Biodun Fatoyinbo COZA: Kò sí ààyè fún àíléso nínú isẹ́ Olúwa

Oríṣun àwòrán, Others
Oludasile ijọ Commonwealth of Zion Assembly, Pasito Biodun Fatoyinbo naa ti da si ọrọ to sẹlẹ ninu ijọ David Oyedepo.
Saaju ni Bisoobu David Oyedepo ti ni ki awọn pasitọ kan ninu ijọ Living Faith lọ rọọ kun nile.
Oyedepo ni wọn ko gbe wọn to lẹnu isẹ wọn ninu ijọ Winners Chapel ni.
- Irọ́ ni pé Iléesẹ́ Ọlọ́pàá ń gba àwọn èèyàn sísẹ́ lásìkò yìí- IGP Alkali
- Adájọ́ pàṣẹ pé kí DSS kó èèyàn méjìlá tó kó nílé Igboho wá sílé ẹjọ́
- Àwọn tó ń ṣe ayédèrú fíìmù fẹ́rẹ̀ sọ mí di ẹni ilẹ̀ lẹ́yìn tí mo pàdánù N52m- Olaiya Igwe
- Dubai se òjò àtọwọ́dá láti fi gbógun ti ooru tó mú jù
- Emir ìlú Taraba fún àwọn Fulani Darandaran ní gbèńdéke ọjọ́ 30 láti kúrò nínú igbó ìpínlẹ̀ òun
- To bá fẹ́ dara pọ̀ mọ́ Yoruba Nation, ìgbésẹ́ tó gbé rèé - Ilana Oodua
Fatoynbo fi esi rẹ yii lede loju opo instagram rẹ nibi to ti ni pe: Ko si aaye fun ọlẹ ati alaileso.

Oríṣun àwòrán, Instagram
Ibeere: ti wan ba le osisẹ banki nitori pe ko sisẹ to bi o ti yẹ, se o maa lọ si ori ayelujara lọ maa pariwo ni?....
Bibeli safiwe ọkunrin kan to ni igi ọpọtọ kan ninu iwe Luuku ori ketala, ẹsẹ kẹfa titi de ẹsẹ kẹsan an ni Fatoyinbo fi gbe ẹsẹ ọrọ rẹ lẹyin.
O ni siso eso se pataki ju ki igi ọpọtọ naa kan gbilẹ lasan lọ.
Ati pe Bibeli ni pe gige ni ki a ge igikigi ti ko ba so eso.
Saaju ni Bisoobu Davis Oyedepo ti fesi fun awọ́n to n sọ̀rọ̀ lori bi o se da awọ́n Pasitọ́ kan duro.
Ìjọ́ mi kìí ṣe alágbé, kìí ṣe owó ló mú ká lé pásítọ̀ mọ́kànlélógójì - Oyedepo
David Oyedepo: Ìjọ́ mi gba ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ síṣẹ́ ju ìjọba ìpínlẹ̀ míràn lọ
Asaaju ijọ Winners Chapel, David Oyedepo ti fesi lori awuyewuye to n waye pe ijọ rẹ le pasitọ mọkanlelogoji tori pe wọn ko pawọ wọle.
Oludasilẹ ileesẹ iransẹ Living Faith, ta mọ si Winners Chapel, Bisọọbu David Oyedepo, ti sọrọ sita nipa pasitọ mọkanlegoji, ti ijọ rẹ da duro laipẹ yii.

Oríṣun àwòrán, Winners Chapel
Bẹẹ ba gbagbe, a ti kọkọ mu iroyin wa fun yin nipa bi ijọ Winners' Chapel se gba isẹ lọwọ awọn pasitọ naa tori wọn ko mu ki ijọ wọn kun si.
Nigba to n salaye bi isẹlẹ naa se waye, Bisọọbu Oyedepo ni awọn olusọ aguntan naa lo ya "alaileso ati olukuna patapata,"
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Mo kìlọ̀ fún Igboho kó má wá sí ilé mi ní Benin Republic, lẹ́yìn táwọn ọlọ́pàá ń ṣọ́ mi - Alábàṣiṣẹ́pọ̀
- Wo bí ìgbẹ́jọ́ Sunday Igboho yóò ṣe lọ ní ìlú Cotonou, Benin Republic lónìí
- Benin Republic ló bẹ́gi dínà aáyan ìjọba àpapọ̀ láti kù gììrì gbé Igboho wá Naijiria - Amòfin
- Èpè Aole ló ṣì ń ja ìran Yoruba lórí ọ̀rọ̀ Sunday Igboho àti Yoruba Nation - Sokoti Alagbede
- Ọ̀rọ̀ tí Oluwo sọ ní Yidi Ileya pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Igboho kò kan òun, kò dára rárá - Olùwọ́de
Oyedepo ni "ọrọ akoso ijọ wa ko ye awọn eeyan ni. Mo gbọ pe awọn eeyan kan n ni a da awọn pasitọ naa duro tori pe wọn ko pa owo to towo wọle ni.
Nigba ta gba eeyan bii ẹgbẹrun meje sẹnu isẹ lẹkan soso, se ko si ori ayelujara nigba naa ni abi o ti ku?
A ni awọn osisẹ pupọ nileesẹ iransẹ yii ju ijọba ibilẹ miran lọ, ti a ko si jẹ wọn lowo osu, bẹẹ ni a ko ya owo kankan lati san owo osu wọn.
Awa kii se agbe tabi gba owoya nile ifowopamọ ki a to le san owo osu awọn osisẹ wa, ẹ le bi awọn manija ile ifowopamọ ta n lo leere."
Oyedepo ni ọmọ majẹmu ni awọn ni ijọ Winners, ti awọn si n rin ninu imọlẹ ọrọ Ọlọrun, bẹẹ ni awọn n gbadun ferese ọrun to si silẹ le ijs naa lori.
- Igboho kò gbọdọ̀ padà sí Nàíjíríà, Benin Republic ẹ tú u sílẹ̀ kó lè lọ gbá ''Asylum" ní Germany- Joe Okei-Odumakin
- 'Sunday Igboho kò yojú sílé ẹjọ́ ní Cotonou, àtìmọ́lé ló ṣì wà'
- Sunday Igboho kìí ṣe ‘Terrorist’, ẹ fi sílẹ̀ ní àhámọ́ - Àwọn Olùwọ́de faraya
- "A kò sinmi lórí ọ̀rọ̀ Yoruba Nation, Sept 14 lá yọjú sí United Nation"
- Àjọ Anti Narcotic Cell ní India ti fẹ̀sùn kan Ndubuisi ọmọ Nàìjíríà kan pé ó gbé Cocaine wọ Mumbai
O wa yan pe bi wọn se da awọn pasitọ naa duro ko ni ohunkohun se pẹlu ọrs owo pipa wọle nitori ijọ naa ko se alaini rara.
Ojisẹ Ọlọrun naa fikun pe ijọ oun kan n gbọran si asẹ Ọlọrun ni, to si n se atilẹyin fun ohunkohun ti awọn ba beere nitori Ọlọrun to dara ni.

Oríṣun àwòrán, Instagram/david oyedepo ministries
Ṣé lóòtọ́ ni ìjọ Winners' Chapel dá pásítọ̀ 41 dúró tórí ọ̀rọ̀ owó?
Ọkunrin kan, to pe ara rẹ ni pasitọ ijọ Living Faith Church, Winners Chapel, Peter Godwin, sọ pe awọn alaṣẹ ijọ naa da oun duro lẹnu iṣẹ nitori pe ẹka ijọ ti oun wa ko pa owo wọle daadaa.
Opin ọsẹ to kọja ni iroyin naa kọkọ jade si ori ayelujara, pẹlu fidio kan nibi ti ọkunrin naa ti n ke ibosi pe ki awọn ọmọ Naijiria gba oun.
- Mi ò le tòṣì láéláé! Ẹni tó bá ń bínú kàn ń bínú lásán ni- Oyedepo
- Ègún ọ̀dá owó yóò jà yín, tẹ́ ẹ̀ bá san ìdá mẹ́wàá - Oyedepo
- Daddy Freeze túbá! Wo ìdí tó fi tọrọ àforíjì fún ọ̀rọ̀ ẹ̀gbin tó sọ sí Pásítọ̀ David Oyedepo
- N kò gba owó rí lọ́wọ́ olùdíje kó tó dé ipò - Oyedepo
- Wíwá lórí Twitter, Facebook àti Instagram ní gbogbo ìgbà máa ń pa àyànmọ́ ẹ̀dá- Oyedepo
- Ẹ má dán abẹ́rẹ́ Covid-19 wò lára mi, mi ò gbà! Mi kìí ṣe ẹmọ́ òyìnbó- David Oyedepo
Ọgbẹni Godwin, ti iwadii fidi rẹ mulẹ pe ẹka ijọ Winners kan to wa nilu Ikere-Ekiti, nipinlẹ Ekiti, lo ti n ṣiṣẹ, sọ ninu fidio naa pe oun ati pasitọ bi ogoji ni Pasitọ Agba fun ijọ naa nipinlẹ Ekiti pe si ipade.
Ọjọ kinni, oṣu Keje, ọdun 2021 lo ni pasitọ agba naa pe awọn si ipade ọhun, to si da wọn duro lẹnu iṣẹ nitori pe ile ijọsin wọn ko pawo wọle daadaa.
Kilo wa ninu lẹta naa?
Peter Godwin ni "nipa oore-ọfẹ Ọlọrun, baba wa ninu ile ijọsin yii gba aṣẹ lọdọ Ọlọrun, lati da ẹgbẹrun mẹwaa ijọ silẹ ni Naijiria, mo si jẹ ẹnikan lara awọn pasitọ ti wọn gba si iṣẹ lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 2020.
"Lẹyin eto igbani siṣẹ mi, mo bẹrẹ iṣẹ, mo si fi ara mi n ṣiṣẹ Oluwa. Mo gbiyanju agbara mi, lati ri i pe mo jere ọkan fun Kristi, ṣugbọn o ṣe ni laanu pe mo gba ipe ni ọjọ kinni, osu Keje, pe pasitọ agba nipinlẹ yii fẹ ẹ ri mi.
"Mo kọkọ ro pe emi nikan ni, a fi bi mo ṣe debẹ, ti mo ba awọn pasitọ miran to le ni ogoji. Ko pẹ, ko jina, ni wọn pin lẹta fun gbogbo wa. Ṣiṣi ti mo ṣi lẹta naa lati wo nkan ti wọn kọ si i, iwe idaduro ni mo ba nibẹ."
Ọgbẹni Godwin tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe, wọn kọ sinu lẹta naa pe "lẹyin agbeyẹwo iṣẹ ti a ṣe laipẹ yii, a ri i pe idagbasoke ijọ rẹ ko ri bi a ṣe nireti.
"A fẹ ẹ fi to ọ leti pe iṣẹ rẹ, gẹgẹ bi pasitọ ko wulo mọ ninu iṣẹ iranṣẹ yii, lati akoko yii lọ. O si gbọdọ fi gbogbo dukia ijọ, ile gbigbe, to fi mọ kaadi idanimọ rẹ, fun pasitọ to n dari agbegbe rẹ, ki o to o lọ."
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Adájọ́ fi ìgbẹ́jọ́ àwọn afurasí tí DSS kó nílé Sunday Igboho sí ọjọ́ ọdún Iléyá
- Ẹ káàbọ̀ sọ́jọ́ Arafat, tí Ọlọ́run yóò fi ààwẹ̀ pa ẹ̀ṣẹ̀ Mùsùlùmí rẹ́
- "Seyi Makinde, yé dá ìjọba ṣe, wá nǹkan ṣe lórí ọ̀rọ̀ ààbò tó mẹ́hẹ́"
- Ojú àwọn arìnrìnàjò rí màbo lójú ọ̀nà Márosẹ̀ Ibadan sí Eko torí ọdún Ileya
- Wo ǹkan mẹ́ẹ̀dògún tó yẹ kí o mọ̀ nípa olówó ayé Obi Cubana
- Adójútini ni Bíṣọ́bù Kukah lórí ọ̀rọ̀ tó sọ nípa Buhari l'Ámẹ́ríkà - iléeṣẹ́ Áàrẹ
Ninu lẹta naa to n lọ kaakiri ori ayelujara, to jẹ eyi ti wọn kọ si ara awọn pasitọ ti iroyin sọ pe wọn da duro, Saave Normor, to jẹ pasitọ ijọ naa kan nipinlẹ Benue.
Akọwe Agba fun ijọ Winners, Adebisi O. Aboluwade, lo buwọlu lẹta idaduro naa sita lorukọ awọn alaṣẹ.

Oríṣun àwòrán, Punchng.com
O sọ pe oun pe awọn alamojuto ijọ ni ọjọ keji, lati beere alaye lori iwe idaduro naa, nitori pe "oun ko hu iwa buruku kankan".
Nibẹ lo ni wọn ti sọ fun oun pe ṣọọṣi naa kii ṣowo, ko má jere.
"Wọn tun sọ fun mi pe owo ti ṣọọṣi ti mo n dari n pa wọle, gbọdọ le gbọ bukaata mi ati ile gbigbe.
"Ṣugbọn nitori pe owo ko wọle daadaa, a da ọ duro."
Bakan naa lo sọ pe wọn ko fun awọn ni ẹbun kankan gẹgẹ bi ẹbun gba mabinu.
O ni igbesẹ naa n mu itiju ba agbo Kristi.
Kini ijọ Winners' Chapel sọ lori ẹsun ti Peter Godwin fi kan an?
Awọn alaṣẹ ijọ Living Faith Chapel ko ti sọ nkankan lori ẹsun naa, boya irọ ni, tabi otitọ.
Ileeṣẹ iroyin BBC, nigba to kan si ẹnikan lara awọn oṣiṣẹ ile ijọsin naa lori nọmba to wa loju opo ayelujara, wọn sọ pe oun ko ni ẹtọ lati ba akọroyin wa sọrọ.
Igba akọkọ kọ re e ti ẹnu yoo kun ijọ Winners' Chapel
Ọpọlọpọ igba ni awuyewuye ti waye lori oludasilẹ ijọ Living Faith Church, Biṣọọbu David Oyedepo.
Nigba miran, o le jẹ nitori ọrọ to sọ nipa ijọba Naijiria, arun Covid-19, idamẹwa tabi ọrẹ.
Ni awọn asiko miran, awọn ọmọ Naijiria ma n bu ẹnu atẹ lu igbe aye ọlọla ti Bisọọbu naa n gbe, paapaa nitori pe o ni awọn baalu aladani to fi n rinrinajo, ati fasiti nla meji.
Ọpọ lo gbagbọ pe Bisọọbu Oyedepo kii fi owo ṣe itọrẹ aanu, to si mọ bo ṣe n gba idamẹwa ati ọrẹ lọwọ awọn ọmọ ijọ rẹ.
Lọdun 2020 si 2021, awuyewuye tun waye nipa Oyedepo, nitori bo sẹ sọ pe oun ko gbagbọ pe Covid-19 wa, ti ko si jẹ ki ile ijọsin rẹ ma a tẹle awọn ilana kan ti ijọba fi silẹ nipa Covid-19.





















