T.B Joshua Synagogue church: Youtube lé T.B Joshua kúro, Facebook nàá tún pàrokò sí i

Oríṣun àwòrán, TB Joshua Ministries
Egbinrin ọtẹ, ba ṣe n pakan, nikan n ru ni ọrọ di fun oludasilẹ ijọ Synagogue, Wooli TB Joshua, pẹlu bi awọn alaṣẹ ẹrọ ayelujara ṣe n ja a kuro loju opo wọn.
Ọjọ diẹ ni ẹrọ ayelujara ti awọn eeyan ti ma n wo fidio, Youtube pa oju opo Joshua rẹ lọdọ wọn, lẹyin ti wọn fi ẹsun kan pe o sọ ọrọ ikorira.
Iyalẹnu lo tun jẹ lẹyin ọjọ diẹ, ti iroyin jade pe awọn alaṣẹ oju opo ayelujara mii, Facebook, naa tun ti le e kuro loju opo wọn.
Iroyin sọ pe Joshua sọ ọrọ tako oju opo Facebook, lẹyin ti fidio kan ṣafihan rẹ nibi to ti n le ẹmi ibalopọ ọkunrin si ọkunrin jade lara awọn eeyan.
Amọ ṣa, oju opo ijọ Synagogue lori Facebook, ti wọn pe ni Prophet TB Joshua Ministries, ṣi wa.
Eeyan to le ni miliọnu marun-un lo wa loju opo naa.
Ẹsun wo ni Facebook fi kan TB Joshua?
Nkan ti Facebook ṣe ni pe wọn yọ gbogbo awọn fidio iṣẹ itusilẹ kuro lọwọ 'ẹmi obinrin', to fi sita, kuro ni oju opo naa.
Ileeṣẹ Facebook sọ pe awọn ko ni i gba ki ẹnikẹni o ma a gbogun ti awọn eeyan nitori iru ibalopọ ti wọn n ni.
Iroyin sọ pe ọpọlọpọ fidio lo wa ni ori ayelujara Youtube ijọ naa, eyi to ṣafihan bi TB Joshua ṣe n le ẹmi ibalopọ ọkunrin si ọkunrin, ati ti obinrin si obinrin, kuro lara awọn eeyan.
Wahala bẹrẹ fun Joshua lẹyin ti ajọ kan, Open Democracy kọ iwe ẹsun si awọn alaṣẹ oju opo naa, lori iru fidio ti Joshua n fi si ibẹ, boya o ba ofin oju opo wọn mu.
Amọ o, ijọ naa ti sọ loju opo Facebook rẹ pe oun kii sọ ọrọ idẹyẹsi tabi ikorira.
- Àwọn tó ń polongo Oduduwa Nation fẹ́ ba àláàfíà, ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan ilẹ̀ Yorùbá jẹ́ ni- YWG
- Ẹ má dán abẹ́rẹ́ Covid-19 wò lára mi, mi ò gbà! Mi kìí ṣe ẹmọ́ òyìnbó- David Oyedepo
- Sanwo-Olu àti Osinbajo ẹ gbà mí o, mo ti jẹ gbèsè - Iyabo Ojo figbe ta
- Aṣọ tí mo wọ̀ lọ sí 'Headies Award' ló sún mi débi oríire ipò aṣojú LAWMA- Eniola Badmus
Kinni awijare Wooli TB Joshua?
TB Joshua funra rẹ ti fesi si awọn iṣẹlẹ yii.
Ninu ọrọ to kọ si ori ayelujara Twitter rẹ, o fi fidio kan sibẹ to ni nirtori rẹ ni awọn alaṣẹ Youtube ṣe ja oun kuro loju opo wọn.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ninu fidio naa, wooli naa sọ pe "ọkunrin kan wa ninu eto isin to n lọ lọwọ, to ni ẹmi ọkunrin ninu, ọkunrin ni ọ, ṣugbọn o ko mọ bi nkan yii ṣe ṣẹlẹ si ọ.
O wu ọ lati fẹ obinrin niyawo, sugbọn mi ọkunrin n yọ ọ lẹnu, o ko si le ran ara rẹ lọwọ..., oya ma a jade bọ fun itusilẹ.
Lẹyin ọrọ ti Joshua sọ yii, ni ọkunrin kan jade sita laarin ero pe lootọ ni ẹmi kan ma n sọ fun oun pe ọkunrin ni ki oun o ma a fi ara mọ.
O ni o ti le ni ogun ọdun ti wahala naa ti bẹrẹ ninu aye oun.
O ṣalaye pe oriṣiriṣi nkan ni oun ma n ṣe lati fa oju wọn mọra, amọ ti wọn ko ba gba t'oun, o ma n dabi pe ki oun ba ẹranko ni ibalopọ.
Ijọ Synagogue sọ pe ifẹ Ọlọrun ni awsn n pin fun gbogbo eniyan lori Emmanuel TV, lai wo ẹya tabi ẹsin wọn ṣe.
"A ni ibaṣepọ to dara pẹlu Youtube, igbagbọ wa si ni pe wọn kanju gbe igbesẹ naa."

















