Oba Abdulrasheed Adewale Telu 1: Ìwà ọ̀daràn yóò dínkù tí ìjoba bá bẹ̀rẹ̀ sí ní pa àwọn ọ̀daràn tí wọ́n bá mú- Oluwo ti Iwo

Oríṣun àwòrán, Oluwo of Iwo land
"Iwa ọdaran yoo dinku ti ijọba ba bẹrẹ sini pa awọn ọdaran ti wọn ri mu" - Oluwo
Oluwo ti ilẹ Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi Telu I, ti ṣe alaye wi pe adinku yoo deba awọn ọkanojọkan iwa ibajẹ ati iwa ọdaran ti awọn eeyan kan n hu lorilẹede Naijiria ti ijọba ba bẹrẹ sini ṣe idajọ iku lẹsẹkẹsẹ fun awọn ọdaran ti wọn gbamu.
Oluwo ṣe alaye ọrọ naa nibi apẹro laarin agbẹ ati darandaran to waye l'ọjọ Iṣẹgun ni aafin rẹ to n bẹ nilẹ Iwọ.
- Wo ojú àwọn ọmọ Yahoo tí EFFC lọ́ mú l‘Osogbo, tí ọ̀rọ̀ fi dariwo
- Ahmed Isah, Ordinary President, ṣàlàyé ìdí tó fí dá ìgbájú-ìgbámú bó obìnrin lórí afẹfẹ
- Ẹ̀yin tí ẹ sọ pé irọ ni mo ń pa bayii ni yoo ri fún yín
- Lizzy Anjorin sọ̀rọ̀ sókè lórí obìnrin tó ń ba fa sùrútù torí ọkọ rẹ̀
- Oluwo, tí wọ́n bá rán ọmọ níṣẹ́ ẹrú, kó fi t'ọmọ jẹ - Gani Adams
Ọba alade naa fi kun ọrọ rẹ wi pe aisi idajọ ni kiakia fun awọn ọdaran ti awọn agbofinro orilẹede yii ti ri gbamu jẹ nnkan to n fun awọn eeyan mii ni igboya lati tẹsiwaju ninu iwa ọdaran.
Oluwo fi kun ọrọ rẹ wi gbogbo awọn orilẹede to ti gun oke agba lagbaye lo n ṣe idajọ lẹsẹkẹsẹ fun awọn ọdaran to n da omi alafia ilu ru. O ni igbese yii yoo mu ko nira fun ẹnikẹni lati ṣe ohunkohun to le mu wọn ku iku oro.
Oluwo ni, "Ẹnikẹni ti wọn ba gba mu to ge ọwọ eeyan lati fi ṣe etutu ọla, ki ijọba ge ọwọ tiẹ naa. Bi ẹnikẹni ba ge eeyan lori ki wọn ge ori tiẹ naa".
Igbagbọ Ọba alade yii ni pe idajọ ododo ti ko falẹ rara yoo ṣe afọmọ to pọ ni orilẹede wa.
- Nǹkan dé o! Àwọn àgbébọn tún yìnbọn pa ọlọ́pàá méjì lẹ́nu iṣẹ́, wọ́n dáná sun àgọ́ ọlọ́pàá
- Nàìjíríà ti rí €4.2m gbà padà nínú owó tí James Ibori gbé- Malami
- Wo ìdí mẹ́fà tí ìjóba kò se tíì kápá Boko Haram
- Béèlì Baba Ijesha kò túmọ̀ sí ìdáláre, iṣẹ́ sì ń bẹ níwájú - Yomi Fabiyi
- Ẹ̀yin tí ẹ sọ pé irọ ni mo ń pa bayii ni yoo ri fún yín
Ipada ti wọn ṣe ni aafin Oluwo lo da lori ọna ati alafia yoo fi jọba laarin awọn darandaran ati agbẹ tofimọ ikede ofin ti ijọba fi de dida ẹran n'ita gbangba.
Awọn ladelade, Baalẹ, aṣoju ijọba ipinlẹ Ọṣun, ẹgbẹ agbẹ, awọn darandaran ati awọn agbofinro ko gbeyin nibi ipade naa.
Kò sí Oduduwa Nation kankan ni ilẹ̀ Iwo! Kí n má gbọ́ ọ - Oluwo
Sunday Igboho sọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀ Oduduwa Republic, Oluwo fèsì lọ́nà ọ̀tọ̀
Oluwo ti ilu Iwo, Ọba bdulrasheed Akanbi ni ni toun o, oun nigbagbọ ninu orilẹede Naijiria kanṣoṣo.

Oríṣun àwòrán, Oluwo
Kabiyesi ti Ilu Iwo n fesi lori ọrọ to ti n ja rayin-rayin kaakiri orilẹede Naijiria lẹnu ọjọ mẹta yii paapaa laarin ẹya Yoruba pe kí ẹya naa yapa kuro lara Naijiria.
Lori ọrọ yii kan naa, gbajugbaja ajijagbara ilẹ Yoruba, Sunday Adeyemi ti ọpọlọpọ mọ si Sunday Igboho to n gba waju gbẹyin lọwọ lati ja fun iran Yoruba nipa kikoju ẹya Fulani ti wọn ni wọn n ṣe wọn lọṣẹ naa ti sọrọ.
Sunday Igboho ni afi dandan ki iran Yoruba yapa kuro lara Naijiria ki wọn si da duro nitori ijọba to wa lode ti gbe ọrọ ẹlẹyamẹya sori ju.
- 'Èmi Alake yóò bi àwọn alálẹ̀ ilẹ̀ àtàwọn Ogboni ná bí mo bá tilẹ̀ máa tako Sunday Igboho ámbọ̀sìbọ́sí...'
- Ẹyọ kan lára agbára tí mo ní, ni mo lò láti mú Wakili - Gani Adams
- Ọwọ́ Sunday Igboho tẹ ‘Sọ́jà’ àti aráàlú mẹ́rin tó ní wọn ń dọdẹ òun
- Ìgbà mẹ́jọ tí ọ̀rọ̀ Oluwo di ariwo nígboro láàrín ọdún márùn ún rẹ̀ lóyè
- O kéré sí Number! 'Àwa ológún ò fi ara wa wọ́lẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ láti máa ṣe alamí lórí irú ẹ Sunday Igboho'
Ẹwẹ, Oluwo ti Iwo ni "bi a ba ni a o fẹ Naijiria kanṣoṣo mọ, ṣe o tumọ si pe ki a pa ile ẹkọ awọn olukọni ti ijọba to wa ni ilu Iwo ti?".
O tẹ siwaju pe ṣe ki awọn tun kọ iṣẹ akanṣe opopona Iwo-Osogbo-Ibadan ti ajọ FERMA n tun ṣe ti?
"Owo iranwọ ijọba ti wọn n pin titi kan mẹkunu nkọ o?"
Oluwo ni "Orilẹede Naijiria ni ireti ẹya dudu, a gbudọ pawọpọ gẹgẹ bi oṣuṣu ọwọ ka si wa ojutuu ọlọjọ pipẹ si oniruuru iṣoro wa".
Oluwo ni irẹpọ ati ibukun wa ninu ajṣepọ gbogbo ẹya Naijiria.
- 'Ẹ wá gbé àwọn òkú yín o! A ò ráyè kó òkú sí mọ́, bí bẹ́ẹ̀ kọ́...'
- A ò ní N200M tí Ajinigbé ń bèrè fún o, ẹ gbá wá o! Olorí Ọba Imope tí wọ́n jígbé da ọ̀rọ̀ bolẹ̀ fún BBC
- Háà! Ọkùnrin méjì fipá bá obìnrin kan lòpọ̀ nínú ọkọ̀ lójú àwọn ọmọ rẹ̀ lójú pópó
- Bí mo ṣe sáré ibùsọ̀ Kìlómítà 1,500 tí mo fi bọ́ lọ́wọ́ agbébọn - Gómìnà Ortom Benue
- Ǹkan pàtàkì márùn-ún tí gbogbo obìnrin tó ní ojú ara gbọ́dọ̀ mọ̀
















