Gani Adams Vs Ogboni: Ààrẹ Ògbóni ní kò tọ́ fún Gani Adams láti máa bú àwọn Ogboni torí ẹrú Aláàfin ni ipò rẹ̀

Gani Adams

Oríṣun àwòrán, Others

Aarẹ Ogboni Awise Agbaye, Oba Adeyinka Adisa Sangolade Arinfanlajogun, ti fun Aarẹ Ọna Kakanfọ ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams lesi, lori ọrọ to sọ nipa olori awọn ogboni ti wọn mu lasiko iwọde Yoruba Nation to waye ni ipinlẹ Eko.

Ni Ọjọ kẹta, Osu Keje, Ọdun 2021 ni kọmiṣọna ọlọpaa pẹlu ikọ awọn ọlọpaa nipinlẹ Eko fi awọn oluwọde Yoruba Nation ti wọn mu lasiko iwọde wọn ni ilu Eko han, eleyii ti adari ẹgbẹ ogboni kan wa ninu wọn.

Gani Adams, nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lẹyin iṣẹlẹ yii, bu ẹnu atẹ lu adari ẹgbẹ ogboni naa, nitori o ni o jẹ ki awọn ọlọpaa maa ti oun gbọngbọn lasiko iwọde Yoruba Nation.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gani Adams, ẹni to sọrọ yii lasiko to n salaye idi ti ko fi le bawọn kopa ninu iwọde Yoruba Nation ni ko si ọba alade nilẹ Yoruba to ga ju aarẹ Ọna Kakanfo lọ.

Amọ, Aarẹ Ogboni Awise lasiko ifọrọwanilẹnuwo kan ninu fidio kan to lu ori ayelujara pa, ni ko tọ si Gani Adams lati bu ẹnu atẹ lu awọn ogboni nitori ẹru ati iranṣẹ Alaafin ti Ọyọ ni ipo rẹ, ti kii ṣe ti adari kankan ni gbogbo ilẹ Yoruba.

''Awọn oye miran ni ilẹ Yoruba ju ipo Aarẹ Ọna Kakanfo lọ, to fi mọ awọn oye ti Ọọni ti Ile-Ife ba fun ẹnikẹni, nitori awọn eekan ni ilẹ Yoruba kii jagun, awọn ẹru ati iranṣẹ nikan lo ma n jagun, gẹgẹ bi ipo Aarẹ Ọnakakanfo.

Àkọlé fídíò, Oduduwa republic: Mo kọ̀ láti kópa nínú ìwọ́de Yoruba Nations rally ni Eko- Iba Gani Adams

''Oye Akogun, Gbonka ni ilẹ Yoruba ju Aarẹ Ọna Kakanfọ lọ''

Ninu ọrọ rẹ, Ọba Adeyinka ni ko si ẹnikẹni to wa ni ipo kan tabi ni awọn oye ibilẹ kankan, ti ko gba ọdọ awọn Ogboni kọja, nitori naa ko tọ si Gani Adams lati bu ẹnu atẹ lu ẹnikẹni to di ipo naa mu.

''Nitori ẹni ti tirẹ de lamọ, amọ ko si ẹni to mọ igba ti tirẹ naa ma de, ko tọ si Gani Adams lati fi ẹnikẹni ṣe yẹyẹ, nitori oun naa ti ko si ọwọ ijọba ri to si mọ bo ṣe ri.''

''Gani Adams ti kọja aye rẹ, to ba jẹ lootọ lo sọ wi pe ipo oun ju ọpọlọpọ ipo awọn lọbalọba nilẹ Yoruba lọ.''

''Ohun ti n sọ fun Gani Adams ni pe ọba ilu rẹ nikan lo gaju lọ, ko si ọba kankan nilẹ Yoruba ti ipo rẹ ga julọ.''

Gani Adams

Oríṣun àwòrán, Others

''Iranṣẹ Alaafin nikan ni Gani Adams jẹ, ati awọn jagunjagun rẹ lo jẹ adari fun, nitori awọn ipo miran gaju tirẹ lọ ni ilẹ Yoruba''

''Ipo ti Ọọni ti Ile-Ife ba fun ẹnikẹni bii Akogun,' 'Gbonka, ati bẹẹ bẹẹ lọ ju ipo Aarẹ Ọnakakanfo ni ilẹ Yoruba.''

Bakan naa lo ke si awọn lọbalọba ni ilẹ Yoruba lati kesi Gani Adams lati ti ọwọ ọmọ rẹ bọ aṣọ, ko ye sọrọ kubakugbe si awọn asaaju rẹ ati awọn ti wọn kii ṣe irọ.