Wo itú tàwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn le è pa láàrin ìlú lónìí láti sàmì àyájọ́ 7-7

Aworan awọn ẹlẹgbẹ okunkun pẹlu ina ti wọn da silẹ

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gbogbo ọjọ keje, oṣu Keje ọdun ni ọpọ gbagbọ pe awọn ẹlẹgbẹ okunkun ya sọtọ lati sami idasilẹ ẹgbẹ Neo-Black Movement of Africa, eyi ti a tun mọ si Black axe.

Ṣugbọn ṣaa, lọdọọdun, isami ayajọ idasilẹ naa ki i ba alaafia de fun araalu, afi ipayinkeke.

Yoruba si ni ifura ni oogun agba, bẹẹ si ni ifura naa ni agba oogun.

Idi ree tawọn ileeṣẹ ọlọpaa lawọn ipinlẹ kan ni Naijiria ṣe kilọ nipa iru itu buruku ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun jakejado orilẹede yii le pa ni ayajọ oni ti i ṣe ọjọ keje, oṣu Keje ọdun.

Atẹjade ti ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo ati Ogun fisita ti wa n sin awọn araalu ni gbẹrẹ ipakọ pe ki wọn fura nipa ọsẹ tawọn ẹlẹgbẹ okunkun naa le se.

Bakan naa, ni awọn ileesẹ ọlọpaa yii tun kede awọn igbesẹ ti wọn fẹ gbe lati sọ ete ipaniyan ati dida alaafia ilu ru, ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa fẹ gbe di asan.

Ni ti ọdun yii, wọnyi ni ohun ti ileeṣẹ ọlọpaa kilọ pe o ṣee ṣe kawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa danwo:

  • Awọn ẹgbẹ okunkun alatako le bẹrẹ ija agba pẹlu ẹgbẹ okunkun Black Axe tabi Aiye
  • Wọn le fẹẹ gbẹsan iwa ika ti wọn ti hu sira wọn ri
  • Wọn le gbabẹ bẹrẹ si i pa ara wọn
  • Ẹgbẹ okunkun Aiye le lo ayajọ oni lati mu awọn eto iparun ti wọn la kalẹ ṣẹ
  • Eyi le bi ija igboro ati gbigba ẹsan lara ọmọ ẹgbẹ mi-in to ba ti ṣẹ wọn tẹlẹ
  • Awọn kan le deede kora jọ pọ sibi kan, eyi ti ki i ri bẹẹ tẹlẹ, lati da alaafia ilu ru.

Awọn ikilọ ọlọpaa fun araalu lati pin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun nipa iwa ibi wọn

Lati dena rogbodiyan lo le ti ọwọ awọn ẹlẹgbẹ okunkun wa lonii, ileeṣẹ ọlọpaa kede pe oun ti ṣepade pẹlu awọn olotẹẹli, awọn onibudo igbafẹ, ilee faaji ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Wọn kilọ pe kawọn onileeṣẹ yii mọ iru awọn eeyan ti wọn yoo gba lalejo ni 7-7, ko ma di pe awọn ẹlẹgiri yoo lo ibẹ fun iṣẹ ibi ati jagidijagan.

Ileeṣẹ ọlọpaa kilọ pe kawọn obi, alagbatọ, olori agbegbe ati awọn alẹnulọrọ gbogbo, ba awọn ọmọ wọn sọrọ nibi ti wọn ti n gbọ.

Wọn ni ki wọn jẹ kawọn ọmọ mọ ewu to wa ninu lilọwọ si jagidijagan, ati ijiya ti ofin la kalẹ fun un.

Bakan naa ni wọn rọ araalu lati foju ṣọri, ki wọn si tete fi akojọpọ awọn eeyan to ba mu ifuradani to ọlọpaa leti.

Wọn ti ṣeto awọn ọlọpaa sawọn ibi to yẹ bi wọn ṣe wi, ki kele le gbe ọmọ to ba tasẹ agẹrẹ.

Lati ran araalu to ba fẹẹ ta ọlọpaa lolobo lọwọ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Oyo, CSP Osifeso Adewale, fi awọn nọmba ẹrọ ibanisọrọ yii sita lati pe ni pajawiri:

615 - 08081768614, 09054133071 ati 09061299291

Kí ni ayajọ 7-7 tumọ si ?

Aworan ada, aake, akengbe ẹmu nisalẹ ati fila loke

Oríṣun àwòrán, Others

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bo tilẹ jẹ pe igbagbọ ọpọ eeyan ni pe ọjọ keje, oṣu Keje ni wọn fi n sami idasilẹ ẹgbẹ Neo Black Movement of Africa (NBM), ko sibi ti wọn kọ ọ si loju opo ayelujara wọn pe ayajọ idasilẹ awọn niyẹn.

Ṣugbọn gbogbo 7-7 ni ikilọ maa n waye, koda, awọn ẹlẹgbẹ okunkun mi-in gan-an yoo maa dunkooko mawọn eeyan lati bọwọ fun ọjọ naa.

Ohun ti ẹgbẹ naa sọ pe awọn wa fun ni lati gbe iran eeyan dudu ga kaakiri agbaye.

Ati fun fifi opin si ẹlẹyamẹya, ifiyajẹni kaakiri agbaye.

Gẹgẹ bi awọn akọsilẹ kan ṣe wi, awọn akẹkọọ mẹsan-an kan ti wọn jẹ ọmọ Naijiria lo da ẹgbẹ "Neo-Black Movement of Africa" (NBM) silẹ laaarin 1970, lati tako ẹlẹyamẹya kaakiri agbaye.

Ṣugbọn lati bii ọdun meloo kan sẹyin bayii ti awọn ọlọpaa lati US, UK ati Canada ti n tọpinpin ẹgbẹ naa ni wọn ti n sọ pe ẹgbẹ okunkun ni.

Wọn fẹsun kan wọn pe wọn n lọwọ si magomago, gbigbe oogun oloro ati tita eeyan si oko ẹru .

Ni Naijiria, 7-7 ki I lọ lai si ikilọ lati ọdọ awọn agbofinro, nitori ikọlu awọn ẹlẹgbẹ okunkun si ni.

Orukọ Black ace ti wọn si tun mọ wọn si, jẹyọ ninu aworan idanimọ wọn ti i ṣe aake ti wọn ni awọn fi n ge imunisin ni.