Miyetti Allah lahùn lórí ìjínigbé àti ìpànìyàn tó ń wáyé ní Kwara, takú pé wọn kò gbọdọ̀ ti àwọn ọjà Kara pa

Oríṣun àwòrán, Miyetti Allah
Ẹgbẹ adaranjẹ ti a mọ si Miyetti Allah Cattle Breeders Association of Nigeria (MACBAN) ẹka ti Ipinlẹ Kwara, ti ke si ijọba ipinlẹ náà ati awọn agbofinro lati kilọ fun awọn ti wọn n pe awọn ni agbébọn, pe ki wọn tọwọ ọmọ wọn bọsọ.
Alaga ẹgbẹ naa, Alhaji Shehu Garba sọ eyi di mimọ ninu atẹjade to fi lede ni ọgbọnjọ osu yii nilu Ilorin èyí tó tẹ BBC News Yorùbá lọ́wọ́.
Garba sọ pe bi wọn ṣe n ro isẹ laabi ni ipinlẹ náà mọ ẹya Fulani, ti wọn si n pe wọn ni agbébọn, jẹ ohun to lewu fun ẹya naa lapapọ.
Alaga naa sọ pe, ẹgbẹ Miyetti Allah kọ lo n sokunfa eto abo to mẹhẹ ni awọn apa ibikan ni ipinlẹ naa.
"Miyetti Allah n ran ikọ̀ ológun "Lafiya Dole", ti ijọba apaapọ gbe kalẹ lọwọ ni, a kii ṣe agbébọn"
Alhaji Garba sọ pe awọn Fulani ni wọn n jẹya isẹ ọwọ awọn agbebọn ju nitori pe, àwọn ni wọn n gba ounjẹ oojọ lọwọ wọn.
O ni awọn ọmọ ẹgbẹ Miyetti kan n ran ikọ̀ ológun ti wọn n pe ni "operation Lafiya Dole", ti ijọba apaapọ gbe kalẹ lọwọ ni, ati awọn ikọ fijilante lati gbogun ti iwa ibi ni ipinlẹ Kwara.
Alaga Miyetti Allah naa wa rọ ijọba lati dẹkun isẹ ọwọ àwọn eeyan kan, to ni wọn ko ara wọn jọ lati da rogbodiyan silẹ laarin awọn olugbe Ipinlẹ Kwara, fun ere tara wọn nikan.
O sọ pe ki ijọba kọ eti ikun si ipe wọn pe ki wọn ti awọn ọja ẹran kara pa, wi pe, ipe naa jẹ ipe eke ati aburu.
Garba wa fọwọ sọya pe, ẹgbẹ naa yoo tẹsiwaju lati ma satilẹyin fun ijọba Kwara ninu igbiyanju rẹ lati kọjú ija si awọn agbebọn ati awọn iwa ibi mii.
Saaju ni BBC News Yoruba gbe iwọde ati ifẹhonuhan awọn ọdọ ilu Oke-Ọdẹ ati agbegbe rẹ latari ikọlu ti awọn agbebọn ṣe si ilu naa lọjọ aiku, ti wọn si pa eniyan mẹrinla.
Nibi iwọde naa ni awọn ọdọ naa ti sọ pe, awọn alaga ijọba ibilẹ ti gbiyanju lati ti awọn ọja kara ni agbegbe naa pa sugbọn awọn lọbalọba, paapaa julọ Olupo ti ilu Ajase-Ipo tako igbesẹ naa
Olupo ti Ajase-Ipo fèsì lórí ìpè fún títí ọjà kara nílẹ̀ Ìgbómìnà pa
Bí àwọn èèyàn ilẹ̀ Ìgbómìnà ṣe ń pè fún títí ọjà kara làwọn agbegbe naa pa, BBC News Yoruba kan si Olupo ti ilu Ajase-Ipo, Ọba Ismail Yahaya Alebiosu lori aago lati mọ ero rẹ lórí ọ̀rọ̀ náà.
Nígbà tó ń bá BBC News Yorùbá sọ̀rọ̀, ọba Alebiosu sọ pe oun ko fẹ sọrọ lori awuyewuye naa nitori pe oun ko fẹ ki ọrọ naa tun le ju bayi lọ.
Ọba Alebiosu fi kun-un pe oun le dahun si awọn ibeere mii sugbọn ti oun ba fesi si awuyewuye náà, o le tun hu awọn nnkan míì to ti rodo lee mumi síta.
Kabiyesi ṣe e lalaye pe, lootọ ni wọn ti fi ọrọ naa to oun leti sugbọn alafia ni oun n le pa, ko si wu oun lati fesi si ọrọ naa.
BBC News Yoruba tun kan si alaga ijọba ibilẹ Ifẹlodun, ti Oke-Ọdẹ, Babanla ati awọn agbegbe mii ti eto abo ti mẹhẹ wa labẹ rẹ, Họnọrebu Femi Yusuf lori ago, lati sọrọ lori eto abo awọn ilu yii ati lori awuyewuye titi ọja Kara pa.
Lootọ ni Femi Yusuf gbe aago rẹ, àmọ́ o ni oun ko fẹ ba Akọroyin sọrọ.
Yusuff ni oun lẹtọ si ipinnu oun, oun ko si setan lati sọrọ nitori oun n se idaro awọn eeyan to ku ni Oke Ode lọwọ.
Àwọn agbófinró ya bo ibùba àwọn agbébọn ni Kwara, pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ajínigbé

Oríṣun àwòrán, @Defence Headquarters
Eto aabo ti n pada bọ sipo ni ipinlẹ Kwara báyìí bi apapọ awọn ọmọ ogun ilẹ wa se kọlu ọ̀pọ̀ ibuba awọn agbébọn nipinlẹ náà.
Gẹgẹbi atẹjade ti agbẹnusọ àgbà feto ìròyìn fun gomina Ipinlẹ Kwara, Rafiu Ajakaye fi léde, ọpọ ẹmi awọn ọdaran yii lo lọ lori ikọlu naa.
Ajakaye sọ pe ẹnikẹ́ni ko ti i le sọ boya awọn ikọ ológun ijọba padanu ẹmi wọn nínú ìkọlù náà tàbí bẹẹ kọ.
Tẹ o ba gbagbe, lọjọ Aiku ni awọn afurasi agbebọn ya wọ ilu Oke-Ọdẹ, ni ìjọba ibilẹ Ifelodun, wọn si pa eniyan mẹrinla to fi mọ, baalẹ agbegbe kan.
Ikọlu si ibuba awọn ajinigbe yii waye ni aala ipinlẹ Kogi si ipinlẹ Kwara
Atẹjade naa ka bayii:
"Apapọ ikọ ọmọ ogun lo gbena woju awọn agbebọn ni ibuba wọn to wa ni agbegbe Baba Sango ni alẹ ọjọ Aje.
Ni ibi ìkọlù yii ni ọpọ ẹmi awọn ọdaran yii ti sofo"
Ìkọlù awọn ọmọ ogun sáwọn agbébọn yii lo waye ni ọjọ keji ti iṣẹlẹ ipaniyan naa waye ni ilu Oke-Ọdẹ ni ọjọ Aiku.
Iroyin fihan pe, ikọlu si ibuba awọn ajinigbe yii waye ni aala ipinlẹ Kogi si ipinlẹ Kwara.
Atẹjade naa tẹsiwaju pe, "saaju ni ajọ ọmọ ogun ofurufu ti kede ikọlu lati ofurufu sori awọn ọdaran náà.
Eleyi to jẹ ibẹrẹ ọtun lati jẹ ibuba awọn agbebọn run.
“Ko tii si aridaju kankan boya awọn ikọ ijọba padanu ọmọ ogun kankan."
"Nínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀ ni mo gbé bàbá mi, ọta ìbọn mẹ́fà ló wà lára rẹ̀, àpò èédú tó fi ń ṣòwò ló lọ rà, tí agbébọn fi yìnbọn fún òun àti ọlọ́kadà tó gbé e"

Kayeefi nla lo jẹ ni ọjọ Aje, ọjọ kọkanlelọgbọn osu yi, nigba ti awọn ọdọ tu jade ni awọn ilu bii Oke-Ọdẹ, Babanla, Igbaja, Agunji, Sagbẹ ati awọn ilu mii to wa lẹkun guusu ipinlẹ Kwara.
Awọn ọdọ naa si kora wọn jọ si ikorita to lọ si ilu Ajase-Ipo, wọn gbégi di opopona Ilorin si Abuja, lati dena lílọ bibọ awọn ọkọ.
Igbesẹ yi waye lẹyin ikọlu ti awọn agbebọn ṣe si ilu Oke-Ọdẹ ni ọjọ Aiku, ọjọ kejidinlogun osu yii.
Awọn agbebọn ya wọ ilu naa ni nǹkan bii ago mẹjọ owurọ, wọn si pa awọn fijilante mẹtala ati baalẹ kan.
Isẹlẹ ipaniyan yii si lo gbe BBC News Yoruba lọ silu Oke Ọdẹ lati mọ ohun to sẹlẹ amọ iyalẹnu lo jẹ fun wa lati se alabapade awọn ọdọ agbegbe naa to n fi ẹhonu han lori iwa isekupani ọhun.
"Gbogbo ọja ẹran to wa nilẹ Igbomina la fẹ ki ijọba ti pa tori ibẹ ni awọn ajinigbe ti n na owo itusilẹ ti wọn n gba"
Nigba ti wọn n ba BBC News Yoruba sọrọ awọn ọdọ naa ni awọn n se ifẹhonuhan naa lati ke si ijọba apapọ pe ko ran awọn lọwọ.
Nigba ti BBC Yoruba ba ọkan lara awọn olufẹhonu naa sọrọ, ọgbẹni Rashid Akogun salaye idi ti eyi fi gbọdọ ri bẹẹ.
"A fẹ ki ijọba ti gbogbo awọn ọja kara ti wọn ti n sowo awọn ẹran ọsin to wa ni agbegbe naa pa, paapaa julọ, ọja kara to wa nilu Ajase-Ipo ni ko wa ni titi pa.
Ọja Kara to wa ni Ajasẹ-Ipo ni awọn ajinigbe ti n na awọn owo ti wọn n gba lọwọ awọn eniyan.
Ti wọn o ba ri ibi na awọn owo yii mọ, yoo bajẹ mọ wọn lọwọ, sugbọn wọn n ri ibi na owo, ni wọn ṣe n ji eeyan gbe lọ lati maa beere fun owo itusilẹ.
Fun idi eyi, gbogbo ọja kara to wa ni ilẹ Igbomina pata ni ki wọn ti pa.
Ni bi ọsẹ meji sẹyin, gbogbo awọn alaga ibilẹ ni ilẹ igbomina gbiyanju lati ti awọn kara yii, sugbọn awọn lọbalọba ko gba wọn láàyè.
"A gbe igi di ọna lati fi ẹhonu wa han si ijọba, kiise lati lu eeyan tabi pa ẹya kankan.
A se eyi ki ijọba ba a le mọ ohun to n dun wa lọkan ni, eniyan mẹẹdogun ni wọn pa ni Oke-Ọdẹ, ko si lee ma lọ bẹẹ.

"A ò fẹ́ ikọ Miyetti Allah ti ijọba gbe ibọn fun, lati wa sọ wa, mọ́ ní agbegbe wa"
Nigba ti oun naa n ba BBC News Yoruba sọrọ lori isẹlẹ isekupani nilẹ Igbomina ati iwọde to waye naa, Murktar Ibitoye tii se araalu to jẹ ọdọ, rọ ijọba pe ki wọn ko gbogbo awọn ikọ Miyetti Allah, ti ijọba gbe ibọn fun, pe ki wọn ma sọ awọn kuro lagbegbe naa.
ibitoye sọ pe, "Bororo lo n pa wa, ẹ tun ko ibọn fun wọn lati maa sọ wa, awọn ọdẹ n fi ye wa pe, Miyetti Allah lo dari awọn agbebọn to wa pa awọn eniyan ni Oke-Ọdẹ.
"Ọja kara si ni awọn Bororo ati Miyetti Allah ma n wa, a ko fẹ bororo mọ ni ilẹ wa, a o fẹ Miyetti Allah naa mọ, alafia ni a fẹ ni ilẹ wa."
Sesan Okeleye naa sọ pe, o se ni laanu pe awọn ọmọ iya awọn to fi ara wọn jin lati pese eto aabo to peye si agbegbe naa, lai gba owo, ni wọn pa bi adiyẹ.
"Wọn gba ibọn lọwọ awọn ọdẹ wọnyii wi pe awọn fẹ lọ tun-un ṣe, sugbọn ọjọ keji ni wọn wa pa wọn nitori ko si ibọn ti wọn yoo fi ja.
Eyi tumọ si pe, awọn to gba ibọn lọwọ wọn mọ nipa nnkan to n sẹlẹ.
Ko ṣẹni to le sun mọ wọn ninu wa, a rọ ijọba ki wọn lọ ba wa jẹ awọn ibuba wọn run.
Wọn ni ibuba ni Babanla, bẹẹ si ni wọn ni ibuba ni Odo-Iyasango, awọn sọja si mọ awọn ibuba wọn yii."
Ọgbẹni Alẹsinlọyẹ wa fi ẹdun ọkan rẹ han pe, gbogbo awọn ọga awọn ni wọn n pa, o darukọ awọn ọga wọn ti wọn ti pa ni ilu kọọkan, to si sọ pe, iku awọn akọni wọn yii lo n fa bi wọ ṣe wọle sawọn lara to bẹẹ.

"Ọta ìbọn mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la bá lára bàbá mi"
Pabanbari nipa isẹlẹ isekupani to waye nilu Oke Ode ni ti ọdọkunrin kan, Rilwan Tajudeen, to n salaye pẹlu omije loju nipa bi baba rẹ se ku sinu isẹlẹ ipaniyan to waye nilu naa lọjọ Aiku.
O ni baba oun kii se ọlọdẹ, sugbọn o jẹ onisowo eedu, "apo eedu lo lọ ra ni Oke-Ọdẹ nigbati wọn yinbọn pa oun ati ọlọkada to gbe e.
"Ninu agbara ẹjẹ ni mo gbe baba a mi, ọta ibọn mẹfa ọtọọtọ si ni a ba lara rẹ.
Inu ọfọ ni mo wa, inu mi si bajẹ gidigidi nipa isẹlẹ naa."

A ò mọ ibi tí à ń lọ ní pàtó ṣùgbọ́n à ń sá àsálà fún èmi wa - Aráàlú
Ni ikorita ni ilu Ajase-Ipo, nibi ti awọn ọdọ ti n se iwọde, ni BBC News Yoruba ti ri bi awọn ọkọ ṣe n ko awọn eeyan jade ni kẹtikẹti lati ilu Babanla, Oke-Ọdẹ ati awọn ilu mii to wa ni agbegbe naa.
Nigba ti BBC Yoruba ba awọn arinrinajo sọrọ, wọn ni awọn n salọ kuro nilẹ Igbomina ni o.
Wọn sọ pe, awọn ko mọ ibi ti awọn n lọ ni pato sugbọn awọn n sa asala fun ẹmi awọn ni.
Ọpọlọpọ mọto si lo to tẹle ara wọn lati gbe aimọye ero kuro ni agbegbe naa.
Akọroyin BBC Yoruba tẹ siwaju si awọn ilu wọn yii lati mọ ohun to n sẹlẹ nibẹ.
Iyalẹnu lo jẹ nitori pe lati ilu Ajasẹ-Ipo titi de ilu Oke-Ọdẹ ni awọn olugbe ibẹ di awọn ẹru wọn sẹba oju popo, wọn si n sọ ọkọ ti yoo gbe wọn kuro.
Awọn ilu yii to wa nilẹ Igbomina ni wọn ti n dahoro diẹ diẹ, koda, awọn olugbe awọn ilu ti wọn ko ti ṣe akọlu si, naa ti n juba ehoro.
Ohun ti wọn sọ ni pe, "iku to pa ojugba ẹni, owe lo n pa fun ni"

Ìlú Oke-Ọdẹ dá páropáro
Bẹẹ lo ṣe lọ titi de ilu Oke-Ọdẹ ti iṣẹlẹ ipaniyan ti waye gan-an.
Ilu naa, ti ọpọ eniyan wa tẹlẹ, lo ti da paroparo bayii, iwọnba awọn eeyan to sẹku ni wọn ko ẹru jade si ibudokọ lati fi ilu silẹ.
Wọn salaye pe Oke-Ọdẹ jẹ ilu ti awọn eeyan n sa wa lati awọn ilu ti ikọlu awọn agbebọn wọpọ si fun abo.
Sugbọn abo naa ko daju mọ nigba ti wọn ti ṣe ikọlu si awọn ọdẹ to n daabo bo ilu.
Ọkọ̀ tó ti kó èèyàn kúrò ní Oke-Ọdẹ ti lé ní 200 - Dẹ́rẹ́bà
Dẹrẹba ọkọ kan sọ nibẹ pe, awọn ọkọ to ti ko awọn eniyan jade lẹnu ọjọ kan ti le ni igba.
O ni gbogbo ilu ti tu tan, nitori o seese ki awọn onisẹ ibi yii maa para ilu naa, lẹyin ti wọn ti mu awọn ọdẹ balẹ.
Igbiyanju BBC Yoruba lati ba alaga tabi awọn asoju ikọ Miyetti Allah to wa ni agbegbe naa, lo ja si pabo titi di akoko ti a n ko iroyin yii jọ, amọ a si n gbiyanju lati ba wọn sọrọ.
Bakan naa, a ko ri awọn ẹbi awọn eeyan to ku ati awọn ti wọn ji gbe lọ ba sọrọ.
Wọn fi ye wa pe awọn eeyan wọn ni idalẹ, ti sare wa ko gbogbo wọn lọ.
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin nipa ohun ti ijọba ipinlẹ Kwara ati ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ naa sọ nipa isẹlẹ isekupani to waye ni Oke Ode.















