Bíṣọ́ọ̀bù, ìyàwó àti àwakò rí ìtúsílẹ̀ gbà kúrò lọ́wọ́ àwọn agbébọn

Àwòrán àwọn ajinigbe agbebon

Bisọọbu ti ijo Anglican ẹkun Jebba nipinlẹ Kwara, Rt Rev Aderogba Adeyinka pẹlu iyawo ati awako ti ri itusile lọwọ awọn ajinigbe lẹyin ti awọn agbebon naa ji wón lojo aiku ose yii.

Aderogba ni wọn gbe oun, iyawo ati awakọ rẹ sa agbako awọn ajinigbe agbebon naa lọ lopopona Oyo si Ogbomoso.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Adewale Osifeso lo fidi iroyin naa mulẹ fun awọn akọroyin ni ana ode yii.

O ni kete ti iṣẹlẹ naa sẹlẹ ni ileeṣẹ olopaa ipinlẹ Oyo ti bere iwadi, ti wọn si fi ọpọlọpọ awọn ọmọ ogun olopaa ransẹ si agbegbe naa lati ri pẹ awọn tọkọyaya pẹlu awako wọn ri itusile.

Osifeso tẹsiwaju ni iwadi fihan pẹ awọn ajinigbe agbebon naa ti tele awọn molebi naa lati igba ti ọko ti yoonu ni agbegbe Yewa ni ipinlẹ Ogun

Ni ipari oro Osifeso, “ iwadi lo lati ri pe ọwo tẹ awọn ajinigbe agbebon naa fun idajọ to yẹ labe ofin orilede Naijiria

Àwọn agbébọn jí Bíṣọ́ọ́bù, ìyàwó àti awakọ̀ rẹ̀ gbé lọ ní Oyo

Gunmen

Oríṣun àwòrán, @SaharaReporters

Awọn agbebọn ti ji Biṣọọbu ijọ Anglican kan, Rev Oluwaseun Aderogba gbe lọ ni ipinlẹ Oyo.

Aderogba, to jẹ Biṣọọbu ẹkun Jebba nipinlẹ Kwara ni wọn gbe oun, iyawo ati awakọ rẹ lọ lopopona Oyo si Ogbomoso.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Adewale Osifeso lo fidi iroyin naa mulẹ fun awọn akọroyin.

O ni alufaa kan, Rev Adekunle Adeluwa lo kọkọ fi ọrọ naa to ileeṣẹ ọlọpaa leti ni agọ ọlọpaa to wa ni Atiba.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, iwadii awọn fi han pe ọkọ Biṣọọbu naa taku lasiko to n rinriajo lati ilu Yewa, nipilẹ Ogun si Jebba, ni ipinlẹ Kwara.

O fikun pe awọn ti dari ọga ọlọpaa to wa lagbegbe naa lati bẹrẹ iṣẹ lori bi wọn ṣe doola awọn eeyan ọhun.

O ni “ Awọn oṣiṣẹ akọṣẹmọṣẹ ẹka to n gbogun ti ijinigbe ati igbesunmọmi, to fi mọ awọn ọdẹ ati fijilante ti bẹrẹ iṣẹ lari doola awọn eeyan naa.”

“Ẹwẹ, ẹka SCID tun ti n ṣiṣẹ lati ri daju pe wọn doola awọn eeyan naa lai ni ipalara kankan.”

Agbẹnusọ ọlọpaa naa pari ọrọ rẹ pẹlu arọwa si awọn araalu lati tete maa ke si awọn ọlọpaa ti wọn ba kofiri awọn ti wọn ba funra si gẹgẹ bii ọdaran lagbegbe wọn.

O ni “A fẹ ki awọn araalu lọ fi ọkan balẹ nitori a oo daabo bo wọn, ki wọn ma si gbagbe lati maa fi ọrọ to wa leti ni gbogbo igba ti wọn ba kofiri awọn ọdaran layika wọn.”