ṣetan lati ma a gbe awo orin jade bi iru eleyii ti oun ṣe pẹlu 'Nice', ati eleyii ti oun kọ fun MC Oluomo ni ayajọ ọjọ ibi rẹ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
'Ẹ fi gbogbo ọrọ emi ati MC Oluomo silẹ fun Ọlọrun. Ọrẹ bi ọmọ iya la jẹ.'
Lori ija oun ati Lizzy Anjorin, Ronke Oshodi ni aarin awọn ko fi bẹẹ dan mọran, amọ oun ti kii ku oriire fun ti igbeyawo rẹ.

Oríṣun àwòrán, Instagram/ronkeoshodioke
Lakotan ọrọ rẹ, Gbajugbaja oṣere tiata naa ni oun ṣetan lati mu atunṣe ba gbogbo bi ohun ṣe n ṣe nkan tẹlẹ, nipa afikun imọ nipa lilo ẹrọ ayelujara, eleyii to pe ni 'Rebranding.
Ronke Oshodi Oke ṣe àwo orin jáde fún MC Oluomo fún ọjọ́ ìbí rẹ̀
Oni ọjọ Abamẹta ni ayẹyẹ ọjọ ibi alaga ẹgbẹ ọlọkọ ero nipinlẹ Eko, Musiliu Akinsanya, ti ọpọ eeyan mọ si MC Oluomo.
Ọpọ awọn ilumọọka lawujọ, awọn osere ori itage ati awọn olorin si lo ti n dawọ idunnu loju opo ibadọrẹpọ lori itakun agbaye pẹlu ọlọjọ ibi naa, fun bi ọba oke se mu ki oju rẹ tun ri ọdun tuntun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Amọ lara awọn ikinni to ya ni lẹnu julọ ni ti gbajugbaja osere tiata lobinrin kan, Ronkẹ Ojo Anthony, taa mọ si Ronkẹ Oshodi Oke, ẹni to gbe awo orin jade fun MC Oluọmọ.

Oríṣun àwòrán, Ronke Ojo Anthony
Loju opo Instagram rẹ ati lori Facebook ni Ronkẹ gbe awo orin to danikan kọ naa si, to si n fi ohun to rẹ dodo, kọrin fun ọlọjọ ibi naa.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
Nigba to n salaye idi to fi se bẹẹ, Oshodi oke ni " ọrẹ mi ni ọ MC Oluọmọ, o maa n duro ti mi lọpọ igba, o maa n satilẹyin fun mi, to si maa n fun mi ni iwuri, to ba gbọ ọpọ ohun ti awọn ọrẹ ti se si mi."
O tẹsiwaju pe " Mo jẹ oloriire pe mo jẹ ọrẹ rẹ, mo si nireti pe ọjọ ibi rẹ yii yoo jẹ pataki fun ọ, mo gbadura pe ki gbogbo ala rẹ wa si imusẹ.
Ronkẹ ni MC Oluọmọ seun o, to maa n tẹti si oun, to si tun seun, to jẹ ọrẹ nla si oun.

Oríṣun àwòrán, Ronke Ojo Anthony
Ninu awo naa si lo tun ti n salaye pe igi gbongbo to n so eso fun ẹni ti ebi n pa ni Oluọmọ jẹ, to si ni ni ori gbogbo ti ọlọjọ ibi naa ti da lọla, yoo jẹ ko maa lọ siwaju si, ti Ọlọrun yoo si jẹ ko se ọpọlọpọ ọdun laye.













