A ti bẹ̀rẹ̀ ètò báyìí lát bẹ́ àwọn Bàbá ńlá wa lọ́wẹ̀ sáwọn tó ṣe ìkọlù sí Ọwọ- Olowo

aworan olowo ti ilu owo

Oríṣun àwòrán, screenshot

Wọn ti bẹrẹ eto ifọlumọ ati ibẹnilọwẹ àwọn agba ni Owo bayii-

Awọn Oba alaye ni ijọba ibilẹ Ọwọ labẹ idari Ọlọwọ ti ilu Ọwọ, Ọba Ajibade Gbadegẹṣin Ogunoye kẹta ni yoo ko awọn ẹlẹsin ibilẹ jọ loni.

Eyi je ona lati lo ọna abalaye lati fi mu awọn to ṣe kọlu si ijọ Saint Francis Catholic Church ni ilu naa lọjọ karun oṣu yi.

Atẹjade kan lati ọwọ akọwe iroyin ọba alaye ọhun, Samuel Adewale, fi yeni pe awọn to n bọ Ogun ni yoo korajọ labẹ abojutu gbogbo ori ade to wa ni ijọba ibilẹ naa lati bọ Ogun lojuna ati ri awọn to ṣe iṣẹ laabi ọhun.

Irubọ naa ni wọn wipe yoo bẹrẹ nii deedee agogo meji ọsan oni, ọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹfa.

Won ti bẹrẹ eto iṣẹṣe ni Owo bayii

Lakoko ti irubọ ọun ba n lọ lọwọ, igbokegbodo ọkọ ni ko nii si igbalaaye fun laarin orita Èkùsì si orita First Bank to jẹ agbeegbe ti irubọ naa yoo ti waye.

Ṣaaju ikede pe irubọ yi yoo waye ni ọpọ awọn to ṣe abẹwo ibanikẹdun si aafin Ọlọwọ ti parọwa pe ki kabiyesi naa o lo ilana abalaye lati fi wa ojutu si iṣẹlẹ ọun ati lati le pinwọ irufẹ akọlu bẹẹ lọjọ'waju.

Igbesẹ yi lo n waye laarin wakati mẹrinlelogun ti wọn yoo ṣe isinku apapọ fun awọn to padanu ẹmi wọn ninu akọlu naa.

Aworan Ooni Ile Ife

Oríṣun àwòrán, Facebook/ooniadimulaife/

Àkọlé àwòrán, Ọ̀rọ̀ eto aabo ilẹ̀ Yoruba ti gba ifowosowopo

Àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ Osun nawọ́ ìrànwọ́ sí Ọ̀wọ̀ lórí aàbò, ẹ wò ọnà tí wọn fẹ̀ gbé e gbà

Orisirisi ni aba ati imọran ti awọn eeyan n gba awọn alaṣẹ Naijiria lọna ati pese aabo to peye.

Ni paapaa nilẹ kaarọ o jiire nilẹ oni to mọ, awọn ẹlẹsin abalaye ti nawọ iranwọ nipa ipeese aabo si ijọba ati awọn araalu ipinlẹ Ondo.

Eyi ko ṣẹyin ikọlu to waye laipẹ yi si ile ijọsin St Francis Catholic Church, Owo.

Idi si ree ti aarẹ fawọn ẹlẹsin ibilẹ nipinlẹ Osun Dokita Oluseyi Atanda fi ni awọn le ṣe iranwọ fun Ondo lori ipenija aabo yi.

Dokita Atanda to tun jẹ Ajana Awo fun Olu Osogbo sọ pe akọsilẹ ti ko lọ jina ninu itan Yoruba ti fi han pe iru ipenija to delẹ yi kii ṣe nkan ti ko lojutu.

''Bi ọmọde ko ba ba itan, o ba arọba to jẹ baba itan. Ifa lo le ba wa se nitori aimọye ogun to ti waye sẹyin nini itan to ṣe pe ifa ti ba wa ṣẹgun kọja nilẹ Yoruba.''

''Eyi ti ko lọ jina ni Ogun Kiriji, a mọ pe Imẹsi nibi ni Osun aworawo olu lo ti ba da ogun duro.''

Aworan awọn ẹlẹsin ibilẹ

Oríṣun àwòrán, Facebook/ooniadimulaife/

O ni awọn ilẹ Yoruba kan wa bi Igbeti,Osogbo ati Ogbomosho ti ogun ko ja wọn ri.

Ni paapa lo si tun ṣakawe igba tawọn kan n gbe ogun bọ lati Ilorin wa ja Osogbo.

''Nigba ti ogun n ko wọn bọ lati Ilorin Osun aworawo olu lo ba wọn ṣẹgun rẹ''

O tẹsiwaju pe Ifa ni pe ki wọn lọ ree bọ Osun ati pe Osun ti wọn bọ lo da etutu Gbegiri ati amala ti wọn lọ gbe si ibode ni Imesi.

''Gbẹgiri ati amala ti wọn gbesi ibẹ ni wọn jẹ ti gbogbo si bẹrẹ si ni kuu lọ''

A ti nawọ iranwọ si wọn ni Owo

O ni awọn ṣẹṣẹ da Ifa fun ilẹ Yoruba lasiko ọdun Ifa oke itasẹ to lọ ni ọjọ Abamẹta akọkọ ninu oṣu Kẹfa yi ni.

Ninu rẹ Ajana Awo sọ pe Ifa sọ fawọn pe ogun ti de ṣugbọn o la ilana kalẹ ti awọn ilu kọọkan,Gomina ati araalu gbọde ṣe.

''Bi igba pe o ṣe rẹgi ni pẹlu nkan to waye ni Owo yi. A o ti da ifa silẹ tan.Bi igba

pe ajẹ ke lana ni ti ọmọ si ku loru ''

''Eyi to de si Owo yi ako mọ ibi ti yoo kan tori naa a gbọdọ gbe igbesẹ to yẹ. Gbogbo wa gbọdọ gbaruku ti ara wa, ki a si pawọ so wọ pọ.''

O ni awọn ko ni ibọn awọn ko ni ada ṣugbọn gbogbo nkan ni ipa Ifa ka.

Ọrọ ti Dr Atanda yi sọ ṣe rẹgi pẹlu ti Oloye Ifagbenusola Atanda to jẹ Asiwaju awo agbaye.

Oun naa sọ ninu atẹjade kan pe asiko ti to bayi lati lo ọna idaabo ibilẹ lati kọdi awọn to n da omi alaafia ilẹ kaarọ o jiire ru.

Aworan awọn ẹlẹsin ibilẹ

Oríṣun àwòrán, Facebook/ooniadimulaife/

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: