Èyí ni iye àkàsọ̀ tí Oludije sípò Olubadan yóò gun, kò tó dé orí ìtẹ́

Àkọlé fídíò, Ọba jijẹ nilẹ Ibadan
Èyí ni iye àkàsọ̀ tí Oludije sípò Olubadan yóò gun, kò tó dé orí ìtẹ́

Idaluu ni iṣelu.

Ilu Ibadan da yatọ laaarin awọn ilu to ku, paapaa nipa ilana ọba jijẹ ti wọn yan laayo.

Bi eeyan yoo ba de ipo ọba Ibadan ti i ṣe Olubadan, o kere tan, ẹni naa yoo gun akasọ mejilelogun tabi mẹtalelogun ko too de ipo ọba Ibadan.

Igun meji lo maa n jẹ Olubadan, awọn naa ni igun Ẹgbẹ agba ati igun Balogun.

Bẹẹ naa lo jẹ pe oye meji to kangun si ipo Olubadan ni Ọtun Olubadan ati oye Balogun.

Mejilelogun ni akasọ igun ẹgbẹ agba bi eeyan ba fẹẹ gbabẹ di Olubadan, mẹtalelogun si ni ti Balogun.

Bi Olubadan to jẹ lati igun Balogun ba waja, ẹni ti yoo kan naa ni oloye to ga julọ ni igun ẹgbẹ agba.

Lati ipo Mọgaji agboole ni ẹni to ba fẹẹ jẹ Olubadan yoo ti bẹrẹ akasọ gigun.

Lẹyin ti wọn ba ti fi ẹni ọhun role bii Mọgaji

Akasọ Ẹgbẹ́ àgbà

To ba jẹ igun ẹgbẹ agba ni eeyan fẹẹ ba de ipo Olubadan, ibi ti yoo kọkọ ti bẹrẹ ni yìí.

Mogaji

Jagun Olubadan

Ajia Olubadan

Bada Olubadan

Aarẹ onibọn

Gbọnka

Aarẹ ẹgbẹ ọmọ Olubadan

Oota Olubadan

Lagunna

Aarẹ ago

Ayingun Olubadan

Aṣaaju Olubadan ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Bi igun ẹgbẹ agba ba fẹẹ fa ọmọ oye kalẹ, ẹni to ba wa nipo Ọtun loke pata ni yoo di Olubadan.

Aworan apa kan Ibadan

Igun Balogun

Ọmọ oye to jẹ Mọgaji lati igun Balogun yoo bẹrẹ lati igun yii:

Jagun Balogun

Ajia Balogun

Bada Balogun

Aarẹ onibọn Balogun

Gbọnka Balogun

Aarẹ ẹgbẹ ọmọ Balogun

Oota Balogun

Lagunna Balogun

Aarẹ Ago Balogun

Ayingun Balogun

Aṣaaju Balogun

Ikọlọba Balogun

Aarẹ Alasa Balogun

Agba Akin Balogun

Ẹkẹfa Balogun

Mayẹ Balogun ati bẹẹ bẹẹ lọ, ko too de ipo Balogun to pari pata.

Bi awọn Balogun yoo ba fa ọmọ oye kalẹ fun ipo Olubadan, ẹni to wa ni ipo Balogun naa ni yoo jẹ Olubadan.

Bi wọn ṣe n to o yii maa n gba ẹlomi-in ni ọdun marundinlogoji si ogoji ọdun ko too de ipo Olubadan.

Eyi lo si fa a to fi jẹ pe ọjọ ogbo ni pupọ ọmọ oye maa n de ori aleefa Olubadan ilẹ ibadan.

Ṣugbọn o ṣee ṣe ka ri Olubadan ti ko ti i dagba ju lọjo iwaju, nitori pupọ agboole Ibadan ti n fi awọn ọdọ jẹ Mọgaji, ki wọn le de ipo Olubadan ki ọjọ ogbo too de.

Ṣaa o, igbagbọ ojulowo ọmọ bibi ilẹ Ibadan ni pe, oloye to ba aburu si oloye to n bẹ niwaju rẹ nitori ikanju lati jẹ Olubadan, ko ni i de ipo naa.

Wọn gba pe ẹni to ba fẹ rere fun aṣiwaju rẹ nikan ni yoo de ipo ọba Olubadan ilẹ Ibadan.