Saheed Osupa kan sáárá sí Burnaboy lẹ́yìn tó pè é ní 'G.O.A.T.', ìyẹn olórín tí òun gbà pé ó ta lẹ́nu jùlọ lágbáyé

Oríṣun àwòrán, instagram/BurnaBoy/Saheed Osupa
Gbajugbaja olorin Fuji, Saheed Osupa ti kan sara si olorin takasufe to ti gba ami ẹyẹ grammy, Damini Ogulu, ti ọpọ mọ si Burna Boy fun bi o ṣe ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bii olorin ó ta lẹ́nu jùlọ lágbáyé ti wọn n da pe ni Greatest of all times, iyẹn "GOAT" lede oyinbo.
Itumọ "GOAT" yii lo duro fun "ẹni tó ta lẹ́nu jùlọ lágbáyé lati irande iran", ti wọn si ma n lo ọrọ yii ni ẹka ere idaraya lati ṣapejuwe eeyan ti ọpọ gba gẹgẹ bii ọga.
Bawo lọrọ GOAT ṣe pa Burna Boy ati Saheed Osupa pọ?
Burna Boy, ṣapejuwe fi ọrọ yii tọka si Saheed Osupa, eekan akọrin Fuji, lasiko to fi n ṣe ifọrọwerọ kan pẹlu Roger Federer, odu agbalọọlu Tennis ti gbogbo agbaye mọ gẹgẹ bi odu ti ko lẹlẹgbẹ ninu ere idaraya naa.
Burna boy kopa ninu eto ori ayelujara kan ti wọn n pe ni 'GOAT talk' pẹlu Roger Federer nibi ti awọn mejeeji yii ti n fọrọ jomitoro ọrọ nipa ohun tabi ẹni ti wọn gba ni iwoye kaluku wọn gẹgẹbi agba ọjẹ lẹka wọn.
Nigba ti asiko to fun awọn mejeeji, iyẹn Burna Boy ati Roger Federer lati sọ awọn akọrin manigbagbe ti wọn mọ yii, ohun ti Burna ti mẹnu ba orukọ Saheed Osupa gẹgẹbi akọrin ti oun gba gẹgẹbi olórín tí òun gbà pé ó ta lẹ́nu jùlọ lágbáyé.
"Awọn olorin Fuji ni akọrin manigbagbe ti mo gba fun; bii Saheed Osupa"
Ki ni Saheed Osupa fọ lesi lori eyi?
Nigba to n sọrọ, Osupa ni inu dun pupọ si ohun BurnaBoy sọ nipa rẹ, eyi to tumọ si pe wọn mọ riri orin rẹ kaakiri agbaye.
Osupa, ẹni ti ọpọ mọ si Oba Orin ni awọn ọrọ ti Burna Boy sọ nipa oun ṣafihan igbelarugẹ aṣa ati ipa ti orin fuji n ni kaakiri agbaye.
"Mo mọ riri ohun ti Burna Boy, sọ nipa mi, ti emi naa si jẹ ololufẹ rẹ. Ni apapọ, a n jọ gbe orin ilẹ wa larugẹ fun agbaye ni."
Osupa tun wa dupẹ lọwọ Burna Boy ati awọn ololufẹ rẹ, to rọ wọn lati tunbọ ma ṣe atilẹyin fun orin Fuji.
"Si OluwaBurna ati awọn ololufẹ rẹ lagbaye, mo dupẹ lọwọ yin fun ifẹ ti ẹ ni si orin Fuji. Mo dupẹ pe ẹ ni igbagbọ ninu orin ilẹ wa."
O tẹsiwaju lati sọ pe oun n gbaradi lati lọ sibi ayẹyẹ orin Burna Boy to n bọ lati fi emi imore han.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post














