Obìnrin tó ń fún omi ọyàn fáwọn ẹbí tó nílò rẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́

- Author, Saida Swaleh
- Role, BBC News, Nairobi
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Chelimo Njoroge ṣe ìrántí ọjọ́ tí ẹ̀rọ amóńjẹdì rẹ̀ kún fọ́fọ́ tí kò ṣe é tì mọ́.
"Mo ti kó nǹkan sínú rẹ̀ fọ́fọ́. Bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀rọ amóńjẹtutù. Mo tún ti bẹ̀rẹ̀ sí ní lo ti àbúrò," ó rẹ́rìn-ín bó ṣe ń sọ̀rọ̀.
Ìyá ọlọ́mọ méjì, ẹni ọdún mẹ́rìndínlógójì náà tó ń gbé ní Nairobi, orílẹ̀ èdè Kenya ṣàwárí rẹ̀ pé òun máa ń pèsè omi ọyàn lọ́pọ̀lọpọ̀. Kódà lẹ́yìn tí kò bá fún ọmọ rẹ̀ lọ́yàn mọ́, ó ṣì máa ń pèsè ọ̀pọ̀ omi ọyàn lọ́pọ̀ yanturu.
Ó wá wò ó pé dípò kí òun máa da omi náà nù, kí òun máa fún àwọn tó nílò rẹ̀.
Fún bíi ọdún, Chelimo ti ń ṣe ìrànwọ́ fáwọn èèyàn, bó ṣe ń fún wọn ní àwọn omi ọmú fáwọn ìyá mẹ́jọ míì ní agbègbè rẹ̀ tó fì mọ́ àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn tó kàn si nígbà tí wọ́n rí fídíò rẹ̀ lórí ayélujára.
"Mo rí ọ̀kan lára àwọn fídíò tó fi sórí TikTok níbi tó ti ṣàfihàn àwọn mílìkì tó wà nínú fírísà, mo sì lanu," Maryann Kibinda tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí Chelimo ti f;un ní omi ọmú sọ.
"Mo kàn si, mo sì sọ pé mo nílò omi ọyàn."
Ní ọjọ́ tó ṣe àgbékalẹ̀ omi ọmú kẹ́yìn, lítà mẹ́rìnlá ló gbé kalẹ̀.
Ìrírí Chelimo nígbà tó máa bẹ̀rẹ̀ sí ní fún ọmọ lọ́yàn kò rọrùn bẹ́ẹ̀. Ó ní ọmọ òun kò tètè rí ọyàn mu tó sì jẹ́ pé òun nílò ẹ̀rọ láti fa omi jáde lọ́yàn òun ni. Àmọ́ nígbà tó yá omi bẹ̀rẹ̀ sí ní jáde lọ́pọ̀ yanturu débi pé kò lè tọ́jú wọn mọ́.
"Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ fífa omi ọyàn mi jáde, mo ní omi ọyàn tó le tó fún àádọ́ta ọmọ," ó sọ.
Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé àwọn fídíò sórí ayélujára láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìlàkàkà àti ìpèníjà nípa fífún ọmọ lọ́yàn, tó sì ń ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ́tótó àti bí èèyàn ṣe lè fi omi ọyàn pamọ́.
Nígbà tó bẹ̀rẹ̀, péréte ni àwọn tó ń wo fídíò rẹ̀ àmọ́ èèyàn tó lé ní 16,000 ni wọ́n ń wò ó báyìí tí ara wọn sì jẹ́ àwọn tí wọ́n bíi tirẹ̀ nígbà táwọn míì jẹ́ àwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́ lórí omi ọyàn.
"Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìyá ni wọ́n fẹ́ máa ṣàgbékalẹ̀ omi ọyàn fún ìrànwọ́ ṣùgbọ́n a ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó fẹ́ gbà," ó sọ.

Ilé iṣẹ́ tí wọ́n ń kó omi ọyàn pamọ́ sí
Orílẹ̀ èdè Kenya ní ibi tí wọ́n máa ń kó omi ọyàn pamọ́ sí tó wà ní ilé ìwòsàn Pumwani Maternity Hospital tó wà ní Nairobi ṣùgbọ́n àwọn èèyàn tó bá wà nílé ìwòsàn náà nìkan ni wọ́n máa ń gbà á lọ́wọ́ wọn tó sì jẹ́ pé àwọn ọmọ tó bá wà lórí àárẹ̀ nìkan ni wọ́n máa ń fún.
Èyí kò lè jẹ́ kí àwọn èèyàn bíi Chelimo ní àǹfàní láti fi omi ọyàn wọn ṣe ìrànwọ́ tó bó ṣe yẹ.
Adarí iléeṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ oúnjẹ ní Nairobi, Esther Kwamboka Mogusu sọ pé èròńgbà àwọn ni láti ri pé wọ́n sọ Pumwani Maternity Hospital láti jẹ́ oríko tó le fààyè gba omi ọyàn ju bó ṣe wà lọ.
"A máa ṣe ìdásílẹ̀ àwọn ààyè méjì si láti lè ṣe ìrànwọ́ fáwọn ọmọdé míì kọjá àwọn tó wà nílé ìwòsàn nìkan," ó sọ.
Iléeṣẹ́ ètò ìlera ń lájọṣepọ̀ pẹ̀lú ìjọba ẹkùn Nairobi àti PATH tí wọ́n sì ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lójúnà àti ri pé àwọn tó ni omi ọyàn láti gbé kalẹ̀ ríbi ṣe bẹ́ẹ̀.
Adarí ẹ̀ka tó ń rí sí ọ̀rọ̀ oúnjẹ ní iléeṣẹ́ ètò ìlera Kenya, Veronica Kirogo sọ pé àwọn ti gbé àwọn ètò kalẹ̀ àti mú ètò Mother Baby Friendly Initiative Plus (MBFI+) di ìrọ̀rùn tó fi mọ́ ṣíṣe ààyè tí wọ́n le gbé omi ọyàn sí.
Ó ní ètò náà máa rí níní ààyè gbígba omi ọyàn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà tó ṣe kókóláti ṣe ìrànwọ́ fáwọn ọmọdé àti ìlànà fún bí wọ́n ṣe le mú ìlera àwọn ọmọdé ní òkúnkúndùn.
Agbẹ̀bi kan tó tún jẹ́ onímọ̀ nípa omi ọyàn, Mary Mathenge gbà pé àlàfo tó pọ̀ wà àmọ́ wọ́n gbọdọ̀ ṣe pẹ̀lépẹ̀lé. Ó gbàgbọ́ pé Kenya nílò ìlànà láti ṣe àmójútó gbígba omi ọyàn pamọ́ pẹ̀lú ìrírí tó tin í láti ogójì ọdún tó ti ń bá àwọn tó ń fọmọ lọ́yàn ṣiṣẹ́.
"Kò sí ọmọ tí kò lè gba omi ọyà láti ọdọ̀ ẹnikẹ́ni," ó sọ.
"Àmọ́ ohunkóhun tó bá ṣe é gbà láti ara ẹ̀jẹ̀ le gba omi ọyàn wọ ara ọmọ, wọ́n gbọdọ̀ ṣe àyẹ̀wò fún ìyá tó fẹ́ gbé omi ọyàn sílẹ̀.
"Ìlànà gbọ́dọ̀ wà fún àyẹ̀wò àti fífi omi ọyàn náà pamọ́ bó ṣe yẹ. Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ ọmọ máa lè jẹ àǹfàní lọ́nà àlááfíà."

Chelimo ní òun ti lò lára àwọn omi ọyàn òun tó ṣẹ́kù fáwọn nǹkan míì bíi lílò ó fún ọṣẹ ìwẹ̀ èyí tí ìgbàgbọ́ wà pé ó máa ń jẹ́ kára àwọn ọmọ jọ̀lọ̀.
Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ rẹ̀ ló máa ń lọ sí àwọn ẹbí tó ń là kàkà láti fún àwọn ọmọ wọn lọ́yàn.
Ipa rẹ̀ láwọn kan ti ń kan sáárá sí lórí ayélujára, tí wọ́n sì fun ní orúkọ "The Liquid Gold Angel"
Àmọ́ Chelimo máa ń ṣe ìrántí kìí ṣe ọ̀rọ̀ òun nìkan pé ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin ló dàbí òun.
Bí ó ṣe ń pa ẹ̀rọ amóńjẹdì rẹ̀ dé fún ìgbà ìkẹyìn, ó gbèrò pé ìjíròrò lórí pípèsè omi ọyàn fáwọn tó nílò rẹ̀ ń tẹ̀síwájú àti pé ọ̀pọ̀ àwọn ìyá tó nílò omi ọyàn tó ní àlááfíà ni wọ́n ri gbà.












