Woman who gave birth in Dubai: Nàìjíríà ní Suliyat Abdulkareem fẹ́ bímọ sí ṣùgbọ́n wọ́n há sí Dubai nítorí Coronavirus

Dubai

Oríṣun àwòrán, @OvieSheikh/@helpsuliyatuae

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọmọ Ọba Dubai, Sheikh Hamdan bin Mohammed bin Rashid Al Maktoum ti ni oun yoo san owo itọju ọmọ Naijiria kan to bi ibẹrin si Dubai, ṣugbọn ti wọn ko ri owo ile iwosan san.

Iya ibẹrin ọhun, Suliyat Adulkareem, bi ọkunrin meji ati obinrin meji lọjọ ikunlẹ kan ṣoṣo nile iwosan Latifa ni Dubai lọjọ kinni, oṣu Keje, ọdun 2020.

Iṣẹ abẹ ni wọn fi gbẹbi ẹni ọdun mọkandinlọgbọn naa, bẹẹ ni awọn ọmọ ọhun ko gbo, eyii to mu ki awọn nọọsi gbe wọn sinu igo.

Gẹgẹ bi ọrọ ti ọkọ iya ibẹrin ọhun sọ fun awọn akọroyin, o ni iye owo itọju iya atawọn ọmọ naa le ni miliọnu mọkanlelogoji naira, ti oun ko si ni kobo lọwọ.

Lẹyin naa ni ọkunrin ọhun, Tijani Abdulkareem ke gbajare si awọn eeyan lori ayelujara fun iranlọwọ.

Rashid Al Maktoum

Oríṣun àwòrán, @OvieSheikh

Agbajọwọ awọn ọmọ Naijiria atawọn eeyan orilẹ-ede miran ni Dubai korajọ, wọn ri miliọnu mẹrin din diẹ da fun un, ṣigbọn ko to nnkan.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Lẹyinorẹyin, ọrọ naa to ọmọ Ọba Dubai leti, o si ti ṣeleri lati gbe owo naa san.

Nigba to n ba ileeṣẹ iroyin CNN sọrọ, Abdukareem ni Oore nla ni ọmọ Ọba Dubai ṣe oun atawọn mọlẹbi oun.

Father

Oríṣun àwòrán, helpsuliyatuae

O ni oun yoo sọ ọkan lara obinrin to wa ninu ibẹrin naa ni Latifa, ti n ṣe orukọ ile iwosan ti wọn ti gbẹbi rẹ.

Baba ibẹrin naa ṣalaye pe oriṣiriṣi awọn eeyan ni Naijiria, titi de Portugal ati Brazil lo ti n pe lati fowo ṣowọ si oun, lẹyin naa lo dupẹ lọwọ gbogbo wọn.

Ṣaaju ni tọkọ-taya naa ti gbiyanju lati pada si orilẹ-ede Naijiria lati bi awọn ọmọ naa, ṣuigbọn wọn ha si Dubai nitori isede ti ijọba Dubai kede lẹyin ti ajakalẹ arun Coronavirus burẹkẹ kaakiri agbaye.

Àkọlé fídíò, Oronpoto Animation: Akin Alabi ní kò dára bí eré aláwòrán fáwọn ọmọdé ṣe jẹ́ aláwọ̀ funfun