2021 Sallah festival: Ààrẹ Buhari ní ọ̀wọ́ngógó ẹran iléyá kò dárá nítorí kò bá ẹ̀sìn Islam mú!

Oríṣun àwòrán, @NigeriaGov
Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti fi ikini ranṣẹ si awọn ọmọ Naijiria lati ba wọn ṣe ayẹyẹ ọdun Eid-El Kabir ti wọn n ṣe kaakiri agbaye.
Ninu atẹjade ti Buhari fi lede gba ọwọ oluranlọwọ pataki rẹ, Garba Shehu ni ijọba oun ṣetan lati mu igbeaye toro fun awọn ọmọ Naijiria nibi ti alaafia, otitọ yoo ti jọba.
Aarẹ Buhari lori awọn ipenija to n koju awọn ọmọ Naijiria lọwọ lọwọ s wi pe ajakalẹ aarun Covid-19 gan an lo ṣokunfa eto ọrọ aje to dẹnukọlẹ kaakiri orilẹede naa.
- Ààrẹ Ògbóni sọ òkò ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí Gani Adams torí bó ṣe tàbùkù Ọba Ogboni tó ṣe ìwọ́de Yorùbá Nation
- Ohun márùn ún tó mú ìgbé ayé le fọ́mọ Nàìjíríà lójoojúmọ́
- Agbébọn já bàálù ológun bọ́, orí kó Abayomi Dairo, awakọ̀ bàálù náà yọ
- A bẹ Seyi Makinde kó wá nǹkan fún àwọn jàńdùkú adàlúrú àmọ́ kò gbà - Mọgaji Moshood
Bakan naa ni aarẹ Buhari ni ojo arọrọda ti da wahala silẹ, to si ba awọn ohun ere oko awọn eniyan jẹ, eleyii to mu ipese ounjẹ labẹle di ọwọngogo, lẹyin ti ijọba gbe igbeṣẹ lati ri pe awọn ounjẹ ti wọn ba n ṣe ni abele ni awọn eniayn n jẹ.

Oríṣun àwòrán, Others
Aarẹ Buhari ni eyi lo fa ti ọwọngogo ounjẹ fi gbode tan, ti ijọba si n sa gbogbo ipa wọn lati ri pe opin deba ọwọngogo yii.
''O ṣeni laanu pe yatọ si pe ojo arọrọda ba ere oko jẹ, awọn ọmọ Naijiria tun n fi iya jẹ ara wọn nitori awọn kan n ta awọn ounjẹ ni ọwọngogo, eleyii to yẹ ki wọn ta ni owo yẹpẹrẹ ki awọn oniṣowo ni abẹle le ri ọwọ mu.''
Ààrẹ Buhari kí àwọn ọmọ Nàíjíríà kú ọdún Eid-El Kabir
Lori eto aabo to dẹnukọlẹ ni Naijiria aarẹ Buhari fi da awọn ọmọ Naijiria loju wi pe sn n ṣiṣẹ takun takun lati da abo bo awọn agbẹ lọwọ awọn agbebọn ti ko jẹ ki wọn lọ si oko wọn.
''Nibayii, a ti ra awọn ohun ija tuntun eleyii ko le koju awọn agbesunmọmi ati awọn agbebọn naa ni igba kan naa.''

Oríṣun àwòrán, others
''Bakan naa ni mo fi asiko yii kesi awọn ọlọja lati din owo ẹran agbo ileya ku eleyii ko ba ẹsin Islam mu''
''Gẹgẹ bi onigbagbọ ninu ẹsin Islam, kii ṣe asa wa ni lati gbe ọwọngogo lori owo ọja , ko dara rara.''
Aarẹ Buhari wa rọ awọn ẹlẹsin musulumi lati gbe igbe aye alaafia ati ibaṣepọ to dara kaakiri ibi ti wọn ba ti ba ara wọn ni Naijiria.
Aarẹ rọ awọn ọmọ Naijiria lati ma a gba adura nigba gbogbo fun awọn adari ati orilẹede Naijiria lapapọ.
- Adájọ́ fi ìgbẹ́jọ́ àwọn afurasí tí DSS kó nílé Sunday Igboho sí ọjọ́ ọdún Iléyá
- Ṣé lóòtọ́ ni ìjọ Winners' Chapel dá pásítọ̀ 41 dúró tórí ọ̀rọ̀ owó?
- Ojú àwọn arìnrìnàjò rí màbo lójú ọ̀nà Márosẹ̀ Ibadan sí Eko torí ọdún Ileya
- Ẹ káàbọ̀ sọ́jọ́ Arafat, tí Ọlọ́run yóò fi ààwẹ̀ pa ẹ̀ṣẹ̀ Mùsùlùmí rẹ́
- Wo ǹkan mẹ́ẹ̀dògún tó yẹ kí o mọ̀ nípa olówó ayé Obi Cubana
Ìjọba Naijiria kéde ọjọ́ Ìṣẹ́gun àti Ọjọ́rú tó n bọ̀ fún ìsinmi ọdún Ileya
Odun Ileya ti awọn Musulumi fun ọdun 2021 yoo waye lọsẹ to m bọ.
Lati se ajọjọ ọdún ileya ti ọdun yii, ijọba Naijiria ti kede ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkanlelogun ati Ọjọru, ọjọ kejilelogun, oṣu Keje, to n bọ gẹgẹ bi ọjọ ìsinmi lẹnu iṣẹ.
Akọwe Agba nileesẹ ijọba to n mojuto ọrọ abẹle, Ọmọwe Shuaib Belgore lo kede rẹ ni Ọjọbọ.
Gẹgẹ bi Belgore ṣe sọ, minisita ọrọ abẹle, Rauf Aregbesola to kede ọjọ isinmi naa lórúkọ ijọba apapọ, ki awọn Musulumi ati awọn ọmọ Naijiria nile-loko ku ọdun.
- Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa "food poisoning" àti bí o ṣe lè dẹ́kun rẹ̀
- Akeredolu, NUJ àtàwọn míì ń ṣèdárò Bunmi Afuye tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ ìdigunjalè lọ l'Ondo
- Ó kéré tán, ajínigbé ti pa èèyàn 222 láàrìn oṣù mẹ́ta ní Kaduna- Gomina El Rufai
- Mọ̀ si nípa agbẹjọ́rò Yoruba Nation tó gbé Buhari lọ sílé ẹjọ́ àgbáyé ICC
- Ọwọ́ àjọ NDLEA tẹ ògbóǹtagì oníṣòwò òògùn olóró méje
- Àjọ̀dún odò Ẹ̀rìn, omi tí wọn kò gbọdọ̀ pa ẹja abàmì inú rẹ̀ wáyé nílùú Erinjiyan
Bakan naa ni Belgore kesi wọn pe ki wọn o tẹsiwaju ninu ìfẹ́, alaafia, oore ṣíṣe ati fifi ara ẹni ji, gẹgẹ bi Anabi Muhammad ṣe ṣe nigba aye rẹ.
O tun rọ wọn pe ki wọn lo asiko ọdún Ileya lati fi gbadura fun alaafia, isọkan, ati idagbasoke Naijiria, paapaa nitori awọn ipenija eto aabo to n koju lọwọ lọwọ.
Aregbesola sọ pe eto aabo ẹ̀mí ati dukia awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria, riro wọn ni agbara fun igbeaye to dara, ati aabo fun awọn ile ẹ̀kọ́, lo jẹ ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari logun.
O si tun rọ àwọn araalu lati ṣọ fun awọn eleto aabo, ti wọn ba sakiyesi ohunkóhun to le ba eto aabo jẹ, lasiko ọdun.
- Buhari fẹ́ dá Naijiria padà sí ọdún 1984, ṣùgbọ́n a kò ní gbà fun- Femi Falana
- Ọmọ Naijiria 350 ni ẹ̀mí wọn sọnù nínù ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi lọ́dún 2020
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ọkùnrin tó gbé ọ̀kadà iléesẹ́ sá lọ lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́
- Ọmọ ìyá kan náà mẹ́ta kú lẹ́yìn tí wọ́n jẹ Àmàlà ní Ilorin
- Ẹ wo ibi ọ̀rọ̀ dé dúró lórí àwọn afurasí tó lọ́wọ́ nínú ikú Tolulope Arotile

















