Boko Haram: Ọwọ́ iléeṣẹ́ ológun tẹ afurasí tó pa akẹẹgbẹ́ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Others
Ileeṣẹ oloogun Naijiria ti sọ pe, akẹgbẹ ọmọ ogun Lẹfutanaati Babakaka Shehu Ngorgi, ti ọpọlọ rẹ ko ṣiṣẹ dede mọ lo ṣeku pa a ni ipinlẹ Bornu.
Ileẹṣẹ ologun lo kede bẹẹ ninu atẹjade kan to fi lede, eyi ti alukoro rẹ, Sagir Musa fọwọ si.
Atẹjade naa ni "Ọmọ ogun kan labẹ ẹka 202 Battalion ni ilu Bama lo ṣadede yin ibọn lu oloogbe ọhun, ni nnkan bi aago mẹwaa abọ aarọ, eyi to yọri si iku rẹ."
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àwòkọ́ṣe ìwà ìrẹ̀lẹ̀, òtítọ́ àti olùfẹ́ mẹ̀kúnnù ni Ayo Fasanmi - Ìjọba Osun
- Àwa àti fijilanté pẹ̀lú ọdẹ́ ìbílẹ̀ ló dojú kọ adigunjalè ní First Bank Okeho - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
- "Ọmọ mi kò tíì mọ̀ pé òun ti di ìlúmọ̀ọ́ká, ó ń wádìí bó ṣe ń rí ara rẹ̀ lórí ayélujára"
- Ìtàn ọba Yorùbá tí wọn yẹgi fún torí ó jí ọmọ gbé ṣe ètùtù
- Ẹ káàbọ̀ sọ́jọ́ Arafat, tí Ọlọ́run yóò fi ààwẹ̀ Mùsùlùmí pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́
O tẹsiwaju pe, ọmọ ogun ọhun, ti wọn ko darukọ rẹ, ṣekupa oloogbe naa, niwaju olu ileeṣẹ wọn, nigba ti oloogbe n ba ẹnikan sọrọ lori ẹrọ ilewọ.
Bo tilẹ jẹ pe wọn ti gbe oku Ngorgi lọ ile igbokusi, ileeṣẹ ologun ni wọn ti fi panpẹ ofin mu ọdanran naa, iwadii si ti bẹrẹ.
O pari atẹjade ọhun pe, wọn ti fi ọrọ naa to awọn ẹbi oloogbe leti.
Lẹyin naa lo ni ileeṣẹ ologun ba gbogbo ẹbi oloogbe naa kẹdun, o si gbadura pe ki Ọlọrun tẹ ẹ si afẹfẹ rere.
ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Ta ló pa ọgágun Borgi, ọ̀rẹ́ ni tàbí ọ̀tá?

Oríṣun àwòrán, Others
Ki lo pa ọgagun Borgi to sẹsẹ se igbeyawo, iku ati ọrun wa ni, Boko Haram ni abi awọn ọta rẹ to n fi ara han bi ọrẹ?
Ibeere yii lo gba ori ayelujara kan, to si nii se pẹlu iku ọmọ ogun orilẹ kan, Lẹfutanaati Borgi, ti wọn pa ni agbegbe Bama ni ipinlẹ Borno.
Gẹgẹ bi iroyin tun ṣe sọ, ko tii pe ọdun kan ti lẹfutannaati Borgi ṣe iyawo, ti iku mu u lọ yii.
Ni bi a ṣe n sọrọ yii, ileeṣẹ ọmọogun ko tii sọ ohunkohun lorii rẹ bẹẹ ni ko tii si ẹnikẹni to lee sọ ni pato ohun gan to le ṣokunfa eyii.

Oríṣun àwòrán, Others
Amọṣa, ohun ti ọkan lara awọn ọgagun agba kan fi to ileeṣẹ iwe iroyin abẹle kan leti ni pe, awọn agbebọn Boko Haram ni wọn de wọn l'ọna.
O ni ọmọ ogun mẹwaa ni wọn pa lọjọ naa, to fi mọ Lẹfutannaati Borgi.
Amọ iroyin miran ti ko fẹsẹ mulẹ ni, awọn ọmọogun akẹgbẹ rẹ, lo yinbọn paa.
Ologun gba 'Camp zero' lọwọ Boko Haram
Ileesẹ ologun Naijiria ni awọn ti tu ibuba awọn ikọ adukukulaja mọni nni Boko Haram ka, ninu igbo Sambisa.
Ibuba wọn naa, ti wọn pe ni ‘Camp Zero‘, lawọn ọmọogun Naijiria kọlu lasiko ti wọn sigun lọ ka Boko Haram mọle eyiti wọn pe ni operation DEEP PUNCH II.
Agbẹnusọ fun ileesẹ ologun orilẹ lorilẹede Naijiria, ọgagun Sani Usman lo kede eyi nilu Maiduguri.

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy
O ni, ikọ ọmọogun Naijiria ko ikogun to pọ nibuba Boko haram. Lara wọn ni awọn ọkọ ijagun oloro, oniruru ibọn, ọta ibọn, awọn iwe ẹsin lorisirisi, agolo, afẹfẹ idana gaasi pẹlu ajilẹ to ni wọn fi n se ado oloro alatọwọda, IEDs.
Alukoro fun ileesẹ ologun orilẹ lorilẹede Naijiria naa tun jẹ ko di mimọ pe awọn ọmọogun naa tun ba awọn ọkọ meje to jẹ ọkọ agbebọn, alupupu, aba ati awọn ọkọ miran jẹ nibẹ

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy
"Ni ọgbọnjọ osu kinni ọdun yi, awọn ọmọ ogun fi ija pẹẹta pẹlu awọn ọmọ ikọ Boko haram, ti wọn si gba ọkọ ijagun EMBT kan, ibọn AK-47, ibọn afẹfẹ tajutaju ati awọn iwe ẹsin lorisirisi pẹlu agolo afẹfẹ idana gaasi pẹlu ajilẹ."
Bakanaa ni wọn tun gba ọkọ ayọkẹlẹ Prado, Golf ati Mitsubishi pẹlu ọkọ meje to jẹ ọkọ agbebọn, alupupu."












