Arafat Day: Wo ohun márùn-ún tí ayájọ́ òní fi lọ́lá jùlọ nínú Islam

Oríṣun àwòrán, Haramain
Ọjọ Aje oni, tii se Ọjọ Kọkandinlogun osu Keje ọdun 2021 ni ọjọ Arafa fun ọdun yii.
Ọjọ Arafa ni ọjọ kẹsan oṣu Zul-Hijjah, ni onka oṣù ojú ọrun.
Ní ayajọ oni ni awọn Alhaji ati Alhaja tuntun máa ń kórajọ pọ sí oke Arafat tó wà ní ìlú Makkah lọdọdún.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Adájọ́ fi ìgbẹ́jọ́ àwọn afurasí tí DSS kó nílé Sunday Igboho sí ọjọ́ ọdún Iléyá
- "Seyi Makinde, yé dá ìjọba ṣe, wá nǹkan ṣe lórí ọ̀rọ̀ ààbò tó mẹ́hẹ́"
- Ojú àwọn arìnrìnàjò rí màbo lójú ọ̀nà Márosẹ̀ Ibadan sí Eko torí ọdún Ileya
- Wo ǹkan mẹ́ẹ̀dògún tó yẹ kí o mọ̀ nípa olówó ayé Obi Cubana
- Adójútini ni Bíṣọ́bù Kukah lórí ọ̀rọ̀ tó sọ nípa Buhari l'Ámẹ́ríkà - iléeṣẹ́ Áàrẹ
Láti ìgbà tí ìrun àílà bá ti to, titi di ìgbà tí òòrùn bá wọ, ni wọn yoo maa gun oke Arafa, láti ṣe ọkan lára àwọn koko iṣẹ hajj naa.

Oríṣun àwòrán, Hujjaj in Masjid al Namirah, Arafat
BBC ṣe ifọrọwerọ pẹlú agba Alfa ẹsìn Islam kan ní Nàìjíríà, Ọmọwe Ibrahim Disina, lóríi àwọn nǹkan tó se pataki to yẹ kí àwọn èèyàn ṣe ni ọjọ Arafa.
Awọn nnkan marun-un to se koko nipa lọjọ Arafa:
Ọlọrun sọ ofin ẹsin Islam kalẹ:
Ní irú ayajọ ọjọ yìí lasiko hajj ìdágbére láyé Anabi Muhmmad (S.A.W.), ni Ọlọrun parí sísọ àwọn òfin ẹsin Islam kalẹ.
Láti ọjọ náà, kò sí ìdájọ kan tó sọkalẹ mọ, eléyìí gan ló fàá tí Sayyidina Umar fi sọ pé:
"Nitori àjùlọ tó wà fún ọjọ yìí, tó bá jẹ àwọn Yahúdí ni, ki sọ ọjọ yìí di ọjọ tí wọn ó máa ṣe ayẹyẹ lọdọdún",
Gẹgẹ bí Ọlọrun ṣe gba ẹmí Anabi Muhammad (S.A.W.) ní ọjọ kọọkanlelọgọrin lẹyìn ìgbà náà.
Adura lori oke Arafa lo lọla julọ:
Gbígba àdúrá nígbà tí èèyàn bá wà l'Árafat ni àdúrà tó lọlá jù lágbáyé.
Gẹgẹ bí Annabi (S.A.W) se sọ pé "Àdúrà tó lọlá jù ni àdúrà tí wọn ṣe lọjọ Arafat"
Ọlọrun maa n yọ awọn eeyan kuro ninu ọmọ ina:
Ní ọjọ Arafat ni Ọlọrun máa n yọ àwọn eeyan kúrò nínú ọmọ iná jùlọ.
Eléyìí wá nínú ẹgbàwá ọrọ Imam Muslim pé: Anabi (S.A.W) sọ pé:
"Kò sí ijọ tí Ọlọrun máa ń yọ àwọn eeyan kúrò nínú ọmọ iná bíi ọjọ Arafa"
Aawẹ ọjọ Arafa maa n pa ẹsẹ rẹ:
Gbígba ààwẹ lọjọ Arafa máa ń pa ẹṣẹ oṣù méjì rẹ, gẹgẹ bí Anabi (S.A.W) ti sọ pé:
"Àwẹ ọjọ rana Arafat máa ń pa àwọn ẹṣẹ ọdún tó kọja àti ti ọdún tó ń bọ."
Muslim ló gba ọrọ yìí wá bákan náà.
Ọlọrun maa n fi awọn Alhaji to wa ni Arafa yangan lọrun:
Ọlọrun máa fi àwọn Alhaji tó lọ sí Arafat yangàn Arafat ní ọjọ yìí.
Imam Ahmad gba ẹgbàwá ọrọ wá pé: Anabi ni: "Ọlọrun máa ń fi àwọn tó lọ sí Arafa yangàn lójú àwọn tó wà lọrun. "

Oríṣun àwòrán, @YasirQadhi
Hajj: Ǹjẹ́ o mọ pàtàkì Ọjọ́ Àràfá fún àwọn mùsùlùmí?
Ọjọ Arafa bọ si Ọjọ Kẹsan ti awọn musulumi n pe ni Dhul-Hajjah, to jẹ ọjọ keji Hajj.
Ọjọ nla ni Ọjọ yii jẹ ninu irinajo awọn musulumi lọ si ilu Mecca, ilẹ mimọ, to si jẹ ọkan ninu awọn ọjọ to se pataki si wọn.
- Ọkọ Lizzy Anjorin fí ẹ̀bùn ọkọ̀ N20m fi ta lọ́rẹ
- Buhari kò jẹ́ kí Yoruba àtàwọn ẹ̀yà míràn gbérí ní Naijiria - Ẹgbẹ́ Yoruba VOR
- "Mo fi nǹkan ọkùnrin mi sínú àgádádogo fún ọ̀sẹ̀ méjì fún ìbálòpọ̀, wàhálà bá de"
- Àwọn egungun ẹ̀yìn mi lágbo tíátà ní Adebimpe Oyebade fi ọ̀nà ẹ̀bùrú gbà mọ́ mi lọ́wọ́ - Yomi Fabiyi
- Wo àwòrán bí ìrìnàjò Hajj ṣe n lọ ní Mecca lásìkò Covid-19
- Mo tún ibojì Funmi Martins ṣe torí ojú ń tì mí nípa ipò ìtìjú tó wà - Ashabi Olorisha
Ti oorun ba ti jade ni ọjọ yii, ni awọn musulumi ti wọn lo bi ilẹ mimọ yoo bẹrẹ irinajo lọ si Oke Arafa to wa ni Mecca.
Ki ni idi ti Ọjọ Arafa fi se pataki si awọn musulumi?
- Ọjọ Arafa ni ọjọ to kangun si ọjọ Eid-al-Adha, iyẹn Ọjọ Ileya, eleyii ti wọn ma n se ni aadọrin ọjọ lẹyin ọdun Ramadan.
- Ọjọ yii jẹ ọjọ ti ẹsin Musulumi gba ibukun ati ire lẹnu Allah gẹgẹ bi ẹsẹ Iwe Mimọ Quran ti kọ silẹ.
- Ọjo Arafa ni Ọjọ keji Hajj ti awọn musulumi jakejado agbaye to lọ si Mecca yoo gun oke aanu arafa to sun mọ Makkah.
- Oke Arafah ni Ojisẹ Allah, Mohammed se ẹsiin ati iwaasu ikẹyin to fi ki wọn pe o digba kan naa.
- Ni Ọjọ Arafa, awọn musulumi ti ko le e lọ si Mecca, ma n gba aawẹ ati adura, nigba ti awọn to lọ si oke Arafa yoo fi gbogbo ọjọ naa gba adura.
- Ọjọ Arafa jẹ ọjọ ti awọn musulumi ya sọtọ patapata lati gba adura fun idariji ẹsẹ ti ọdun to kọja ati eleyii ti n bọ.
















