Ọ̀pọ̀ ajínigbé ya bo abúlé Alálùbọ́ṣà ní Kwara, ẹ̀mí bọ́, ọ̀pọ̀ farapa

Awọn ti ajinigbe se lese

Ọjọ buruku, esu gbomimu ni ọjọru jẹ fun awọn eeyan abule Alalubosa nipinlẹ Kwara, nitori ikọlu ati ajalu nla to ya bo abule naa.

Idi ni pe ọjọ yii ni awọn agbebọn kan, tí wọn fura si pe wọn jẹ ajinigbe wọn ya bo abule Alálùbọ́ṣà, ni agbegbe Oko-Olówó, ni'jọba ibilẹ Àṣà, Ìpínlẹ̀ Kwara.

Lẹyin abẹwo wọn ọhun, ẹmi eeyan kan bọ, eeyan mẹta farapa, ti alaafia ilu naa si di fia-fia.

Abule naa daru patapata lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ Kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an yii, nigba ti awon agbebọn ja naa bẹrẹ si ni rọjo ibọn bajinatu laarin abule naa, ti ọrọ si di boole lọ, yago fun mi.

Yatọ si ẹni kan ti wọn yinbọn pá, eeyan mẹta miiran tun fara gbọta nibi iṣẹlẹ ọhun.

Abule Alalubosa

"Agbebọn yinbọn lu eeyan meji lapa, fi ibọn fọ ọkunrin kan lẹṣẹ"

Awọn ara abule salaye fun BBC Yorub,a lasiko ti a kan si abule naa pe, ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ naa de.

Wọn ni wọn si bẹrẹ si ni rọjo ibọn si gbogbo awọn ti wọn joko lati gba atẹgun nita ile wọn.

Ki awọn eeyan yii too du ara lati wọ inu ile, nnkan ti bajẹ mọ awọn eeyan miran lara laarin wọn.

Wọn yinbọn lu ọmọ obinrin kan ti orukọ rẹ njẹ Semiat Mukaila lapa, wọn fi ibọn fọ Abdullahi Awẹ lẹṣẹ, awọn mejeeji si n gba itọju nileewosan bayii.

BBC Yoruba gbọ pe bakan naa ni wọn fun Isiaq Abdullahi, nibọn lapa.

Lẹyin ti wọn yinbọn si Abdul Rasheed Alafara lẹṣẹ tan, ti iyẹn sa lọ, ni wọn tun sa a lada yanna-yanna titi ti ẹmi fi bọ lọrun rẹ.

Abule Alalubosa

Fijilante pa ọkan lara awọn ajinigbe, wọn ko ri eeyan kankan gbe salọ

Pẹlu atilẹhin awọn ikọ fijilante, awọn agbebọn ọhun ko ri eeyan kankan ji gbe lọ, koda, awọn fijilante pa ọkan lara wọn, àwọn yoku si na papa bora.

Isiaq, sọ fún BBC Yoruba pe "awọn mẹfa ni awọn agbebọn to wa ati pe bi wọn ṣe wọ ilu ni wọn bẹrẹ si ni yinbọn, wọn si yinbọn fun bii odidi ọgbọn iṣẹju.

"A pe ọlọpaa sugbọn wọn o wa, awọn fijilante lo wa, ti wọn si mu ọkan balẹ ninu awọn agbebọn naa ki awọn marun-un yoku to sa lọ.

O tẹsiwaju pe ko si aabo mọ fun ọmọ Naijiria mọ rara, o si rọ ijọba lati fun awọn fijilante ni irinṣẹ gidi nitori pe awọn ni wọn n lọ koju awọn agbebọn naa.

BBC Yoruba wa kan si Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Ajayi Ọkasanmi, ẹni to sọ bi isẹlẹ naa se waye ati bi igbesẹ ti wọn gbe lori rẹ.

Okasanmi ni aago kan oru ni ẹni kan fi iṣẹlẹ naa to ọlọpaa leti, ti awọn agbofinro si ti lọ sibẹ.

Ọkan lara awọn ajinigbe naa, ti fijilante pa