Ayo Fasanmi Afenifere: Ta ni Bàbá Fasanmi tí wọ́n ń gbé lọ sí Iye Ekiti padà lẹ́yìn tó papòdà?

Ayo Fasanmi

Oríṣun àwòrán, others

Ẹbi Oloogbe Ayo Fasanmi to doloogbe ti kede bi eto isinku rẹ yoo se ri lọjọ Isẹgun, ọjọ kẹrin, osu kẹjọ, ọdun 2020 yii.

Wọn ni ilu abinibi rẹ ni Iye Ekiti ni ipinlẹ Ekiti ni Guusu Iwọ́ Oorun Naiiria ni eto isinku naa yoo ti waye.

Ijọ mimọ St John Anglican Church to wa ni Iye Ekiti ni yoo seto kookari isinku naa.

Koda, ẹbi ti fẹ́nuko pe ninu iboji ti wọn sin ololufẹ Baba si lọ́dun 2014 naa ni itẹ́ oku ti Baba yoo sun si gbẹ̀yin bi o se sọ saaju iku rẹ̀.

Ogbeni Folabi Fasanmi to jẹ ọkan lara awọn ọma baba naa lo salaye fawọn akọroyin bẹẹ nile Baba Fasanmi to wa ni Osogbo nipinlẹ Osun.

O salaye pe ohun to wu Baba ni ki wọn tete sin in ni eyi ti awọn ẹbi si ti pinnu lati mu sẹ pẹlu ajọsepọ awọn Gomina Iwo Oorun Naijiria ati awọn oloselu ti wọ́n ba Baba rin nigba aye rẹ̀..

Ọmọ Baba Fasanmi salaye pe iboju oloke meji ni Baba ati aya re seto silẹ nigba aye wọn ni eyi ti wọ́n jọ fẹnuko pe ẹni to ba kọkọ lọ lo maa wa ni isalẹ ti eni keji ti ọlọjọ ba de fun a wa ni oke ninu iboji naa.

Oloogbe Felicia to jk aya Oloogbe Ayo Fasanmi jade laye ni ọjọ kẹsan an, osu kẹwaa, ọdun 2014.

O ni ni kete ti gbogbo eto ba ti to ni ẹbi a fi to Naijiria leti ti Baba yoo si fi ara rẹ lélẹ̀ ni itẹ́ ikẹyin.

Àkọlé fídíò, Oronpoto Animation: Akin Alabi ní kò dára bí eré aláwòrán fáwọn ọmọdé ṣe jẹ́ aláwọ̀ funfun

Tani Baba Ayo Fasanmi to doloogbe yii?

A bi Ayo Fasanmi lọjọ kẹtadinlọgbọn, osu kẹsan an, ọdun 1925.

O si jade laye ni irọlẹ ọjọ kọkandinlọgbọn, osu keje, ọdun 2020.

O ku osu meji pere ki Baba pe eni ọdun marundinlọgọ́run un lo dagbere faye pe o digbose.

Ẹkọ apoogun oyinbo ni Baba ka to si gboye to di akọsẹmọsẹ nipa rẹ.

O wa lara awọn ti Baba Awolowo jọ sisẹ papọ nigba aye Baba iran Yoruba ninu oselu Naijiria.

Fasanmi jẹ senetọ ri to si tun se asojusofin ri nigba aye rẹ.

Oun ni olori agba ẹgbẹ́ Yoruba ti wan pe ni Afenifere titi ti ọlọjọ fi de.

O tun jẹ́ agba ẹgbẹ́ oloye ti APC.

Àwòkọ́ṣe ìwà ìrẹ̀lẹ̀, òtítọ́ àti olùfẹ́ mẹ̀kúnnù ni Ayo Fasanmi - Ìjọba Osun

Ìjọba Osun àti ẹgbẹ́ Afenifere dárò ikú akínkanjú olóṣèlú tó kú

Awọn eeyan ti n sedaro agba ilu, oloselu ati ọkan lara awọn asaaju ẹgbẹ Afẹnifẹre to papoda, Alagba Ayo Fasanmi.

Ninu atẹ́jade kan to fisita, ijọba ipinlẹ Osun ti kẹdun lori iku agba oselu naa, ẹni to sapejuwe bii awokọse fun onirẹlẹ, ẹni ti ko mọtara rẹ nikan ati olootọ eniyan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Kọmisana feto iroyin ati ilanilọyẹ araalu nipinlẹ naa, Funke Egbemode, ninu atẹjade naa ni ijọba ipinlẹ Osun mọriri gbogbo aseyọri agba oselu naa nigba aye rẹ, paapaa ipo asaaju to dimu ninu oselu.

Ijọba Osun ni "Baba Fasanmi jẹ asaaju to maa n safihan ifẹ fun orilẹede wa lawọn ọna to pegede, to si tun maa n gbarata lori ipese eto idẹrun fawọn ọdọ."

Ayo Fasanmi

Oríṣun àwòrán, Sogo ọmọ Osun

Atẹjade naa ni ijọba Osun mọriri bi Baba Fasanmi se fẹran ilu Osogbo, ẹni ti isẹ gbe wa silu naa lọdun 1951 gẹgẹ bii osisẹ apoogun amọ to gba lati gbe nilu naa titi di ọjọ iku rẹ.

Ijọba Osun wa gbadura pe ki Ọba oke tẹ oloogbe naa si afẹfẹ rere.

Ọkan gboogi ni Baba Fasanmi ninu ẹgbẹ Afẹnifẹre ki wọn to yapa - Odumakin

Bakan naa, ẹgbẹ ọmọ Yoruba, Afẹnifẹre ti kẹdun ọkan gboogi lara wọn, Baba Ayo Fasanmi to papoda ni ẹni ọdun merinlelaadọrun.

Akọwe ẹgbẹ Afẹnifẹre, Yinka Odumakin, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni Baba Fasanmi jẹ akinkanju eniyan to si ni ifẹ awọn ọmọ kaarọ-ojiire.

Àkọlé fídíò, Oronpoto Animation: Akin Alabi ní kò dára bí eré aláwòrán fáwọn ọmọdé ṣe jẹ́ aláwọ̀ funfun

Bakan naa lo fi kun pe Fasanmi jẹ ọkan gboogi lara awọn to tẹlẹ Baba Obafemi Awolowo nigba aye rẹ ni, to si ja fun idagbasoke ilẹ Yoruba

'Wọn gbaruku ti Awolowo, to fi mọ igba ti o wa ni atimọle'

Wọn tun jẹ Sẹnetọ ni ipinlẹ Ondo ninu ẹgbẹ oṣelu UPN ni saa ijọba alagba ti ekeji ni Naijiria (2nd Republic), ti wọn si ko ipa ribiribi ninu ẹgbẹ naa.

Odumakin ni, Baba Fasanmi jẹ ọkan ninu awon to di opo ẹgbẹ afẹnifẹre mu, amọ wọn yapa diẹ kuro ninu ẹgbẹ afẹnifẹrẹ nigba to ku diẹ ki wọn ku.

O fikun pe ilẹ Yoruba yoo mọ iku agba oselu naa lara, to si gbadura pe ki Ọlọrun tẹ si afẹfẹ rere.

Ayo Fasanmi, aṣaájú ẹgbẹ́ Afenifere jáde láyé

Ayo Fasanmi

Oríṣun àwòrán, Others

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo ti kede pe Oloye Ayọ Fasanmi, tii se ọkan lara awọn asaaju ẹgbẹ Afenifere ti jade laye.

Atẹjade kan ti ọmọ oloogbe naa, Folabi Fasanmi fisita lo kede ipapoda ọkan lara asaaju ẹgbẹ Afenifere naa ni alẹ ọjọru

Gẹgẹ bi atẹjade naa ti wi, ọdun mẹrinlelaadọrun lo lo loke eepẹ, ki ọlọjọ to de.

Alagba Fasanmi, nigba aye rẹ, jẹ agba oselu to de ipo Sẹnatọ, oun si ni asaaju fun ẹgbẹ ọmọ bibi ilẹ Yoruba kan, Ilosiwaju Yoruba.

Atẹjade naa ni baba Fasanmi fi ọwọ rọri ku ni nile rẹ to wa nilu Osogbo, ti wọn yoo si maa kede eto isinku rẹ laipẹ.