Ìdí réè tàwọn ọdọ̀ kàn ṣe pé ìjọba orílẹ̀-èdè 32 lẹjọ̀ lórí ìyípadà ojú ọjọ́

Oríṣun àwòrán, Claudia Duarte Agostinho
- Author, Selin Girit
- Role, BBC World Service
''Ẹru n ba mi gidi gidi''
Bẹẹ ni Claudia Duarte Agostinho sọ ni igba to ṣe iranti igbona jainjain to waye nigba ti ina nla kan ṣẹ yọ ni Portugal ni ọdun 2017 ti o ṣi gbẹmi awọn eeyan to le ni ọgọrun kan.
''Awọn ina wọnyi mu mi bẹrẹ si ni beere pe iru ọjọ iwaju wo lo n duro de wa?''
Claudia ẹni ọdun mẹrinlelogun,ọmọ iya rẹ ọkunrin Martim ẹni ogun ọdun ati ọmọ iya rẹ obinrin Mariana ẹni ọdun mọkanla wa lara awọn ọdọ Portugal to ti pe ijọbọ orileede mejilelọgbọn lẹjọ.
Ninu wọn la ri gbogbo orileede EU,Ilẹ Gẹẹsi,Russia, Switzerland ati Turkey.
Ẹsun ti wọn fi kan awọn ijọba yi ni pe wọn o gbe igbesẹ to yẹ lori ọrọ iyipada oju ọjọ ati pe wọn kọlati mu adinku ba afẹfẹ gaasi to n ṣe kaoba fayika ti wọn tu sita.
Iru ẹjọ ti wọn pe yi lo jẹ akọkọ iru rẹ ti wọn yoo gbe wa siwaju ile ẹjọ to n gbẹjọ ẹtọmọniyan ECHR ni Strasbourg.
Bi wọn ba fi jare nidi ẹjọ yi, yoo ni ipa pataki nipa ohun ti yoo de awọn ijọba ti ọrọ naa kan labẹ ofin.LỌjọru ni wọn yoo bẹrẹ igbẹjọ naa ni ile ẹjọ.
Ọjọ ori awọn to pẹjọ yi wa laarin ọdun mọkanla si ọdun mẹrinlelogun wọn si ni iyipada oju ọjọ lo wa lara ohun to fa ina ti ko sinmi lati maa jo ayika lọdọdun ni Portugal lati ọdun 2017
Wọn ni awọn ti n mọ riri iyipada oju ọjọ yi lara ni paapa bi ayika ṣe n gbona jainjain ni Portugal eyi to mu ki awọn maa deju mọ inu ile ju ti tẹlẹ lọ.
Wọ n ni eleyi ṣe akoba fun orun sisun awọn tabi nini anfaani lati ṣe ere idaraya.
Awọn mii ninu wọn lawọn n koju ipenija ilera bi aisan semi semi.
Ko si kankan ninu awọn ọdọ wọnyi to n beere ki wọn san owo gba ma binu fun wọn.

Oríṣun àwòrán, Global Legal Action Network
''O wu mi ki n wa layika ti ko si idọti kankan nibẹ,mo fẹ wa nipo ilera alaafia''
Mariana, ọmọ ọdun mọkanla lo n s eroọkan rẹ bayii to si ni ''Mo n ba wọn pẹjọ yi tori pe ọjọ iwaju mi ṣe pataki si mi.Ẹru n ba mi nipa bi ibi taa n gbe loni yoo ṣe ri lọjọ iwaju''
Claudia sọ pe gbogbo igba ti Mariana ba gbọ ti hẹlikọpta n fo loke ni aya rẹ maa n ja.
A maa mu ranti igba ti ina jo igbo kijikiji ti iwọn rẹ le ni ẹgbẹrun lọna aadọta acre ti eeru ina to jo yi ṣe n fẹ lu awọn ile ni jina jina ibi ti ina ọhun ti jo.
O sọ pe ''Ohun iwuri ni pe Mariana kopa ninu ipẹjọ yi pẹlu wa.O ṣafihan iru ẹri ọkan to ni toun ti pe o ṣi kere lọjọ ori.''
O fi kun pe tohun ti bẹẹ, o jẹ nkan to fọwọ kan ni lẹmi tori ohun to yẹ ko maa ṣe gẹgẹ bi ọmọde ni ere pẹlu awọn ọrẹ rẹ. Ko yẹ ki iru nkan bayii maa wa lọkan rẹ.
Awọn agbẹjọro to n ṣoju awọn olupẹjọ mẹfa yi ni ireti wa wi pe wọn yoo wi awijare pe igbesẹ awọn ijọba mejilelọgbọn yi n dari agbaye lọ si ibi ti ayika yoo ti gbona kọja afarada nigba to ba ya.
Gearóid Ó Cuinn to jẹ oludari Global Legal Action Network (GLAN) to n ṣatilẹyin fawọn olupẹjọ yi ni ''igbona riri ayika yi kọja afarada''
''Bi awọn ijọba ko ba gbe igbesẹ to yẹ, awọn ọdọ olupẹjọ yi yoo koju ipenija fun ilera ati igbayegbadun wọn latari igbona riri ayika.Amọ pe awọn ijọba lagbara lati mu opin ba gbogbo nkan to n ṣẹlẹ yi ṣugbọn wọn kọ lati gbe igbesẹ kankan'

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iwadii kan to waye lọdun 2021 fidi rẹ mulẹ pe ijaiya ati aidunnu si bi ijọba ṣe mu ọrọ iyipada oju ọjọ ni akoba to n ṣe fun idagbasoke awọn ọdọ kaakiri agbaye.
Eeyan ẹgbẹrun mẹwaa ni iwadii yi ṣayẹwo wọn ni orileede mẹwaa ti ọjọ ori wọn si wa laarin ọdun mẹrindinlogun si mẹẹdọgbọn.
Ababọ rẹ ni pe aimojuto ọrọ iyipada oju ọjọ lati ọdọ ijọba ni nkan ṣe pẹlu idaamu ọkan to ba awọn ọdọ.
Ninu esi wọn lọtọọtọ ati lapapọ ijọba awọn orileede ti wọn pe lẹjọ sọ pe wọn ko ribi fidi ọrọ mulẹ doju ogongo pe aiyasi ọrọ iyipada oju ọjọ lati ọwọ ijọba n ṣokunfa idaamu ọkan to laamilaka lara awọn ọdọ.
Wọn ni ko si ẹri to fi han pe iyipada oju ọjọ jẹ ewu si ẹmi awọn eeyan lorilẹ agbaye tabi nipa ilera wọn.
Bẹẹ ni wọn sọ pe didasi ọrọiyipada oju ọjọ kọja nkan ti ile ẹjọ ẹtọmọniyan to wa ni Yuroopu le da si.
Gearóid Ó Cuinn s pe ''awọn ọdọ mẹfaa to wa lati Portugal yi yoo koju ipenija nla pẹlu awọn agbẹjọro ti orileede mejilelọgbọn yoo ko wa lati wa jẹjọ lori ọrọ to ṣe pe o ti n lapa lara wọn''
''Ọrọ naa fẹ da biija laarin David ati Goliath ni pẹlu ẹjọ to n lepa iyipada nipa bi ijọba ṣe n ṣeeto nipa iyipada oju ọjọ ki o baa le ṣe anfaani fọjọ iwaju''

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Kọmisana fẹtọmọniyan labẹ igbimọ Yuroopu Dunja Mijatovic, to da si ẹjọ yi bakan naa sọ pe ẹjọ naa yoo ṣe atọna bawọn orileede yoo ṣe maa foju wo ọrọ ẹtọmọniyan ati ọrọ iyipada oju ọjọ.
O sọ fun BBC pe ''Itaniji leleyi jẹ si awọn orileede,ileeṣẹ lagbaye,gbogbo wa pata lati fi han pe ọrọ yi kan wa kii kan ṣe ọrọ lasan lori iwe.Kii ṣe nkan taa fọwọ yẹpẹrẹ mu.O nii ṣe pẹlu ki a ṣe iyipada awọn igbesẹ tabi ilana ijọba''
Idajọ ECHR yoo di dandan lori awọn orileede mejilelọgbọn yi ti yoo si mu ki wọn mura daada si ilana wọn nipa mimu adinku ba iye afẹfẹ gaasi to ni ipalar afun ayika to n jade sita.
Ireti wa pe ile ẹjọ yoo gbe idajọ kalẹ laarin oṣu mẹsan si oṣu mejidinlogun.
Claudia ni iṣẹlẹ yi mu ki oun maa ro pe ṣe oun si le bi ọmọ si iru ayika yi lọjọ iwaju.
Amọ o sọ pe ''taa ba pegede ninu ẹjọ yi, yoo tunmọ si pe ireti ọjọ iwaju ti yoo sunwọn yoo wa fun wa''















