Sunday Igboho and Yoruba Nation: Ìjọba àpapọ̀ tún ti kébòsí lórí Sunday Igboho, wọ́n ní ó ń gbìyànjú àti gba pásípọ́tù ìrìnà mírán láti sá ròkè òkun

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Sunday igboho/instagram

Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti pariwo sita pe Oloye Sunday Adeniyi Adeyẹmọ ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ti n wa ọna lati gba iwe irinna silẹ okeere miran lọna ati lee sa kuro lorilẹede Naijiria.

Ijọba apapọ sọ eleyi di mimọ ninu lẹta kan eyi to tẹ awọn oniroyin lọwọ ti wọn ni ileeṣẹ wọlewọde lorilẹede NAijiria kọ ṣọwọ si oludari agba ileeṣẹ alaabo ọtẹlẹmuyẹ DSS, ọga agba ọlọpaa lorilẹede Naijiria pẹlu ajọ ọtẹlẹmuyẹ NIA.

Wọn ni Sunday Igboho, ẹni to n le iwaju ijijagbara fun idasilẹ orilẹede Yoruba n gbero ati sa ms ofin lọwọ lori ẹsun kiko ohun ija oloro pamọ sile lati da orilẹede Naijiria ru eleyi ti wọn fi kan an lẹyin ti wọn kọlu ile rẹ ni ibẹrẹ oṣu keje ọdun 2021.

Bi o tilẹ jẹ pe Sunday Igboho ti sẹ kanlẹ pe irọ ni gbogbo ẹsun ti wọn fi kan oun, sibẹ awọn ileeṣẹ alaabo ṣi n waa kiri ti ko si si ẹni lee sọ ibi to wa.

Iwe irinna silẹ okeere to jẹ ti Sunday Igboho wa lara awọn ohun ti awọn DSS fi han araye pe awọn ri ko ninu ile rẹ lasiko ikọlu naa.

Ninu lẹta ti o lu si awọn oniroyin abẹle lọwọ yii ni ileeṣẹ wọlewọde tun ti paṣẹ fun gbogbo awọn adari ẹka rẹ gbogbo pe nibikibi ti wọn ba ti kẹẹfin Sunday Igboho nṣe ni ki wọn fi panpẹ ofin gbe e lẹyẹ o ṣọka.