Igangan attacks: Ẹ̀ṣọ́ aṣọ́bodè mẹ́ta àti ọmọ ológun kan farapa níbi ìkọlù kan tó wáyé nílùú Igbó Ọrà -Iléeṣẹ́ aṣọ́bodè

Igboro ilu Igangan lẹyin ikọlu ọjọ Ẹti

Awọn oṣiṣẹ ẹ̀ṣọ́ aṣọ́bodè mẹta ati ọmọ ológun kan farapa níbi ìkọlù eléyìí tó wáyé pẹ̀lú àwọn olókoòwo fàyàwọ́ kan lágbègbè Igbo Ora ní Ijọba ìbílẹ̀ Ibarapa, Ipinle Oyo ni nkan bii aago mẹ́jọ alẹ́ ọ́jọ́ Ẹtì Friday ọjọ́

kẹrindínlógún, Oṣu Agẹmọ, ọdún 2021. Awọn Oṣiṣẹ aṣọ́bodè tí wọ́n farapa ni wọ́n jẹ́ oṣiṣẹ ẹ̀ka Zone A, Federal Operations Unit, lásìkò tí wọn ń ṣàyẹ̀wò ọkọ̀ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn lọ́wọ́ ni wọ́n fojú gán-ánni ọkọ akẹ́rù mẹ́jọ tí wọ́n kó àwọn iresi tí kìí ṣe tilẹ̀ yìí wọlé

ṣùgbọ́n tí dírẹ́bà àti àwọn arìnrìn-àjò ọ̀hún bẹ̀rẹ̀ síí dáná ìbọn yá àwọn aṣọ́bodè náà.

Ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n ṣe ìkọlù yìí lọta ìbọn bà nígbàtí àwọn tókù sì fẹsẹ̀ fẹ́ẹ papọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹrù fàyàwọ́ tí wọ́n gbé.

Lásìkò tísẹ́ iwadii n lọ lọwọ lati fojú àwọn ọ̀daràn yìí ba ilé ẹjọ́, gbogbo awọn oṣiṣẹ aṣọ́bodè àti ọmọ ológun tí wọ́n ṣe ìkọlù sí pẹlu ẹni tí ọta ìbọn bà lórí ti ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ báyìí.

 Adelé adarí àgbà àjọ aṣọ́bodè ẹ̀ka ọ̀hún, DC Usman Yahaya, bu ẹnu atẹ lu ikọlu naa bẹ́ẹ̀ lo tẹnumọ́ ipinnu rẹ̀ láti túbọ̀ gbógun ti okoowo fàyàwọ́ láìṣáàrẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí Adelé adarí àgbà àjọ aṣọ́bodè ti sọ, ó pé òun kò ní fìgbà kan jẹ́kí ìrẹ̀wẹ̀sì dé bá òun, pàápàá bí ìkọlù ti ń fojoojumo wáyé sórí àwọn òṣìṣẹ́ aṣọ́bodè láti ọwọ́ àwọn Ọ̀dàràn wọ̀nyí.

Ìgboro ìlú Igboora kan gógó lẹ́yìn ìkọlù àwọn afurasí darandaran Fulani lọ́jọ́ Ẹtì

Gogogo ni igboro ilu Igboọra kan ati awọn ilu miran lagbegbe Ibarapa lẹyin iṣẹlẹ ikọlu awọn agbebọn to waye nibẹ lalẹ ọjọ Ẹti.

Nigba ti ikọ BBC News Yoruba de ilu naa lowurọ ọjọ Abamẹta ninu ipaya ati ibẹrubojo lawọn olugbe ilu naa wa.

Bakan naa ni ara n kan awọn olugbe ilu Igboọra ati awọn ilu miran lagbegbe Ibarapa lori awọn eeyan ti o padanu ẹmi wọn lasiko ikọlu naa.

Ni bi a ṣe n sọrọ yii, awọn ọdọ ilu naa ti fi ẹhonu han ti ajoku taya ọkọ si kun opopona gbogbo ni ilu naa.

Igboro ilu Igangan lẹyin ikọlu ọjọ Ẹti

Amọ ṣa awọn agbofinro atawọn ologun ti wa ni ilu naa bayii lati rii daju pe alaafia jọba.

Igboro ilu Igangan lẹyin ikọlu ọjọ Ẹti
Igboro ilu Igangan lẹyin ikọlu ọjọ Ẹti

Ṣé lóòtọ́ làwọn afurasí darandaran Fulani tún ṣọṣẹ́ nílú Igangan àti agbègbè rẹ̀?

agbebọn kan

Oríṣun àwòrán, other

Ṣe lootọ ni awọn afurasi agbebọn darandaran Fulani tun ya wọ ilu Igangan ni ipinlẹ Ọyọ lalẹ ọjọ Ẹti?

Eyi ni ibeere to tun gba ẹnu awọn eeyan paapaa awọn ọmọ Yoruba gbogbo lori lẹyin ti iroyin lu si igboro pe ikọlu miran tuntun ti waye ni ilu Igangan.

Awọn iwe iroyin abẹle kan ṣalaye pe awọn araalu naa kan fi to awọn oniroyin leti pe ọks mẹta ni awọn agbebọn naa gbe wa fi ṣe ọṣẹ ikọlu naa eyi ti ko ju bi iṣẹju mẹwaa lọ.

Awọn iroyin abẹle naa tun jẹ ko di mimọ pe awọn fijilante ilu naa ati awsn ọmọ ẹgbẹ OPC to dide koju awọn agbebọn naa lo da wọn lẹkun ikọlu naa.

Wọn fi kun un pe ilu Igbo Ọra, Igangan ati Ayetẹ ni wọn ti ṣọṣẹ naa.

Bi o tilẹ jẹ wi pe oniruuru iroyin lo n jade nipa iye awọn eeyan to gbẹmi mi lasiko iṣẹlẹ naa, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ko tii fi idi iṣẹẹ naa mulẹ ati boya eeyan kankan jalaisi nipasẹ rẹ.

Igba akọkọ kọ niyi ti iklu awn agbebọn darandaran yoo maa waye ni ilu Igangan ati awọn ilu miran lagbegbe Ibarapa ni ipinlẹ Ọyọ.