Harvey Weinstein: Àwọn olùfisùn rẹ̀ faramọ ìdájọ ifipabanilopọ tí wọ́n dá fún un

Weinstein
Àkọlé àwòrán, Àwọn olùfisùn Harvey Weinstein faramọ ìdájọ ifipabanilopọ

Gbogbo àwọn olùfisun, Harvey Weistein lo faramọ idájọ ilé ẹjọ pe o jẹbi ifipabanilopọ ati iwa ipa ti o lo pẹ̀lú gbajugbaja òṣèré tẹlẹ̀ri .

MaGowan sọ fun BBC pe "ǹkan ti o dùn mọ oun ninu ni", nítori pe irú idájọ náà fun àwọn eeyan lásan ni ohùn àti ireti ní ààrin àwùjọ

Weinstein, ẹni ọdún mẹ́tàdinláàdọrin ni wọ́n dájọ fun ni New York fun ibalopọ̀ àti ìwà ọdaran.

Ẹwọ̀n ọdun márùnlélógun ni wọ́n da fún Weinstein lori idajọ ilé ẹjọ fun ibalopọ pẹẹ̀ú obinrin meji, sùgbọ́n agbẹ́jọrò ré ni yóò pe ẹjọ kòtẹmilọrun

Sááju ní wọ́n ti fi ẹsun kan Weinstein ni Los Angeles nitori o lọ ìwà ipá pẹlu àwọn obinrin meji kan lọdun 2013

Lẹ́yìn náà ni àwọn kan dide pẹlu akọle #MeToo lati ri idajọ ododo gbà nitori pe alágbara ni ẹni ti wan n ba koju.