Wo Olubadan 42 tó ti jẹ saájú Ọba Owolabi Olakuleyin àti àkókò tí wọn lò lórí ìtẹ́

Olubadan ti ilẹ̀ Ibadan, Ọba Owolabi Olakulehin ti re ìwàlẹ̀ àṣà lẹni aadọrun ọdun.
Ní òwúrọ̀ òní, ọjọ́ Keje, oṣù Keje ọdún 2025 ni Ọba Olakulehin darapọ̀ mọ́ àwọn babańlá rẹ̀.
Ọba Olakulẹyin si ni Olubadan kẹtalelogoji ti yoo jẹ, ti awọn olubadan mejilelogoji si ti jẹ siwaju rẹ.
BBC Yoruba wa se akojọpọ iye awọn Olubadan to ti jẹ siwaju Ọba Owolabi Olakuleyin ati iye ọdun ti wọn lo lori oye.
Wo awọn Olubadan to ti jẹ kọja nilẹ Ibadan, igba ti wọn joye ati iye akoko ti wọn lo lori itẹ:
Lagelu ni ọba tabi olori tabi Baalẹ akọkọ nilẹ Ibadan, oun si ni ẹni to tẹ ilu naa do, to si n se akoso rẹ, amọ a lee pe ni Olubadan akọkọ ti yoo dari ilu naa.
Amọ ko si akọsilẹ kankan nipa iye ọdun ti Lagelu lo lori itẹ nilẹ Ibadan.
Bakan naa, ọpọ awọn olori miran lo ti dari ibadan lẹyin Lagelu lati ọdun ti wọn ti da silẹ sugbọn ti orukọ̀ wọn ko si ni akọsilẹ rara.
Baalẹ Maye Okunade: 1820 si 1830 - O lo ọdun mẹwa lori oye
Baalẹ Oluyedun: :
Baalẹ Lakanle
Basọrun Oluyole: 1850
Baalẹ Oderinlo Opeagbe Idiomo/Kure: 1850 si 1851 - Ọdun kan soso pere ni o lo lori oye
Baalẹ Oyesile Olugbode: 1851 si 1864 - Ọdun mẹtala ni o lo lori oye
Baalẹ Ibikunle: 1864 si 1865 - Ọdun kan ni o lo lori oye
Basọrun Ogunmola ni Mapo: 1865 si 1867 - Ọdun meji ni o lo lori oye
Baalẹ Akere akọkọ: 1867 si 1870, ọdun mẹta ni o lo lori itẹ
Baalẹ Orowusi (Awarun) Kobomoje: 1870 si 1871, ọdun kan ni o lo lori oye
Aare Ọna Kakanfo, Obadoke Latosa: 1871 si 1885 - Ọdun mẹrinla ni o lo lori oye.

Baalẹ Ajayi Osungbekun: 1885 si 1893 - Ọdun mẹjọ ni o lo lori oye
Baalẹ Fijabi akọkọ: 1893 si 1895: Ọdun meji ni o lo lori aleefa
Baalẹ Osuntoki: 1895 si 1897 - Ọdun meji ni o lo lori aleefa
Baalẹ Fajinmi: 1897 si 1902 - Ọdun marun ni o lo lori aleefa
Baalẹ Mosaderin: 1902 si 1904 - Ọdun meji ni o lo lori aleefa
Baalẹ Dada Opadare: 1904 si 1907 - Ọdun mẹta ni o lo lori aleefa
Baalẹ Sunmonu Apampa: 1907 si 1910 - Ọdun mẹta ni o lo lori aleefa
Baalẹ Akintayo Awanibaku Elenpe: 1910 si 1912 - Ọdun meji ni o lo lori aleefa
Baalẹ Irefin: 1912 si 1914 - Ọdun meji ni o lo lori aleefa
Baalẹ Shittu Latosa (Ọmọ Aare Latosa) 1914–1925
Baalẹ Oyewole Foko: 1925–1929
Olubadan Okunola Abass Alesinloye: 1930–1946 - Oun ni Olubadan akọkọ ti yoo gba ade.
Ọdun mẹrindinlogun si ni o lo lori itẹ, oun si ni Olubadan to tii pẹ lori oye julọ.

Olubadan Akere Akọkọ: Osu mẹta pere ni o lo lori itẹ ni ọdun 1946
Olubadan Oyetunde Akọkọ: Osu Kọkanla si osu Kejila ọdun1946
Osu kan pere ni o lo lori aleefa, oun si ni saa rẹ kere julọ ninu awọn Olubadan to ti jẹ nilẹ Ibadan.
Olubadan Fagbinrin Akere Keji ní Oritamerin: Osu mẹfa ni o lo lori aleefa ni dun 1946
Olubadan Akintunde Bioku Oleyo ni Oranyan: 1947 si 1948, ọdun kan soso ni o lo lori oye
Olubadan Fijabi Keji: 1948 si1952, ọdun mẹrin ni o lo lori aleefa
Olubadan Memudu Alli Iwo Gbenla: Osu mẹta ninu ọdun 1952
Olubadan Apete: 1952 si 1955, ọdun mẹta ni o lo lori aleefa
Olubadan Isaac Babalola Akinyele: 1955 si 1964 (Oun ni Olubadan akọkọ to ka iwe).
O lo ọdun mẹsan lori itẹ.
Olubadan Yesufu Kobiowu ni Oranyan: Osu Keje ọdun1964 – Osu Kejila ọdun 1964, O lo osu marun lori itẹ
Olubadan Salawu Akanni Aminu: 1965 si 1971, o lo ọdun mẹfa lori itẹ
Olubadan Shittu Akintola Oyetunde Keji: 1971 si 1976, O lo ọdun marun lori itẹ
Olubadan Gbadamosi Akanbi Adebimpe ni Odinjo: 1976 si 1977, o lo ọdun kan lori oye.

Olubadan Daniel ‘Tayo Akinbiyi: 1977 si 1982 - Ọdun marun ni o lo lori aleefa
Olubadan Yesufu Oloyede Asanike Kinni - 1982 si 1994 - Ọdun mejila ni o lo lori aleefa
Olubadan Emmanuel Adegboyega Operinde Kinni: 1994 si 1999 - Ọdun marun ni o lo lori aleefa
Olubadan Yunusa Ogundipe Arapasowu Kinni 1999 si 2007 - Ọdun mẹjọ ni o lo lori aleefa
Olubadan Samuel Odulana Odugade Kinni 2007 si 2016 - Ọdun mẹsan ni o lo lori aleefa
Olubadan Saliu Akanmu Olasupo Adetunji, Aje Ogungunnisọ Kinni: Ọjọ kẹrin osu kẹrin ọdun 2016 si ọjọ keji osu kinni ọdun 2022.
Ọdun mẹfa ni o lo lori itẹ.















