Kí ni òfin sọ lórí ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú tó ń ṣe àgbáríjọ nínú ẹgbẹ́ míì bí Labour Party ṣe fún Peter Obi ní gbèdéke láti fẹgbẹ́ sílẹ̀?

Oríṣun àwòrán, LABOUR PARTY/X
Ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party, LP ti fún olùdíje sípò ààrẹ níbi ètò ìdìbò gbogbogbò ọdún 2023 lẹ́gbẹ́ náà, Peter Obi ní gbèdéke ọjọ́ méjì láti kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ wọn.
Èyí ló ń wáyé bí Peter Obi ṣe darapọ̀ mọ́ àwọn àgbáríjọpọ̀ alátakò tí wọ́n kéde pé ẹgbẹ́ òṣèlú African Democratic Congress, ADC ni àwọn máa lò gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ òṣèlú láti tako ààrẹ Bola Tinubu níbi ètò ìdìbò ọdún 2027.
Ṣáájú ni Peter Obi ti sọ pé ẹgbẹ́ òṣèlú ADC máa ri dájú pé àwọn máa fi àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣáájú gbogbo nǹkan tí àwọn bá ń ṣe.
Ọ sọ èyí lẹ́yìn tó wà níbi ìpàdé tí wọ́n ti kéde ẹgbẹ́ òṣèlú ADC gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ tí wọ́n fi máa yẹ aga mọ́ ààrẹ Tinubu nídìí 2027.
Peter Obi sọ pé ìpinnu láti ṣe àtìlẹyìn fún ẹgbẹ́ náà kò rọrùn rárá àmọ́ ìfarajìn òun ni láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tó kájú òṣùwọ̀n láti ri pé Nàìjíríà dé àbúté ògo.
"Ìpinnu yìí kò rọrùn rárá. Ó wá láti inú ìrònújinlẹ̀ lórí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti ọ̀nà tí a nílò láti gbà láti tẹ Nàìjíríà síwájú.
"Kò sí ẹgbẹ́ kan tó le dá Nàìjíríà tún ṣe. Láti ṣe àtúnṣe àwọn nǹkan tó bá Nàìjíríà jẹ́ dé ààyè tó wà lónìí, a nílò láti gbégi dínà àwọn nǹkan, èyí tí kò rọrùn rárá."
Ó ní òun gbàgbọ́ pé Nàìjíríà tuntun le wáyé.
Peter Obi kò sọ nínú ọ̀rọ̀ pé bóyá òun ti fi ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party tó wà sílẹ̀ láti darapọ̀ mọ́ ADC.
A fún ọ lọ́jọ́ méjì péré - Labour Party
Ẹ̀wẹ̀, ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party ti ní àwọn fún Peter Obi ní gbèdéke ọjọ́ méjì láti kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ àwọn.
Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ ẹgbẹ́ náà, Obiora Ifoh fi sórí ìkànnì X ẹgbẹ́ Labour Party lọ́jọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹta, oṣù Keje sọ pé ẹgbẹ́ àwọn kò ṣetán láti darapọ̀ mọ́ àwọn tó jẹ́ pé wọ́n kàn ń wá ipò agbára lásán ni.
Ó ní àwọn tó ba Nàìjíríà jẹ́ débi tó dé báyìí ni wọ́n kóra wọn jọ́ síní àgbáríjọpọ̀ náà àti pé ààpò ara wọn lásán ni wọ́n ń jà fún.
Wọ́n ní àwọn mọ̀ pé Peter Obi ti ń gbìyànjú láti bá àwọn kan sọ̀rọ̀ nínú ẹgbẹ́ àwọn láti darapọ̀ mọ́ òun lọ sí ADC àti pé gbogbo ìpàdé alẹ́ tó ń ṣe làwọn ń gbọ́.
"A mọ̀ pé àwọn kan ti kọ̀ pé àwọn kò tẹ̀le, a sì tẹnumọ pé àwọn ò darapọ̀ mọ́ àwọn kankan ṣáájú ètò ìdìbò tó ń bọ̀.
Agbẹnusọ ẹgbẹ́ Labour Party náà fi kun ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àwọn fún Peter Obi ní ọjọ́ méjì láti ṣe ìpinnu ohun tó bá fẹ́ ṣe tàbí kó fi ẹgbẹ́ àwọn sílẹ̀.
Ṣé ó ṣeéṣe kí ẹni tó wà nínú ẹgbẹ́ òṣèlú kan tún máa ṣe àgbáríjọ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú míì láì fi ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ sílẹ̀?
Níbi ìpàdé tí wọ́n ti kéde ADC gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ òṣèlú táwọn alátakò fẹ́ lò láti kojú Tinubu náà ni wọ́n ti fún David Mark àti Rauf Aregbesola ní káàdì ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú náà.
Ṣáájú àsìkó yìí ni ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní ìpínlẹ̀ Osun ti ní àwọn ti lé Aregbesola kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú náà fún àwọn ẹ̀sùn pé ó ń ṣiṣẹ́ tako ẹgbẹ́.
Bákan náà ni David Mark ti kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀ pé òun kò ṣe ẹgbẹ́ òṣèlú PDP mọ́.
Ìbéèrè tó gbẹnu ọ̀pọ̀ èèyàn ni pé kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí Peter Obi, Atiku Abubakar, Nasir El-Rufai àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ tí wọ́n ní ẹgbẹ́ òṣèlú yàtọ̀ sí ADC tí wọ́n ti ń ṣe àgbáríjọ.
Gẹ́gẹ́ bí Dókítà Gbade Ojo ṣe sọ̀, ó ní òfin tó ń rí sí ètò ìbò ní Nàìjíríà ìyẹn "Electoral Act" sọ ni pé tí ẹgbẹ́ òṣèlú tí èèyàn bá wà kò bá gbe èèyàn mọ́, ààyè wà láti kọ̀wé fi ẹgbẹ́ náà sílẹ̀.
Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òfin kò fi ààyè gba èèyàn láti jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú méjì, èèyàn le fi iṣu síná kó máa fọgbọ́ wá ọ̀bẹ.
Ó ṣàlàyé pé àwọn tí wọ́n ń kó ara wọn jọ yìí ń gbìyànjú láti palẹ̀mọ́ sílẹ̀ de ètò ìdìbò ọdún 2027 ni.
Ó sọ pé tó bá ti ku oṣù mẹ́fà sí ètò ìdìbò, gẹ́gẹ́ bí òfin ṣe là á kalẹ̀, ni àwọn èèyàn náà máa mọ odó ti wọ́n máa da ọ̀rúnlá sí.
"Àwọn tí kò ì tíì fi ẹgbẹ́ òṣèlú wọn sílẹ̀ ní oore di ìgbà tí ètò ìdìbò máa ku oṣù mẹ́fà kí wọ́n tó kọ̀wé fi ẹgbẹ́ sílẹ̀.
"Ó ní iye oṣù tí òfin sọ pé èèyàn gbọ́dọ̀ lò nínú ẹgbẹ́ tuntun kó tó le gbé àpótí ìbò.
"Tí wọ́n bá ibi tí ADC ń lọ, wọ́n máa ma kọ̀wé fipò sílẹ̀ tàbí kí wọ́n padà sínú ẹgbẹ́ tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀, wọ́n fẹ́ mọ bí ètò ṣe máa tò ní ẹgbẹ́ tuntun tí wọ́n ń lọ.
Festus Adedayo sọ pé òun ní ìgbàgbọ́ pé àwọn èèyàn náà máa kọ̀wé fipò wọn sílẹ̀ lẹ́gbẹ́ òṣèlú tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó gbégbá ìbò nítorí ó le ṣokùnfà kí wọ́n má rì í ipò tí wọ́n ń wá.














