Major General Huseini Ahmed ti wọ káà ilẹ̀ sùn, ó digbéré!

Isinku Ọgagun Huseini

Oríṣun àwòrán, Army Headquarters

Wọn ti sin oku, Ọgagun agba to jẹ adari ẹka ikojanu ileeṣẹ ọmọ ogun. Wọn sin in si iboji ti awọn ologun to wa ni Abuja.

Awọn agbebọn ti ẹnikẹni ko mọ lo ṣekupa Ọgagun Huseini Ahmed lọjọ kẹẹdogun oṣu keje ọdun 2021 nigba to n rinrinajo laarin opopona Lokoja si Abuja.

Ọga agba awọn ọm ogun oriilẹ, Ọgagun Faruk Yahaya sọ ninu ọrọ rẹ nibi isinku naa pe ọgagun agba naa jẹ atẹpamṣẹ to ṣi mọ iṣẹ rẹ bi ẹni mọ owo.

O ṣapejuwe ọgagun naa loriṣiriṣi ọna ara to fi da yatọ ati ipa ribiribi to ko nileeṣẹ ọmọ ogun nigba to wa laye.

Isinku Ọgagun Huseini

Oríṣun àwòrán, Army Headquarters

Ohun to yẹ koo mọ nipa oloogbe Ọgagun Husieni Ahmed

Wọn bi Ọgagun Ahmed lọjọ kẹrindinlogun oṣu keji ọdun 1968 nilu Maiduguri. Ijọba ibilẹ Maiduguri lo ti wa ni ipinlẹ Borno.

O lọ sile ẹkọ girama Yelwa ni Makurdi to si wọ ile ẹkọ awọn ọmọ ogun lọdun 1988 ti wọn si fun un ni ipo Regular Combatant Commission lọjọ kẹdọgbọn oṣu kẹsan ọdun 1993.

O jẹ ọkan lara awọn ọlpaa ologun to goke di Ọgagun agba ko to kagbako iku ojiji yii.

Lati mọ riri awọn iṣẹ takun takun to ti ṣe, ọpọlọpọ ami ẹyẹ ni wọn ti fi da Ọgagun Ahmed Huseini lọla loniruuru ipele nileeṣẹ ogun.

Ọgagun Hassan Ahmed

Oríṣun àwòrán, Nigeria army hq

Ọ̀gágun àgbà Huseini Ahmed, adarí ẹ̀ka akójanu iléeṣẹ́ ọmọogun oríilẹ̀ ní Nàìjíríà

Awọn agbebọn ti yinbọn pa ọgagun ọmọogun Naijiria kan lasiko to fi n rinrinajo lati ilu Lọkọja lọ si ilu Abuja to jẹ olu ilu Naijiria.

Atẹjade kan ti ile iṣẹ ọmọogun fi sita ṣalaye pe Ọgagun Huseini Ahmed kagbako iku ojiji naa ni alẹ Ọjọbọ nigba ti awọn agbebọn naa kọlu ọkọ rẹ.

Ileeṣẹ ọmọogun oriilẹ ni Naijiria ṣapejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bi eyi to banininujẹ lọpọlọpọ, bẹẹ ni wọn ni ko tii si ẹni lee sọ ni pato awọn to wa lẹyin iṣẹlẹ naa ati idi to faa.

Orilẹede Naijiria n ba ipenija ọrọ abo to n ṣe segesege faa lọwọ pẹlu bi awọn ẹgbẹ agbebọn loriṣiriṣi ṣe n rọjo wahala kaakiri tibutoro orilẹede Naijiria.

Opopona ti ọgagun naa rin jẹ skan lara awọn oju opo to ti fi oju wina ikọlu awọn agbebọn wọnyii sẹyin.

Bakan naa ni ko si ẹni lee sọ lọwọ yii boya oun nikan lo wa ninu ọks rẹ lasiko ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.

Àkọlé fídíò, Silas Robotic Engineer: Kò sí ǹkan rere tí ọmọ Nàìjíríà kò lè ṣe

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria, Ọgagun Onyema Nwachukwu ni ọjọ Ẹti ni wọn yoo sin okun Ọgagun agba naa.

Ọkan lara awọn oludari ni olu ileeṣẹ ọmọogun oriilẹ Naijiria nilu Abuja ni Ọgagunagba Hassan, oun si ni akojanu ileeẹ ọmọ ogun oriilẹ ni Naijiria.