Aáwọ̀ PENGASSAN àti ibùdó ìfọpo Dangote dópin lẹ́yìn ìpàdé àláfíà pẹ̀lú ìjọba àpapọ̀

Dangote ati awọn ọkọ agbebo bẹntiro

Oríṣun àwòrán, Dangote Refinery

Àkọlé àwòrán, Dangote ni ara wọn atawọn adari wọn nikan ni PENGASSAN n sin, kii ṣe lati mu aye dẹrun faraalu
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Ijọba apapọ ti sọ pe gbogbo awọn oṣiṣẹ ti ileeṣẹ ifọpo Dangote da duro lẹnu iṣẹ ni yoo da pada sẹnu iṣẹ lẹyin to da si aawọ to n waye laarin ileeṣẹ ọhun ati ẹgbẹ PENGASSAN.

Ijọba ni awọn oṣiṣẹ naa ko ni padanu owo tabi ajẹmọnu kankan latari bi wọn ṣe gba iṣẹ lọwọ wọn ṣaaju.

Minisita fun ọrọ iṣẹ ati igbanisiṣẹ, Mohammed Maigari Dingyadi, lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan lẹyin ipade alaafia to ba igun mejeji ṣe.

"Ko si oṣiṣẹ kankan ti wọn yoo dunkoko mọ nitori ipa ti wọn ko ninu aawọ to waye laarin Dangote ati PENGASSAN"

O ni "Lẹyin agbeyẹwo igbesẹ ti wọn fi da awọn oṣiṣẹ naa duro, a fẹnuko nibi ipade ti a ṣe pe awọn alaṣẹ Dangote yoo bẹrẹ si n si da awọn oṣiṣẹ to da duro pada sawọn ẹka mii ninu ileeṣẹ naam.

"Ko si oṣiṣẹ kankan ti wọn yoo dunkoko mọ nitori ipa ti wọn ko ninu aawọ to waye laarin Dangote ati PENGASSAN.

"PENGASSAN ti bẹrẹ igbesẹ bi wọn yoo ṣe fopin si iyanṣẹlodi wọn. Igun mejeji si ti fẹnuko lati gba alaafia laaye."

Minisita naa sọ siwaju si pe ẹtọ oṣiṣẹ ni labẹ ofin lati darapọ mọ ẹgbẹ to ba wu u, ileeṣẹ ti irufẹ ẹni bẹẹ ba n ba ṣiṣẹ si gbọdọ bọwọ fun ẹtọ naa.

Aawọ PENGASSAN ati Dangote burẹkẹ si lẹyin ti Dangote da oṣiṣẹ 800 duro to si fi awọn mii rọpo wọn lori ẹsun pe wọn darapọ mọ ẹgbẹ oṣiṣẹ.

Aáwọ̀ PENGASSAN àti ibùdó ìfọpo Dangote gba ọ̀nà míì yọ, ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ń palẹ̀mọ́ mọ́ fún ìyanṣẹ́lọdì

Dangote ati Joe Ajaero niwaju awọn ọkọ agbepo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ede aiyede to n waye laarin ẹgbẹ PENGASSAN ati ileeṣẹ ifọpo Dangote ti gba ọna mii yọ bayii lẹyin ti ẹgbẹ oṣiṣẹ, NLC, ke si awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ lati maa murasilẹ fun iyanṣelodi.

Aṣẹ NLC yii lo n waye lẹyin aigbọraẹniye to wa laarin Dangote ati PENGASSAN latari bi Dangote ṣe da oṣiṣẹ 800 duro lẹnu iṣẹ to si fi awọn ọmọ ilẹ India rọpo wọn.

Ninu atẹjade kan ti Aarẹ NLC, Joe Ajaero fi lede lọjọ Aje ni aṣẹ ọhun ti jẹyọ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

PENGASSAN ati awọn to n ta epo ni Naijiria, NUPENG ni Dangote n dunkoko mọ awọn oṣiṣẹ rẹ, o n tẹ ẹtọ wọn loju mọlẹ bẹẹ lo si n fi iya ti ko tọ jẹ wọn.

NLC ṣalaye pe ọrọ naa ti kuro ni ọrọ PENGASSAN ati NUPENG nikan, o ti di ọrọ ija fun ẹtọ awọn oṣiṣẹ kaakiri Naijiria bayii.

Ajero sọ ninu atẹjade naa pe "Ija to n lọ lọwọ pẹlu PENGASSAN ati NUPENG yii n ṣafihan arun to jinlẹ gidi – eyii ni ni bi awọn alagabra atawọn olowo nla ṣe maa n fi awọn oṣiṣẹ wọn ṣe ẹru lai naani ofin to mọ ọrọ oṣiṣẹ."

NLC tẹsiwaju lati fẹsun kan ileeṣẹ Dangote pe o n wu iwa bii ipinlẹ to da duro ninu ipinlẹ latari bo ṣe tẹ abala ogoji ofin Naijiria loju mọlẹ, to si tun tẹ ofin agbaye nipa ọrọ oṣiṣẹ loju mọlẹ lai naani rẹ.

O ni "Asiko lati maa bẹbẹ ati lati maa ṣe ijiroro ti ko so eso rere kankan ti kọja, asiko ti to bayii lati gbe igbesẹ akinkanju.

"A fẹ ki gbogbo yin bẹrẹ imurasilẹ lati ṣe agbajọpọ gbogbo awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ Dangote to wa labẹ iṣakoso yin ni kankan."

Ajaero sọ pe eredi aṣẹ yii ko ju ọna lati ri daju pe Dangote bọwọ fun ẹtọ awọn oṣiṣẹ rẹ.

O pari ọrọ rẹ pe awọn gbọdọ gbena woju ẹkun ileeṣẹ Dangote lai fi akoko ṣofo.

Bí ìyànṣẹ́lódì àwọn òṣìṣẹ́ elépo ṣe bẹ̀rẹ̀, ìjọba àpapọ̀ dásí aáwọ̀ tó wà láàrin PENGASSAN àti ibùdó ìfọpo Dangote

Ijọba apapọ ti n gbe igbesẹ lati fopin si aawọ to n waye laarin ileeṣe ifọpo Dangote ati ẹgbẹ PENGASSAN lori ẹsun pe Dangote gba iṣẹ lọwọ awọn oṣiṣẹ rẹ to darapọ mọ ẹgbẹ ọhun to si fi awọn ọmọ orilẹede India rọpo wọn.

Minisita fun ọrọ iṣẹ, Maigari Dingyadi, ti ke si PENGASSAN pe ki wọn da iyanṣelodi wọn to bẹrẹ lana duro.

Amọ nigba to n sọrọ, ileeṣẹ Dagote bu ẹnu atẹ lu PENGASSAN pe awọn gan lo n fa ọwọ aago itẹswiaju epo rọbi Naijiria sẹyin.

Dangote ni ara wọn atawọn adari wọn nikan ni PENGASSAN n sin, kii ṣe lati mu aye dẹrun faraalu.

Igbesẹ ijọba apapọ lati yanju aawọ yii

Wayi o, minisita Maigari Dingyadi ti n gbe igbesẹ lati mu ki alaafia jọba laarin Dangote ati ẹgbẹ PENGASSAN.

Gegẹ bii ohun ti wọn sọ, ileeṣẹ to n ri si iṣẹ ati igbanisisẹ "n jiroro pẹlu Dangote atawọn adari PENGASSAN, ifẹrọwerọ wọn si ti fi han pe ko si ọna abayọ kankan ju alaafia lọ."

Ẹwẹ, Dingyadi ti parọwa si PENGASSAN pe ki wọn gba alaafia laaye ki wọn si fopin si iyanṣelodi wọn ati pe oun ti fi iwe pe awọn adari mejeji fun ipade kan ti yoo waye ninu ọọfisi oun lonii ọjọ Aje.

O rọ PENGASSAN lati da iyanṣẹlodi wọn duro lati faye gba ipade alaafia.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Patience Onuobia fi lede, o ni awọn mejeji ti aawọ wa laarin wọn yii lo ṣe pataki si ọrọ aje Naijiria, wọn si gbọdọ fopin si aawọ to n waye laarin wọn lọwọ yii.

O in "Yatọ si pe iyanṣẹlodi yoo mu ki wọn padanu owo gọbọi, yoo tun mu aye nira fun awọn ọmọ Naijiria."

Wayi o, PENGASSAN ti sọ pe awọn ko ni fopin si iyanṣẹlodi ọhun ayafi ti Dangote ba da awọn oṣiṣẹ ti iye wọn to 800 pada sẹnu iṣẹ wọn lai fọta pe.

Kí ló ń fa wahala láàárín iléeṣẹ́ ìfọpo Dangote àti PENGASSAN tí wọ́n fi kéde ìyanṣẹ́lódì?

Ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ epo àti gáàsì ní Nàìjíríà, PENGASSAN tí kéde pé àwọn máa bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì káàkiri Nàìjíríà bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹsàn-án.

Àtẹ̀jáde kan tí akọ̀wé ẹgbẹ́ náà, Lumumba Okugbawa fi léde lọ́jọ́ Àbámẹ́ta darí gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn láti bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì fún wákàtí mẹ́fà ní ọjọ́ Àìkú, kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ àdúrà ọlọ́jọ́ kan.

Àtẹ̀jáde náà ní ìyanṣẹ́lódì náà yóò kan gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ tó wà ní yàrá ètò àtàwọn òṣìṣẹ́ tó ń ṣiṣẹ́ ní ìgbooro.

PENGASSAN darí gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn tó wà ní iléeṣẹ́, àjọ àti ẹ̀ka ìjọba láti bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì bẹ̀rẹ̀ láti òru ọjọ́ Ajé.

Kí nìdìí tí PENGASAAN fi ń pè fún ìyanṣẹ́lódì?

Ẹgbẹ́ PENGASSAN nínú àtẹ̀jáde náà sọ pé ìdí tí àwọn fi fẹ́ gùnlé ìyanṣẹ́lódì náà kò ṣẹ̀yìn bí iléeṣẹ́ ìfọpo Dangote Refinery ṣe fọwọ́ òsì júwe ilé fáwọn òṣìṣẹ́ tó lé ní ẹgbẹ̀rin (800) nítorí pé wọ́n darapọ̀ mọ́ PENGASSAN.

Wọ́n júwe ìwà iléeṣẹ́ Dangote náà bí ìwà títàpá sí ẹ̀tọ́ àwọn òṣìṣẹ́ Nàìjíríà, títẹ ìwé òfin Nàìjíríà lójú mọ́lẹ̀, àìbọ̀wọ̀ fún òfin tó de òṣìṣẹ́ àti títàpá sí àpérò ILO.

Wọ́n ní Dangote gba iṣẹ́ lọ́wọ́ àwọn òṣìṣẹ́ náà nítorí wọ́n darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ tí wọ́n sì gbé iṣẹ́ wọn fáwọn ará ilẹ̀ India.

Àtẹ̀jáde tí PENGASSAN ti kọ́kọ́ fi léde ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹsàn-án ni wọ́n ti kọ́kọ́ darí àwọn alága ẹgbẹ́ wọn káàkiri láti rip é wọ́n gbégi dínà pípèsè gáàsì sí iléeṣẹ́ ìfọpo Dangote.

"Gbogbo epo rọ̀bì tó ń lọ sí iléeṣẹ́ ìfọpo Dangote ni ó gbọdọ̀ dúró. Gbígbé epo tó ń lọ sí iléeṣẹ́ náà ni ó gbọdọ̀ dúró lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀," àtẹ̀jáde náà sọ.

Nínú àtẹ̀jáde tí wọ́n fi síta lọ́jọ́ Àbámẹ́ta ni wọ́n ti sọ pé gbogbo ìgbésẹ̀ tó nííṣe pẹ̀lú gáàsì àti ìpèsè epo rọ̀bì lọ sí ilé ìfọpo Dangote ni ó máa dúró lójú ẹsẹ̀.

Wọ́n ní ohun tí àwọn máa dojú àdúrà kọ ni pé àwọn máa képe Ọlọ́hun láti kó sí àwọn tó le bá Dangote sọ̀rọ̀ nínú láti sọ fun pé ìdí tó ṣe nílò láti bọ̀wọ̀ fún òfin.

Iléeṣẹ́ ìfọpo Dangote fèsì

Iléeṣẹ́ ìfọpo Dangote lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n júwe ìdarí PENGASSAN náà bí èyí tó jẹ́ ìjayà, tó sì jẹ́ títàpá sí òfin àti ìwà ọ̀daràn.

Dangote ní kò sí òfin kankan ní Nàìjíríà tó fi ààyè gba PENGASSAN láti dènà gbígbé gáàsì àti epo rọ̀bì wọ iléeṣẹ́ ìfọpo àwọn.

Wọ́n ní ìwà ọ̀daràn ni fún PENGASSAN tàbí ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ kankan láti dènà tàbí gbégi dìnà ìbáṣepọ̀ Dangote àti àwọn iléeṣẹ́ tó ń bá ra ọjà fún ìpèsè gáàsì àti epo rọ̀bì sí ilé ìfọpo náà.