Yoruba Nation: Ẹgbẹ́ VOR ní ìran Yorùbá wà lábẹ́ ewu lábẹ́ ìṣèjọba Buhari

Ẹgbẹ awọn eekan ọmọ Yoruba, Voice of Reason (VOR) ti kesi aarẹ Buhari lati tẹti si ifẹhọnuhan awọn ọmọ Yoruba to n pe fun idasilẹ Yoruba Nation ati awọn ẹya mii to n beere fun atunto orilẹede Naijiria .
Ẹgbẹ naa fi ipe yii lede ninu atẹjade to fisita fun awọn akọroyin, o fikun pe o ti han si gbangba pe iran Yoruba wa ninu ijamba labẹ iṣejọba aarẹ Buhari.
Ẹgbẹ VOR wa kesi ijọba lati ranti wi pe, iran Yoruba nikan ni ko beere fun iyapa lati igba ti Naijiria ti di ọkan, nitori naa, lo fi se pataki pe ko se akiyesi ipe fun iyapa yii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Mo tún ibojì Funmi Martins ṣe torí ojú ń tì mí nípa ipò ìtìjú tó wà - Ashabi Olorisha
- Àwọn egungun ẹ̀yìn mi lágbo tíátà ní Adebimpe Oyebade fi ọ̀nà ẹ̀bùrú gbà mọ́ mi lọ́wọ́ - Yomi Fabiyi
- Wo àwòrán bí ìrìnàjò Hajj ṣe n lọ ní Mecca lásìkò Covid-19
- Ọmọ Elebuibon tó jẹ́ òṣèré tíátà àti ìyá awo figbe ta lórí ìdẹ́yẹsí tó ń kojú - Oyin Elebuibon
- Ẹ̀yin aṣọ́bodè, ẹ yé ta ẹ̀jẹ̀ wa sílẹ̀ mọ́, agbègbè wa kìí ṣe ibùdó ogun - Olu ti Igboora
- À kò ní le è máa káwọ́ gbera mọ́ nípa àwọn ìkọlù ìgbà gbogbo nílẹ̀ Yorùbá- Gani Adams
- Inú mi dún, mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà fún nǹkan ti mo da- Mary Daniel
- Ẹ wo bí àwọn ajínígbé ṣe gbé ọmọ ọdún 12 sí inú pósí láàyè
VOR ni ilana iṣejọba to n lọ lọwọ ni Naijiria, ni wọn ti n fari apa kan, da apakan si.
VOR ni ''bi aarẹ Buhari ṣe de ipo ni ọdun 2015 ko ṣẹyin ibaṣepọ laarin awọn ọmọ Yoruba, to gbaruku ti aarẹ Buhari pẹlu ileri pe oun yoo ṣe atunto orilẹede Naijiria''

Oríṣun àwòrán, Others
''Amọ o ṣe ni laanu pe titi di asiko yii, ko si ohun to jọ, n ṣe ni aarẹ Buhari n ṣe ohun gbogbo lati mu ifaṣẹyin ba ẹya Yoruba ati ọrọ aje wọn.''
Gẹgẹ bi ọrọ ẹgbẹ naa, gbogbo awọn ti aarẹ Buhari yan si ipo ni iṣejọba rẹ ni wọn wa lati ẹya Fulani, eleyii to dẹyẹ si ẹya Hausa fun ara wọn, ti ko si dun mọ wọn ninu.
''Ati wi pe ẹya Yoruba ko le e ba wọn kopa ninu iru iṣejọba yii mọ, nitori ipalara lo jasi fun ẹya Yoruba.
''Iṣejọba labẹ aarẹ Buhari ti jasi ijiya fun gbogbo ẹya to yatọ si ẹya Fulani ni orilẹede Naijiria, ti eto ọrọ aje ko si ni ojutu mọ pẹlu gbese ni lọtun-losi ti ijọba ti jẹ silẹ pẹlu ajọṣepọ Ile Igbimọ Aṣofin Apapọ.''
''Iya ati iṣẹ ni awọn Naijiria fi n ṣọrọ ni ojoojumọ, ti inu awọn ọmọ Naijiria ko si dun si ijọba nitori gbogbo ohun to n ṣẹlẹ.''
Bakan naa ni ẹgbẹ VOR bu ẹnu atẹ lu bi ijọba ṣe ṣe ikọlu si ile ajijagbara fun ẹya Yoruba, Oloye Sunday Igboho, eleyii to jasi iku awọn eniyan to wa nibẹ lasiko ikọlu naa.
Amọ wọn gboriyin fun awọn Gomina ni Guusu Naijiria fun ijiroro wọn lati beere fun atunto orilẹede Naijria.
Amọ wọn bu ẹnu atẹ lu bi wọn ko ṣe ṣe deede pẹlu ohun ti wọn fẹ nitori wọn n beere fun ipo aarẹ orilẹede Naijiria ni ọdun 2023, ati abadofin PIB, to niiṣe pẹlu akoso eroja epo rọbi ni Naijiria.
Ẹgbẹ VOR wa kilọ fun awọn ijọba ni ilẹ Yoruba lati ṣọra ṣe lori abadofin eto idibo ni Naijiria lori ipese agọ idibo nitori iye awọn eniyan to n dibo nibẹ yoo fun iha Ariwa Naijiria lati ni agọ idibo ju awọn ẹya miran lọ.



















