Covid-19 vaccine: Ẹ má dán abẹ́rẹ́ Covid-19 wò lára mi, mi ò gbà! Mi kìí ṣe ẹmọ́ òyìnbó- David Oyedepo

Oríṣun àwòrán, facebook/David Oyedepo
Oludasilẹ ijọ Living Faith ti ọpọ mọ si Winners Chapel, Biṣọọbu David Oyedepo tun ti sọ pe oun ko ni gbabẹrẹ ajẹsara covid-19.
Biṣọọbu Oyedepo ni oun ko ni tọrọ aforiji lọwọ ẹnikẹni nitori oun kọ lati gbabẹrẹ ajẹsara ajakalẹ arun coronavirus.
Biṣọọbu naa sọrọ yii nibi eto adura ijọ naa to waye lọjọ Abamẹta ọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹrin ọdun 2021 yii.
Pasitọ Oyedepo ni oun kii ṣe ẹmọ oyinbo ti wọn le dan abẹrẹ coronavirus wo lara rẹ.
Oludasilẹ ijọ Winners Chapel tun sọ pe abẹrẹ Oxford/Astra Zeneca ti ijọba n fun awọn ọmọ Naijiria lodi si ofin.
Oyedepo ni ''ọrọ ajakalẹ arun coronavirus ti daru mọ gbogbo agbaye loju, ṣugbọn ninu ijọ Ọlọrun ni ojutuu si arun naa wa.''
David Oyedepo ni: ''Mi o o ri bi ti wọn ti n fi ipa fun eeyan abẹrẹ. Mi kii ṣe agbẹjọro ṣugbọn mo ro pe ko tọna.
O kan le wa ṣadeedee wa si ile mi lati fun mi labẹrẹ lai ranṣẹ si ọ tẹlẹ.'
A kii ṣe ẹmọ oyinbo ni Naijiria, itanjẹ lasan ni ọrọ abẹrẹ yii,'' Oyedepo lo sọ bẹẹ.
Oṣu kẹta, ọdun 2021 yii ni orilẹede Naijiria gba abẹrẹ Oxford/Astra Zeneca to le ni miliọnu mẹta.
Eeyan to le ni miliọnu kan lo ti gba abẹrẹ ọhun bayii ni Naijiria.
Eeyan to le ni ẹgbẹrun lọna ọjọ, 160,000 lo ti lugbadi arun covid-19 ni Najiria, nigba ti ẹgbẹrun meji meji ninu wọn ti ba arun naa lọ.













