Wo obìnrin mẹ́ta tó jẹ Awùjalẹ̀ nínú ọba 56 tó jẹ nílùú Ìjẹ̀bú Òde

Oríṣun àwòrán, Collage
Yoruba ni ori ti yoo de adé, kò ní ṣe alai dade, orí tí yóò wọ ìlẹ̀kẹ̀, kò kúkú ní ṣe alai wọ ọ, bẹ́ẹ̀ ni ibadi tí yóò wọ Mọ́sàajì, aṣọ ọba to jìnnà koro koro, kò kúkú ní ṣe aláì wọ ọ.
Ìdí ni pé orí ẹni lọ ń mú ní ti a fi ń de adé owó, ọ̀rọ̀ ẹni náà lọ ń mú ní tẹ ọ̀pá ìlẹ̀kẹ̀.
Bẹẹ ni ọ̀rọ̀ ipò ọba rí nílẹ̀ Yorùbá,torí orí ẹni lọ ń gbé ní de ipo ọlà.
Bi o tilẹ jẹ pe ni asiko yii, awọn ọkunrin nìkan ló ń jẹ ọba nílẹ̀ Yorùbá àmọ́ àwọn obìnrin náà tí jẹ ọba rí ní àwọn ìlú kan.
Lara awọn ilu ti obìnrin tí jẹ́ ọba ní ìlú Ilé-Ifè níbi tí Ọọ̀ni Luwo gbagida tí jọba.
Bákan náà, obìnrin mẹta lo tí jẹ Aláàfin rí nilu Oyo, àwọn náà ni Ọba Jomijomi, Ọba Jepojepo àti Alaafin Orompotoniyun.
Àwọn obìnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó jẹ́ Awujalẹ ní Ìjẹ̀bú Òde
Bákan náà, ìtàn tún sọ fún wa nípa àwọn obinrin mẹta tí wọn ti jẹ Awujalẹ rí nílẹ̀ Ìjẹ̀bú.
Ọba Ore Gbadegun:
Àwọn obìnrin Awujale náà ni Ọba Ore Gbadegun to jẹ ọba ní ọdún 1644.
Oun si ni obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò jẹ Awujalẹ, ọdún mẹ́wàá lo sì lo lórí ìtẹ́.
Ọbabìnrin Awujale àkọ́kọ́ yìí sí ní Awujalẹ kẹrindinlọgbọn ni Ijebu Ode.
Ọba Ore Jeje
Obìnrin kejì to tun jẹ Awujalẹ ní Ọba Ore Jeje, ẹni tó jọba lọ́dún 1749.
Ọdún kan ṣoṣo sì ni ọbabìnrin Ore Jeje lo lórí ìtẹ́, kò tó dara pọ mọ babanla rẹ.
Oun si ni Awujalẹ kejidinlogoji nílùú Ìjẹ̀bú Òde.
Ohun tó wà jẹ ìyàlẹ́nu ni pé ọbabìnrin méjì ló jẹ́ ọba Awujalẹ tẹle ara wọn nílùú Ìjẹ̀bú Òde.
Ìdí ni pé ní kété tí ọbabìnrin Awujale Ore Jeje wàjà, obìnrin miran lo tún joko lórí ìtẹ́ bíi Awujalẹ.
Ọba Sapennuwa Ruba Koye
Ọbabìnrin ọhun ni Awujalẹ Sapennuwa Ruba Koye to jẹ ọba lọ́dún 1750, òun sì ni obìnrin kẹta tí yóò jẹ Awujalẹ.
Awujalẹ Sapennuwa yìí ṣí ní Awujalẹ Kọkàndínlógójì.
Ọdún marun lo sí lo lórí ìtẹ́, kò tó wàjà, tí Ọba míràn to jẹ ọkùnrin sì jókòó lórí ìtẹ́ Awujalẹ.
Àmọ́ lẹ́yìn ọba Ruba Koye, obìnrin miran kò tíì gùn orí ìtẹ́ Awujalẹ mọ títí di àkókò yìí.
Àwọn obìnrin mìíràn dìde láti jẹ Awujale ni Ijebu Ode
Bi Ọba Sikiru Adetona, Awujalẹ ilẹ̀ Ijebu, ti wọ káà ilẹ̀ sùn, ijagudu wáyé láti mú Awujale miran ti yoo gun orí ìtẹ́ lẹyin rẹ.
Ọpọ eeyan sì ni ẹnu ń yà pé àwọn obìnrin kan náà jáde síta pé àwọn nifẹ lati jẹ Awujalẹ.
Àwọn akọni obìnrin mẹta to tí jẹ́ Awujalẹ ṣáájú sì lọ jẹ ìwúrí àti awokọse rere fún wọn láti ni ìgboyà láti kéde pé àwọn fẹ́ jẹ Awujalẹ.
Wo àwọn Awujalẹ tó ti jẹ nilu Ìjẹ̀bú Òde, títí dé orí Ọba Sikiru Kayode Adetona.
1. Ọba Olu-Iwa (Ta bá ní ká wo ó finni fínnífínní, a kò l3 p3 ọba Oluiwa ni Awujalẹ àmọ́ ó wà lára àwọn èèyàn tó ṣe àwárí ìlú Ìjẹ̀bú Òde)
2. Ọba Oshin (Oshin náà kii se Ọba, Adeleye lọ jẹ nígbà tí Oluiwa wàjà, òun sì lọ di ilé mú fún Obanta to rìnrìn àjò wa lati ilu Ile Ife)
3. Obanta – 1430
4. Ọba Guru – 1445
5. Ọba Munigbuwa – 1455
6. Obanta Kejì – 1460
7. Ọba Lọja – 1470
8. Ọba Lofin – 1482
9. Ọba Apasa – 1496
10. Ọba Ganju – 1508
11. Ọba Tewogboye – 1516
12. Ọba Ruwamuda – 1520
13. Ọba Ofinran – 1532
14. Ọba Lapengbua – 1537
15. Ọba Otutubiosun – 1537
16. Ọba Moko Idowa Ajuwakale – 1540
17. Ọba Adisa – 1552
18. Ọba Abimbola - 1555
19. Ọba Jewo – 1561
20. Ọba Elewu Ileke – 1576
21. Ọba Olumisodan Elewu Ileke – 1590
22. Ọba Mase – 1620
23. Ọba Olotuseso – 1625
24. Ọba Kola – 1635
25. Ọba Ajana – 1642
26. Ọba Ore Gadegun – 1644 (Obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò jẹ Awujale)
27. Ọba Gunwaja – 1655
28. Ọba Jadiara tabi Olowojoyemeji – 1660
29. Ọba Sapokun – 1675
30. Ọba Falokun – 1687
31. Ọba Mekun – 1692
32. Ọba Gbodogi – 1702
33. Ọba Ojigi Amoyegeso – 1710
34. Ọba Liyewe Arojofaye – 1730
35. Ọba Moyege Olope – 1730
36. Ọba Ojora – 1735
37. Ọba Fesojoye – 1745
38. Ọba Ore Jeje – 1749 (Obìnrin kejì tí yóò jẹ Awujale)
39. Ọba Sapennuwa Ruba Koye – 1750 (Obìnrin kẹta tí yóò jẹ Awujalẹ)
40. Ọba Orodudu Joye – 1755
41. Ọba Tewogbuwa Kínní – 1758
42. Ọba Gbelegbuwa àkọ́kọ́ – 1760
43. Ọba Fusengbuwa – 1790
44. Ọba Setejoye – 1820
OBA ANIKILAYA
46. 45. Ọba Figbajoye Agboogunsa – 1821
46. Ọba Afidipotemole Ademuyewo – 1850
47. Ọba Atunwase Adesinbo – 1886
48. Ọba Ogbagba Agbotewole Akọkọ – 1895
49. Ọba Fusigboye Adeona – 1906
50. Ọba Fesogbade Ademolu – 1916 (Wọn lé kúrò lórí ìtẹ́)
51. Ọba Adekoya Eleruja – 1916
52. Ọba Ademolu Fesogbade – 1917 (Wọn tún le kúrò ní orí ìtẹ́ Awujalẹ fún ìgbà kejì)
53. Ọba Adenuga Afolagbade – 1925
54. Ọba Ogunnaike Fidiwogba – 1929 sí 1933
55. Ọba Daniel Adesanya Gbelegbuwa Kejì – 1933 sí 1959
56. Ọba Sikiru Oluwakayode Adetona, Ogbagba Agbotewole Kejì – 1960 sí 2025















