Kwara: Ẹ wo bí àwọn ajínígbé ṣe gbé ọmọ ọdún 12 sí inú pósí láàyè

Oríṣun àwòrán, Others
Ọmọ ọdun mejila kan ti wọn jigbe ni awọn ẹṣọ alaabo lorilẹede Naijiria ti doola ẹmi rẹ ni ipinlẹ Kwara.
Ọmọkunrin ọdun mejila naa ni wọn doola ẹmi rẹ lasiko ti awọn ẹṣọ alaabo n ṣiṣẹ ''patrol'' ni agbegbe naa.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ajọ ẹṣọ alaabo NSCDC, Babawale Afolabi, ni awọn to ji ọmọ naa gbe si inu posi ti wọn si fi aṣọ funfun bo.
Afolabi ni ọrọ ba ẹyin yọ nigba ti awọn ẹṣọ alaabo da ọkọ naa duro lati ṣe ayẹwọ ọkọ naa nitori o gbe posi si inu oko.
''Bi wọn ṣe ṣi ọkọ bayii, ni awakọ ati awọn to wa ninu ọkọ, bọ silẹ ninu ọkọ, ti wọn si sa wọ igbo lọ, eleyii lo mu ki wọn yoju wo posi ti wọn ri pe wọn ko tii daradara''
''Ọmọkunrin naa ni wọn ri ninu posi ti wọn fi aṣọ funfun bo o''
''Nibayii ileeṣẹ ẹṣọ alaabo ti kesi awọn ẹka eto aabo to n sọ ibode lati bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa, ki wọn si fi panpẹ mu awakọ ati awọn to wa ninu ọkọ''.
''Ọmọ naa ni wọn ti mu lọ si ileewosan, ti wọn si ṣe ayẹwo rẹ, ti iwadii si fihan pe orilẹede Benin Republic ni ọmọdekunrin naa ti wa.''
- Iyalaje Oodua: Toyin Kolade ṣàlàyé ìdí tí Ooni Ogunwusi ṣe fi jẹ Ìyálájé Oodua fún gbogbo ilẹ̀ Yorùbá lágbáyé
- Ìpànìyàn àti ìjínigbé tó gẹ́ ni Southern Kaduna, El-Rufai wá ń ke se-Ọ̀dọ́ Kaduna
- Ènìyàn 80 ló ti d'òkú nítori òjò àrọ̀rọdá tó fa omí yalé agbara ya sọọbù
- Ìjọba àpapọ̀ tún ti kébòsí lórí Sunday Igboho, wọ́n ní ó ń gbìyànjú àti sá kúrò ní Nàìjíríà
- Wo ìdí tí àjọ INEC fi yọ orúkọ gómìnà báńkì àpapọ̀ tẹ́lẹ̀, Chukwuma Soludo kúrò nínú àwọn olùdíje gómìnà Anambra
- Cubana Chief Priest ra màálù 46 fún ìsìnkú ìyá ọ̀gá rẹ̀, àwọn ọmọ Naijiria ń fi èrò wọn hàn
Agbẹnusọ ileeṣẹ ajọ ẹṣọ alaabo NSCDC, Babawale Afolabi ni awọn ti fa ọmọ naa le ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Benin Republic fun iwadii ati lati darapọ pada mọ awọn ẹbi ati ara rẹ.












