Wo bí o ṣe le è dáàbò bo ọkàn rẹ kó máa ba à kọṣẹ́ lójijì

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Ameer Ahmed
- Role, BBC World Service
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
Ọkan to ji pepe ṣe pataki fun agọ ara ẹda, ọkan naa lo maa n tu ẹjẹ jade, eyii to n gbe afẹfẹ atawọn nnkan miii kaakiri agọ ara.
Aisan ọkan 'Cardiovascular diseases (CVD) wa lara nnkan to n gbẹmi ẹda julọ lagbaye n bo ṣe n gbẹmi nnkan bii miliọnu mejidinlogun eeyan lọdọdun, gẹgẹ ọrọ ajọ WHO.
Iku mẹrin ninu marun un to n waye latari CVD n waye latari ọkan to dede kọṣẹ ati aisan rọpa-rọsẹ.
Lati mu ki ọkan rẹ wani alaafia n tumọ si, fun agbalagba, ki ọkan rẹ maa lu ni igba ọgọta si ọgọrun laarin iṣẹju kan.
Evan Levine, to jẹ olutọju arun ọkan niléẹ Amẹrika sọ pe "a le din arun ọkan ku ko to bẹrẹ nipa jijẹun aṣaraloore, ṣiṣe ere idaraya ati yiyago fun siga mimu."
Amọ ti ọkan eeyan ko ba ṣaisan, ṣe o tumọ si pe ọkan irufẹ ẹni bẹẹ ko le kọṣẹ lojiji?
Ki lo n mu ki ọkan ṣadede kọṣẹ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọkan eeeyan le ṣadede kọṣẹ ti ko ba si ọna fun ẹjẹ lati lọ sinu ọkan naa.
Ti ohun to n gbe ẹjẹ lọ sinu ọkan ba ti di, iṣan ọkan le bajẹ tabi ko bẹrẹ si n ku. Ti ko ba si itọju ni kankan, iṣẹlẹ naa le ni ipalara ti ko ni si ọna abayọ mọ.
Ti ẹka to pọ ju ninu ọkan ba ti kọṣẹ, ọkan naa ko ni ṣiṣẹ mọ ti awọn onimọ n pe ni "cardiac arrest," ẹni naa yoo si dagbere faye .
Laarin wakati mẹta si mẹrin ti ọkan ba bẹrẹ si n kọṣẹ ni yoo maa fi apẹrẹ han, idi ree to fi ṣe pataki lati tete tọju rẹ bii iṣẹlẹ pajawiri.
Ohun to ṣaba maa n fa ki ọkan kọṣẹ ni awọn ọra ninu ọkan, eyii to maa n di iṣan to maa n mu ko ṣoro fun ẹjẹ lati rekọja.
Lọdọdun 805,000 eeyan ni ọkan wọn maa n kọṣe nilẹ Amẹrika.
Ninu awọ 805,000 yii, 605,000 ninu wọn o n ni iriri naa fun igba akọkọ nigba ti 200,000 ti ni iriri ọhun ri.
Eyii n tumọ si pe eeyan kan lo maa nki iṣoro ọkan laarin iṣẹju aaya ogoji nilẹ Amẹrika.
Bawo ni o ṣe maa mọ ti ọkan rẹ ba n kọṣẹ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oniruru apẹrẹ lo le waye ti ọkan ba fẹ kọṣẹ, amọ eyii to wọnpọ julọ ni ki aya maa dun eeyan.
Fun awọn obinrin, aya le maa dun wọn ki ọrun tun maa dun wọn pẹlu.
Ọmọwe Ailin Barseghian to jẹ onimọ inpa arun ọkan ni California sọ pe ti ọkan ba fẹ kọṣe, o le kọkọ da bii igba ti ọlọ inu eeyan ko lọ ounjẹ to jẹ ṣaaju.
Amọ ọkan to ba maa kọṣẹ yoo maa mu ki awọn ibomii ni agọ ra bii apa, agbọn, ẹyin tabi ikun dun eeyan.
Awọn apẹrẹ mii ni ki oyi oju maa kọ eeyan, ki eeyan maa laagun yọbọ, ko ma le mi daadaa tabi ki eemi eeyan maa pariwo.
Lootọ ni pe ọkan awọn kan le dede kọṣẹ, nigba mii awọn apẹrẹ le kọkọ waye laarin wakati mẹta tabi ọjọ diẹ ṣaaju iṣẹlẹ ọhun.
Aya to n dun eeyan lai si ọna abayọ le jẹ apẹrẹ ọkan to ti n kọṣẹ.
Ailin Barseghian sọ pe "Lẹyin wakati mẹta, awọn iṣan ọkan yoo bẹrẹ si n ku ti ẹjẹ ko ba ṣan wọ inu rẹ daada, mo maa gba irufẹ ẹni bẹẹ lamọran lati maa jẹ oogun aspirin titi ti awọn eleto ilera yoo fi de."
Awọn onimọ sọ pe lẹsẹkẹsẹ ni eeyan gbọdọ gba itọju to ba ṣakiyesi pe ọkan oun fẹ maa kọṣẹ.
Dokita Evan Levine ni "O gbọdọ mọ irufẹ ẹni ti o jẹ ati irufẹ ewu to le koju rẹ - bii ọjọ ori rẹ, bi o ṣe sanra to, bi o ṣe n mu siga si ati itan idile rẹ boya wọn maa n ni arun ọkan nibẹ.
Awọn onimọ ti kilọ pe awọn kan n sọ pe arun ọkunrin ni arun naa amọ iwadii ti fi han pe awọn obirin ti wọn ba ni aisan ẹjẹ riru, itọ ṣuga atawọn ti wọn ba n mu siga naa le ni aisan ọhun.
Bi o ṣe le dena ki ọkan rẹ kọṣẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lara awọn ọna lati dena ki ọkan kọṣẹ ni ṣiṣe ohun to yẹ lati dena ẹjẹ riru ati eroja 'cholesterol' inu ara rẹ.
Cholesterol jẹ ohun to maa n wa ninu ẹjẹ eeyan to wulo lati mu ki ẹjẹ naa lokun si. Amọ ti iwọn awọn cholesterol kan ba ti pọ ju ninu ara, o lewu.
Awọn to n tọju arun ọkan sọ pe o daa lati gbe igbeaye ti yoo daabo bo ọkan ẹni.
Jijẹ ounjẹ ti ọra rẹ ko pọ ju, ounjẹ to ni 'fibre' daadaa dara fun agọ ara.
Ṣora fun jijẹ iyọ to pọ ju nitori ti iyọ ba pọ ju o le fa ẹjẹ riru.
Ṣọra fun jijẹ awọn ounjẹ ti wọn po pẹlu ẹrọ igbalode atawọn ounjẹ ti ọra rẹ pọju nitori o le fikun iwọn cholesterol ara rẹ.
Irufẹ awọn ounjẹ wọnyii ni keeki, pie ẹlẹran, ẹran dindin, bọta atawọn ounjẹ to ni epo pupa.
Jijẹ ounjẹ to dara pẹlu ere idaraya ni awọn onimọ ti sọ pe o dara fun ọkan ẹda.
O maa n ṣoro fun ẹni ti ko ba sanra ju lati ni ẹjẹ riru.
Awọn onimọ tun kilọ pe siga mimu le ṣakoba fun ọkan ẹni.
Ọpọ ọdọ ni okan wọn ti n kọṣe lode oni

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bo tilẹ jẹ pe awọn to ti dagba lo ṣaba maa n ni arun ọkan, iwadii kan lati ajọ US National Center for Health Statistics ti sọ pe awọn ọdọ naa ti n ni arun ọkan bayii.
Lọdun 2019, ida 0.03% ọdọ ti ọjọ ori wọn jẹ ọdun mejidinlogun si ọdun mẹrinlelogoji ni ọkan won kọṣẹ.
Nigba ti yoo di ọdun 2023, iye ida naa ti di 0.05%.
Dokita Evan sọ pe eyii ko ṣẹyin irufẹ ounjẹ ti awọn eeyan naa n jẹ ati bi wọn ṣe kọ lati maa ṣere idaraya.
Evan ni "Gbogbo wa ni lati maa lọ sinu giimu lati ṣe ere idaraya. O kọmi lominu pe asiko COVID ti mu ki ọpọ eeyan maa rẹwẹsi ki wọn si maa joko sojukan fun ọpọ wakati."
Yaọ si awọn nnkan wọnyii, Dokita Ailin Barseghian ni tirẹ ni eeyan le jogun arun ọkan bẹẹ ni awọn nnkan mii bii wahala ati aisun dede le fa arun ọkan fun eeyan.















