FBI kẹde $10,000 fún ẹnikẹ́ni tó bá lè ṣamọ̀nà bí ọwọ́ yóò ṣe tẹ ọmọ Nàìjíríà tó ń wọ́ ike l'Amẹrika

Awọn oṣiṣẹ FBI ti wọn wọ ihamọra ogun ati aworan afurasi naa.

Oríṣun àwòrán, FBI

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọ ọtẹlẹmuyẹ ilẹ Amẹrika, FBI, ti ṣeleri owo ti iye rẹ jẹ ẹgbẹrun mẹwaa dọla fun ẹnikẹni to ba le ṣamọna bi wọn ṣe le mu afurasi kan to jẹ ọmọ Naijiria, Olumide Adebiyi Adediran.

Adediran, to jẹ ẹni ọdun mẹrindinlọgọta ni wọn fẹsun ṣiṣe jibiti ati ike wiwọ niluu Illinois lọdun 2021 kan.

Ninu atẹjade kan ti ajọ naa fi lede, wọn ni "FBI yoo fun ẹnikẹni to ba le ṣamọna bi ọwọ wa yoo ṣe tẹ Olumide Adebiyi Adeiran ni $10,000."

Wọn ni afurasi naa gbiyanju lati gba owo lawọn banki pẹlu iwe sọwedowo ẹlomiran to ji, bẹẹ lo tun gbiyanju lati lo orukọ ati oju awọn ẹlomiran lati ṣi apo lawọn oniruru ile ifowopamọ.

O sa kuro ni aringbungbun Illinois ninu oṣu Kejila ọdun 2001 ki igbẹjọ ẹsun iwa ọdaran ti wọn fi kan an to bẹrẹ.

Nigba ti yoo di ọjọ keji, oṣu Kinni, ọdun 2002 ni wọn fi iwe lede pe ki ọlọpaa mu lẹyin to ru ofin adehun beeli rẹ lọdun naa lọhun.

Aworan afurasi naa, Olumide Adebiyi Adeiran ti FBI fi lede

Oríṣun àwòrán, FBI

FBI sọ pe Adediran ni ajọṣepọ pẹlu awọn eeyan kan ni South Florida, o si wa lara awọn eeyan ti awọn n wa kaakiri agbaye.

Wọn juwo rẹ gẹgẹ bii ọkunrin to ga ni iwọn 5'11" to tun jẹ ẹni ti iwọn rẹ jẹ nnkan bii igba kilo, ti irun ori rẹ dudu ti awọ ẹyin oju rẹ si jẹ 'brown.'

Yatọ si orukọ abisọ rẹ to jẹ Olumide, o tun maa n pe ara rẹ lawọn orukọ miran lawujo.

Lara awọn orukọ to maa n pe ara rẹ ni "Kevin Olumide Adediran, Eric O. Williams, Maxo Alexandre, Olumide Adkins, ati Edward N. Anderson."

FBI ti wa ke si ẹnikẹni to ba mọ ibi to wa tabi iroyin nipa bi ọwọ ṣe le tẹ ẹ ki wọn kan si ọọfisi ijọba ilẹ Amẹrika to ba sunmọ wọn julọ.