Àlàyé nípa ìlú tí àwọn obìnrin ti ń fún ọkọ wọn ní májèlé jẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, BBC News Mundo
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Ninu oṣu Kejila, ọdun 1929 ni igbẹjọ kan bẹrẹ nile ẹjọ kan niluu kekere Szolnok, lorilẹede Hungary.
Ẹjọ ọhun lo da lori ilu kekere kan ti orukọ rẹ n jẹ Nagyrey, nibi ti ọpọlọpọ obinrin ti n jẹjọ ẹsun pe wọn mọọmọ fun awọn ọkọ wọn ni majele jẹ.
Ileeṣẹ iroyin New York Times jabọ pe obinrin bii aadọta lo n jẹjọ pe wọn fun ọkọ wọn ni majele jẹ niluu naa.
Iwo iroyin ọhun ṣalaye pe laarin ọdun 1911 si 1929, o le ni aadọta ọkunrin ni Nagrey, to jẹ ibi ti wọn ti n ṣiṣẹ agbẹ ni aadoje kilomita siluu Budapest, ti gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra pẹlu iranlọwọ iyawo wọn.
Orukọ ti wọn sọ awọn afurasi naa ni "angel makers".
Okan lara awọn afurasi ọhun to gbajumọ julọ lasiko igbẹjọ naa ni Zsuzsanna Fazekas – to jẹ agbẹbi abule naa.
Igbeaye ni Nagyrev
Ilu kekere kan ni Nagyrev ni ẹba odo Tisza to jẹ agbegbe to tobi julọ ti wọn ti n po waini ni Hungary.
Lọpọ igba ni wọn maa n gbe ọkọ fun awọn obinrin nibẹ ninu eyii ti wọn maa n gbe ọmọge fun awọn ọkunrin to dagba ju wọn lọ daadaa.
Ninu igbeyawo naa, o ṣoro fun awọn obinrin ọhun lati kọ ọkọ wọn silẹ bo tilẹ jẹ ọpalamba iya maa n jẹ wọn nile ọkọ ọhun.
Latari pe ko si dokita kankan ni Nagyrey, Zsuzsanna Fazekas n ṣiṣẹ oniṣegun yatọ si iṣẹ agbẹbi to n ṣe.
Maria Gunya, to ba BBC sọrọ lọdun 2004 sọ pe "Imọ rẹ mu ki ọpọ eeyan maa lọ sọdọ rẹ, bẹẹ ni wọn ni igbagbọ nla ninu rẹ.
Nigba naa, ọmọde ni Gunya ti baba rẹ jẹ ọlọpaa to n ṣewadii ẹsun yii lọdun naa lọhun.
Gunya ṣalaye gbogbo igba lawọn eeyan ilu naa maa lọ si ọdọ Fazekas fun ọna abayọ si iṣoro wọn.
O ni "O bẹrẹ si n gbọ oniruru nnkan to n ṣelẹ ninu ile awọn eeyan: bii awọn ọkunrin to maa n na iyawo wọn, bi wọn ṣe n fi ipa ba awọn iyawo wọn lopọ, ti oju ọpọ awọn ọkunrin naa ko si gbe ibikan."
O sọ fun wa pe ni gbogbo igba ti awọn obinrin naa ba n ṣalaye ohun ti oju wọn n ri nile ọkọ wọn, yoo sọ fun wọn pe "Oun ni ọna abayọ si iṣoro ti wọn n dojukọ."
Ọna abayọ ọhun ko ju nnkan ti agbẹbi ọhun maa n rẹ sinu omi, lẹyin naa ni yoo po o pọ pẹlu majele gẹgẹ bii ileesẹ iroyin ilẹ Gẹẹsi, The Times ṣe jabọ.
Bi akara ṣe tu sepo

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹyin ọdun diẹ ni wọn bẹrẹ si n sin ọpọ oku ọkunrin labule naa.
Laarin ọdun 1911 si ọdun 1929, nnkan bii aadọta ọkunrin ni wọn sin oku wọn niboji Nagyrey. Pupọ wọn ni wọn jẹ ọkọ ati baale ile.
Lẹyinorẹyin, awọn alaṣẹ fura si awọn iku naa wọn si bẹrẹ si n hu oku awọn oloogbe ọhun kuro ninu iboji wọn.
Ninu aadọta oku ti wọn ṣe ayẹwo rẹ, mẹrindinlaadọta lo ni eroja 'arsemic' ninu, eyii to fi han pe wọn jẹ majele.
Gbogbo iwadii wọn lo n tọka si Fazekas.
Lọjọ kọkandinlogun, oṣu Keje, ọdun 1929, ọlọpaa lọ sile rẹ lati fi ṣikun ofin gbe.
Nigba ti wọn yoo fi de ile rẹ, wọn ri to ti gbe ọkan lara awọn majele to po pọ jẹ nigba to ri pe akara ti tu sepo fun oun.
Awọn to kọkọ jade laye

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iwadii ọlọpaa fi han pe ọdun 1911 ni awọn to kọkọ ku jade laye, eyii to jẹ ọdun kan naa ti Fazekas de abule ọhun.
Ọdun naa si ni ọpọ baale ile bẹrẹ si n fo ṣanlẹ ku latari majele ti wọn jẹ.
Amọ ṣa, niluu Szolnok, to wa lẹba ilu naa, obinrin mẹrindinlọgbọn lo jẹjọ lọdun 1929 yii kan naa.
Mẹjọ ninu wọn gba idajọ iku ti awọn to ku si dero ẹwọn.
Awọn iroyin kan sọ pe awọn obinrin naa ti n fẹ lara awọn ọmọ ẹlẹwọn ọmọ ilẹ Russia ti wọn n ṣiṣẹ ninu oko ọkọ wọn to lọ jagun loju ogun agbaye Keji.
Nigba ti awọn ọkọ wọn pada de lati oju ogun ti aye ko gba wọn mọ ni wọn gbẹmi awọn ọkunrin ọkunrin ọhun.
Ohun to ṣẹlẹ lawọn agbegbe mii to sunmọ Nagyrev

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O dabii bi pe kii ṣe awọn eyan wọnyii nikan lo gbẹmi ọkọ wọn.
Niluu Tiszakurt ti ko jina si agbegbe wọn, awọn ọlọpaa ṣawari eroja 'arsemic' ninu agọ ara awọn oku kan nibẹ amọ ko si ẹnikẹni to jẹjọ ẹsun naa.
Lapapọ, nnkan bii ọọdunrun eeyan lo jade laye lagbagbe ọhun.
Bo tilẹ jẹ pe iṣẹlẹ naa ti pẹ, itan ohun to ṣẹlẹ nibẹ ko parẹ titi di oni yii, eyii ti ko fi ọkan awọn ọkunrin agbegbe naa balẹ.
Bo tilẹ jẹ pe ko daa bi awọn obinrin naa ṣe gbẹmi awọn ọkọ wọn, a gbọ pe awọn ọkunrin ti iyawo wọn ko gbẹmi wọn bẹrẹ si n wu iwa daadaa lẹyin iku awọn akẹgbẹ wọn.












