Adájọ́ da ẹjọ́ Ilana Omo Oodua nu, tó ní kí wọn wọ́gilé ìbò gómìnà Ekiti àti Osun

Alagba Banji Akintoye ati ami ile ẹjọ

Adajọ Banji Ikuewumi tile ẹjọ giga tijọba apapọ to n joko nilu Ado-Ekiti ti wọgile ẹjọ ti ẹgbẹ ajijagbara fun ilẹ Yoruba, Ilana Omo Oodua (IOO) pe.

Ẹgbẹ Ajijagbara naa lo n tako amulo ofin ọdun 1999, to si ni ofin naa ko fẹsẹ mulẹ mọ, ti ko si le sisẹ.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ lori ẹjọ naa, adajọ ni agbẹjọro agba fun ilẹ wa ati ajọ eleto idibo, INEC ko tii yọju sile ẹjọ tabi fi agbẹjọro olujẹjọ ransẹ lati igba ti igbẹjọ naa ti bẹrẹ.

Amọ o salaye pe ajọ INEC ati agbẹjọro agba ko ni ibujoko wọn nipinlẹ Ekiti, nitori naa, ile ẹjọ giga ilu Abuja lo yẹ ki ẹgbẹ IOO ti pe ẹjọ naa.

Bakan naa lo fikun pe awọn olupẹjọ ẹfẹẹfa to pe ẹjọ naa lorukọ ẹgbẹ Ilana Omo Oodua lagbaye ko fi ẹri to daju han pe ofin ọdun 1999 lo dangajia to, to si n sakoba fun wọn.

Adajọ Ikuewumi tẹsiwaju pe wọn ko fi ẹri to daju han pe eto idibo gomina to n bọ nipinlẹ Ekiti pa awọn ati miliọnu meji oludibo to wa nipinlẹ naa lara.

O wa kadi idajọ rẹ nilẹ pe awọn olujẹjọ mẹfẹẹfa naa ko to lati soju miliọnu meji oludibo to wa nipinlẹ Ekiti lati pe ẹjọ tako ofin ọdun ilẹ wa ọdun 1999 tabi da idibo gomina ipinlẹ naa to n bọ duro.

Adajọ ti sọ ara rẹ di Baba Keresimesi to n da ẹjọ nu tori ailasẹ bi olujẹjọ ko tiẹ yọju – Ilana Omo Oodua:

Wayi o, ẹgbẹ IlanaOmo Oodua ti wa fesi lori idajọ to waye lori amulo ofin ilẹwa naa ati idibo gomina ni Ekiti.

Atẹjade ti akọwe ibaraẹnisọrọ fun ẹgbẹ Ilana Omo Oodua, Maxwell Adeleye fisita wa sapejuwe idajọ naa bii asise nidi agbekalẹ idajọ.

Atẹjade naa ni adajọ Ikuewumi ti wa sọ ara rẹ di Baba Keresimesi to n da ẹjọ nu lori pe ko lasẹ lati gbọ ẹjọ naa bi o tilẹ jẹ pe awọn olujẹjọ lori ẹjọ naa ko fi igba kankan yọju sile ẹjọ lati osu kẹrin ti igbẹjọ ti bẹrẹ.

“A pe ẹjọ kotẹmilọrun lori idajọ yii nitori lero temi, bii igba ti adajọ eeyan se asise nidi agbekal idajọ ni.

Amọ dipo ti adajọ naa fi n sọ ara rẹ di Baba Keresimesi lori idajọ yii, se lo yẹ ko taari ẹjọ naa lọ si Abuja dipo to fi wọgile, amọ ijagudu wa lori rẹ si n tsiju.”

Bẹẹ ba gbagbe, osu kẹrin ọdun yii ni ẹgbẹ ajijagbara fun ilẹ Yoruba, Ilana Omo Oodua pe ẹjọ naa pe ki ileeẹjọ da ibo gomina Ekiti ati Osun nu nitori ofin ilẹ wa ọdun 1999 ko kunju iwọn to lati fi seto idibo gomina mejeeji naa.