Ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ ajìjàgbara ṣèwọ́de n'Ibadan torí ìkọlù agbébọn nílẹ̀ Yorùbá

Oríṣun àwòrán, Yoruba Koya
Àwọn ẹgbẹ́ ajìjàgbara tó ń jà fún òmìnira ilẹ̀ Yorùbá gùn lé ìwọ́de nílùú Ìbàdàn nítorí ìṣẹ́ ibí àwọn agbébọn nílẹ̀ Oodua.
Lára àwọn iṣẹ́ ibi táwọn ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ ajìjàgbara náà ń korò ojú sí ní ìjínigbé, ìfipábánilòpọ̀, ìpànìyàn àti bíba dúkìá ìlú jẹ́.
Gbọ̀ngàn Mapo ni àwọn olùwọ́de náà tí gbéra, tí wọn sì gba Bẹẹrẹ, Oje, Bus stop kọjá, kí wọn to lọ dúró síwájú ilé gómìnà ní Agodi.
Ṣe ni àwọn aráàlú tú jáde kẹ̀tíkẹ̀tí láti darapọ̀ mọ́ àwọn olùwọ́de náà nígbà tí wọ́n gbọ́ ohun tí wọn ń ṣe ìwọ́de lé lórí.
Wọ́n ní ìwà ọ̀yáju àti àbùkù ilẹ̀ Yorùbá ni ìṣẹ̀lẹ̀ ìpànìyàn tó wáyé ní Owo láìpẹ́ yìí, tí irúfẹ́ àwọn ìwà ìpànìyàn tó ń wáyé káàkiri ilẹ̀ Yorùbá náà sì gbọ́dọ̀ dáwọ́ dúró ní kíákíá.
Akọ̀wé àpapọ̀ fún Àgbáríjọpọ̀ àwọn ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ ajìjàgbara náà, Olóyè Steve Abioye nígbà tó ń báwọn aráàlú sọ̀rọ̀ ní Oje, gbà wọn ní ìmọ̀ràn láti dáàbò bo ara wọn, kí àwọn agbébọn máa ba à pa wọn bíi ẹran.
Alákóso àwọn ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ ajìjàgbara náà, Johnson Ajilore kéde pé àwọn agbébọn náà ti gẹ̀gun sílẹ̀ Yorùbá, àsìkò sì ti tó fún ìran Yorùbá láti dìde dáàbò bo ara wọn lọ́wọ́ agbébọn tó ń pànìyàn lojoojumọ.
Ajilore ní báwọn agbébọn náà ti ṣe ní ìlú Igangan rèé, bákan náà ni wọ́n ti gbẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Yorùbá làwọn ìlú ńlá ńlá míì àti abúlé.
"Ṣé bá ṣe máa ba lọ rèé, tá sì máa gbé nínú ìbẹ̀rù nílẹ̀ baba wa? Àsìkò ti wá tó báyìí fáwọn èèyàn wa láti dìde tako ìwà ìkà náà.
Owo Church Killing: Ọjọ́ June 17 ní wọn yóò sìnkú àwọn 40 tó kú ní ìkọlù sí ṣọ́ọ́ṣì

Oríṣun àwòrán, Google
Ijọ Catholic Diocese of Nigeria ti kede pe Ọjọ kẹtadinlogun, Oṣu Kẹfa ni awọn yoo sin oku gbogbo awọn to gbẹmi mi ni ikọlu si ẹka ṣọọṣi ni ilu Ọwọ, nipinlẹ Ondo.
Awọn agbesunmọmi lo ṣekọlu si ile ijọsin St. Francis Catholic Church ni ilu Ọwọ, ti wọn si ṣina bolẹ pẹlu ado oloro lu awọn ọmọ ijọ ni asiko ẹsin ni oAyajọ Pentecost.
Gẹgẹ bi ile ijọsin naa ṣe sọ, eniyan ogoji lo ku ninu iṣẹlẹ naa, ti awọn eniyan to le ni aadọta si farapa.
Adari eto iroyin , Rev.Fr. Augustine Ikwu lo fi iroyin naa lede fun awọn oniroyin.
Ninu ọrọ rẹ, o ni isinku ọlọgọọrọ naa ni awọn yoo ṣe ni itẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ ni si agbegbe Emure, ni ilu Ọwọ.
Wọn fikun un pe eniyan ogoji ni awọn si ri ka to ku ninu ikọlu naa, ti awọn to farapa si n gba itọju ni Federal Medical Center, Owo ati St. Louis Catholic Church ni Owo, to fi mọ awọn ileewosan aladani ni ipinlẹ Ondo.
Titi di asiko yii to jẹ ọsẹ kan lẹyin iṣẹlẹ naa, ko i tii si ẹnikẹni ti wọn fi panpẹ ọba mu pe o lọwọ ninu iṣẹlẹ naa.












