Oduduwa Nation: Olùwọ́de ní ètò ààbò tí Makinde pèsè, ló mú ki ìwọ́de Ibadan lọ wọ́ọ́rọ́

Ami idamọ orilẹede Oduduwa àti aworan gomina Seyi Makinde

Awọn eeyan to n seto ipolongo fun idasilẹ orilẹede Oduduwa ti gbosuba kare fun gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde lori atilẹyin rẹ.

Nigba to n ki gomina Makinde pe o seun, agbẹnusọ fun Sunday Igboho, Olayomi Koiki ni awọn n m riri ipese eto aabo peye to pese fawọn oluwọde Oduduwa Nation.

Koiki, to kede bẹẹ loju opo Facebook rẹ, Koiki ni awọn n kede fun araye pe gomina ipinlẹ Oyo ti seto gbogbo eto to yẹ lati jẹ ki alaafia jọba lasiko iwọde naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Gomina ipinlẹ Oyo lo se atilẹyin fun iwọde Oduduwa Nation nipa ipese eto aabo to peye, lati ri daju pe ẹnikni ko da iwọde alaafia naa ru.

Awọn olupolongo Oduduwa Nation

Oríṣun àwòrán, Koiki Media

Atilẹyin gomina Makinde yii lo fi n da wa loju pe ipolongo alaafia naa yoo lọ laisi rogbodiyan kankan."

Awọn oluwọde naa wa mọ riri atilẹyin gomina Seyi Makinde fun aseyọri iwọde alagbara to waye lọjọ Abamẹta naa.

Ọrọ to Olayomi Koiki sọ

Oríṣun àwòrán, Koiki Media

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe pitimu ni agbegbe Mapo ati Oja Oba nilu Ibadan kun ni idaji ọjọ Abamẹta fun awọn ọlọpaa to n gbarodan.

Awọn ọlọpaa to wa ni Mapo

Agbegbe yii si ni iwọde naa ti gberasọ, bẹẹ ni awọn agbofinro yii tun wa kaakiri awọn agbegbe to se koko nilu Ibadan lati ri daju pe alaafia jọba lasiko iwọde naa.

Amin iyasọtọ kan

Olùwọ́de Oduduwa kò yọjú sí gbọ̀ngàn Mapo,báwọn ọlọ́pàá ṣe gbàródan

Awọn ọlọpaa to wa ni Mapo

O ti to ọjọ mẹta bayii ti ariwo ti gba ilẹ kan pe iwọde alagbara nla kan yoo waye nilu Ibadan, tii se olu ilu ipinlẹ Oyo lonii ọjọ Abamẹta.

Awọn eeyan to n polongo idasilẹ orilẹede Oduduwa si ni wọn n se agbatẹru iwọde naa, eyi ti wọn ni yoo waye ni gbọngan Mapo.

Aago mẹsan owurọ ọjọ Satide si ni wọn ni iwọde naa yoo bẹrẹ ni Mapo, ti wọn yoo si maa lọ yika ilu Ibadan lati ba awọn eeyan sọrọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bẹẹ ni irọkẹkẹ nipa iwọde naa ti gbode, ti ọpọ eeyan si n woye pe se iwọde naa yoo waye laisi rogbodiyan bi.

Awọn ọlọpaa to wa ni Mapo

Amọ nigba ti BBC Yoruba gunlẹ si gbọngan Mapo ni aago to yẹ ki iwọde waye, a ko tii kofiri awọn eeyan to se agbatẹru iwọde naa.

Titi di akoko yii ta n nko iroyin yii jọ, ko ti i si ẹnikan kan ninu wọn to yọju.

Amin idamọ ikọ to n fẹ idasilẹ Oduduwa Nation

Koda, awọn agbofinro ti oju wọn ko rẹrin rara lo ti de Mapo lati idaji, ti wọn si fọn ka gbogbo agbegbe Oja Oba.

Awọn ọlọpaa to wa ni Mapo

Nigba ti BBC Yoruba se iwadii lọwọ ọkan lara awọn to se agbatẹru iwọde naa lori aago lati mọ ohun to n da wọn duro, o ni inu ile lawọn si wa bayii.

Ohun ti ko han si wa ni boya wọn n reti ki awon ẹsọ alaabo kuro ni agbegbe naa, ki iwọde to bẹrẹ, amọ lọwọ lọwọ bayii, awọn agbofinro ti sọ agadagodo si ẹnu ọna Mapo.

Àkọlé fídíò, Yemi Farounbi: Yorùbá yóò dáàbò bo ara rẹ́, bí ìjọ́ba bá kùnà láti ràgà bò wọ́n

Ojogbon Banji Akintoye ati Sunday Igboho wa lara awon to yẹ ko le iwaju iwọde naa.