Kidnapping: Ọwọ́ ọlọ́pàá ba Pásítọ̀ olórí ikọ̀ ajínigbé tó pa èèyàn márùn ún

Awọn agbebọn pẹlu iboju

Oríṣun àwòrán, Facebook/Policeng

Afurasi ọmọ ikọ ajinigbe kan Musa Umar, ti tu kẹkẹ ọrọ lori bi o ti ṣe maa n gbẹmi awọn eeyan ti wọn ba jigbe.

Umar to jẹ ọmọ ọdun mejilelogun yi ni alukoro ọlọpaa Frank Mba ṣafihan rẹ, pẹlu awọn afurasi miran nilu Abuja lọjọru.

Musa sọ pe, o ti to ọdun mẹta toun ti dara pọ mọ awọn ajinigbe yii, iṣẹ toun si ni lati maa gbẹmi awọn eeyan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Afurasi yii ṣalaye lede abinibi rẹ, Hausa pe lati igba toun ti bẹrẹ, ọkunrin mẹta ati obinrin meji ni ẹmi wọn ti tọwọ oun bọ.

''Agbẹ ni mi bẹẹ si ni mo jẹ ajinigbe. Ikọ ajinigbe gba mi ṣiṣẹ lati maa pa awọn eeyan, bi a ba si ni ka ka ni meni meji, mo ti gbẹmi eeyan marun un.

Awọn agbebọn pẹlu iboju

Oríṣun àwòrán, Facebook/Policeng

Ọkunrin mẹta, obinrin meji. Katsina si ni wọn ti wa''

Pasitọ to n lewaju awọn ajinigbepawo naa ko si panpẹ ọlọpaa:

Ẹwẹ, Frank Mba ṣe afihan Paitọ ẹni ọdun mejilelaadọta kan, Adetokumbo Adenopo to jẹ baba isalẹ fawọn ajinigbe kan.

Paitọ naa to jẹ oludasilẹ ijọ New Life Ministry, Lukosi ni Shagamu sọ fawọn ọtẹlẹmuyẹ ọlọpaa pe niṣe ni oun n ji awọn eeyan gbe nitori ki ijọ oun ba le gbooro si.

Frank Mba ni afurasi Paitọ yii lẹdi apo pọ pẹlu awọn ọdaran mẹta mii, lati ji Jonathan Ekpo gbe.

Àkọlé fídíò, Fulani Kidnapping: Owó púpọ̀ la san kí wọ́n tó fi mi sílẹ̀

O ni wọn gbe Ekpo pamọ sinu aja ilẹ to wa ninu ile ijọsin Paitọ naa ni Ogijo.

Ogun miliọnu Naira ni wọn fẹ gba lọwọ mọlẹbi arakunrin naa, ki ọwọ ọlọpaa to tẹ wọn lọjọ kẹsan osu keje, ti wọn si fi si ahamọ.

Awọn afurasi wọn yii ti ọlọpaa ṣafihan wọn wa lara awọn ọdaran marundinlogoji, ti ileeṣẹ ọlọpaa ṣafihan wọn fun orisirisi iwa ọdaran.

Bakan naa, ileeṣẹ ọlọpaa to n mojuto ilu Abuja ti mu awọn afurasi mẹrinlelogun, ti wọn si ti gba orisirisi nnkan ija lọwọ wọn ṣaaju ọdun ileya to sunmọ yii.

Agbebọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ ìgbà ni ìjínigbé ti wáyé ní ojú ọ̀nà ìlú Abuja si Kaduna

Bala Ciroma, to jẹ ọga agba ọlọpaa nilu naa sọ pe, awọn gba ibọn atọwọda mẹrin, ibọn ẹtu kan ati ibọn atamataṣe kekere kan.

Ko tan sibẹ, wn tun gba ọta ibọn, foonu alagbeka mẹrindinlọgbọn ati siimu foonu mejilelogun, lọwọ awọn afurasi yi.

N50 mílíọ̀nù làwọn ajínigbé tó jí akẹ́kọ̀ọ́ Kaduna gbé ń béèrè

Awọn ajinigbepawo to ji awọn akẹkọ mẹfa ati olukọ meji gbe nileewe aladani kan nilu Kaduna ti n beere fun aadọta miliọnu naira gẹgẹ bii owo itusilẹ wọn.

Patako ajuwe ileewe ti wọn ti ji akẹkọọ gbe

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn obi awọn akẹkọ kan nileewe naa niroyin sọ pe wọn fi idi eyi mulẹ fawọn iwe iroyin abẹle kan lorilẹde Naijiria.

Gẹgẹ bii ohun ti wọn ni ọkan ninu obi naa sọ, ọgbọn miliọnu naira ni awọn ajinigbe naa n beere lori ọmọ kọọkan ti wọn ji gbe; ṣugbọn ọgọrun miliọnu naira lapapọ lawọn alaṣẹ ileewe naa ni agbara awọn ka.

Bi o tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ko tii fi iroyin tuntun sita lori ibi ti iṣẹ de duro lori ṣiṣe awari awọn akẹkọ ati olukọ naa, awọn obi ati alaṣẹ ileewe naa fi to awọn oniroyin leti pe ijiroro ṣi n ls lori iye owo ti wọn yoo gba fun itusilẹ wọn.