Pakistan rape sentence: Ilé ẹjọ́ dájọ́ ikú fún ọkùnrin méjì tó fi ipá bá obìnrin kan lòpọ̀ lójú àwọn ọmọ rẹ̀

Ọgba ẹwọn

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Ọgba ẹwọn to wa ni ilu Lahore ni igbẹjọ naa ti waye labẹ eto aabo to l'agbara

Ile ẹjọ kan ni Pakistan ti dajọ iku fun ọkunrin meji nitori ẹsun ifipabanilopọ.

Abid Malhi ati Shafqat Ali Bagga fi ipa ba obinrin kan to jẹ ọmọ orilẹ-ede Pakistan ati France lopọ.

Iroyin sọ pe wọn pade obinrin naa lasiko ti epo bẹtiro tan ninu ọkọ arabinrin naa ni opopona kan nilu Lahore.

Dipo ki wọn ran lọwọ, niṣe ni wọn fi ipa wọ inu ọkọ rẹ, wọn ja a lole, wọn si tun fi ipa balopọ loju awọn ọmọ rẹ mejeeji.

Ọrọ ti ọlọpaa kan sọ lẹyin iṣẹlẹ naa, pe kini obinrin naa n wa nita lasiko naa lai si ọkunrin kankan pẹlu rẹ ti fa iwọde nla ni Pakistan.

Awọn oluwọde

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Iru iwọde to tẹle iṣẹlẹ naa ko waye ri ninu itan orilẹ-ede Pakistan

Amọ ni ọjọ Satide, ile ẹjọ kan nilu Lahore sọ pe Abid Malhi ati Shafqat Ali jẹbi ẹsun ifipabanilopọ, ijinigbe, idigunjale ati igbesunmọmi.

Adajọ si dajọ iku fun wọn.

Agbẹjọro wọn sọ pe wọn yoo pe ẹjọ kotẹmilọrun lori idajọ naa.

Awọn oluwọde kan ni India tako ifipabanilopọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bawo ni iṣẹlẹ naa ṣe waye?

Ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2020 ni obinrin naa kagbako awọn afipabanilopọ yii.

Ẹnu irinajo lo wa, ti epo ọkọ rẹ fi tan.

O pe ẹbi rẹ kan to gba a nimọran lati pe nọmba ajọ pajawiri to wa ni opopona naa, oun funra rẹ si ti n bọ lati wa ran an lọwọ.

Gẹgẹ bi ẹsun ti mọlẹbi rẹ kan kọ ni agọ ọlọpaa, niṣe ni ọkunrin meji fi tipatipa wọn inu ọkọ ti oun ati awọn ọmọ rẹ duro si, ti wọn si ji owo ati ẹṣọ ara rẹ.

Wọn tun fi ipa ba a lopọ ni ori papa kan to wa nitosi loju awọb ọmọ rẹ, ki wọn o to salọ.

Botilẹ jẹ pe ibanujẹ ọkan mu obinrin yii, o gbiyanju lati ṣapejuwe awọn to kọlu.

Iwọde nlanla loriṣiriṣi to waye lẹyin ti ọga ọlọpaa ilu Lahore, Umer Sheikh fi ọgbọn sọ pe ẹbi obinrin naa ni nkan to ṣẹlẹ si, ko ṣẹlẹ ri ni orilẹ-ede Pakistan.

Lẹyin iwọde yii ni wọn ṣe ofin tuntun lori ifipabanilopọ, eyi to faaye gba igbẹjọ ni kiakia, ati idajọ alailaanu.